Ẹni tí mo sọ di èèyàn lé mi jáde nílé rẹ̀, àmọ́ mo ti di onílé mẹ́rin báyìì - Laide Bakare

Oríṣun àwòrán, @Laide Bakare
Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Laide Bakare ti ṣiṣọ loju eegun bo ṣe n gbe lọdọ eeyan ri, ti ẹni naa le jade ko to di onile mẹrin ọtọtọ niluu Eko.
Ninu atẹjade kan to kọ loju Instagram rẹ, Laide kan sara si ara rẹ lọjọ ayajọ awọn obinrin lagbaye.
Nigba to sọrọ lori bo ṣe jẹ ẹni ti ko nile lori ati bo ṣe di onile mẹrin.
- Ọkùnrin kan rèé tó gé nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ lẹ́yìn tó fa igbó yó
- Gbogbo ẹ̀yà ara Bamise Ayanwole ló pé nígbà tí mo rí òkú rẹ̀'
- Wo àwọn ìgbésẹ̀ tí Sunday Igboho gbé, tó fi di ọ̀tá ìjọba
- Sunday Igboho kò sì lè kúrò ní Benin Republic, sùgbọ́n ó tí kúrò ní àhámọ́ lọ gba ìtọ̀jú nílé ìwòsàn níbẹ̀- Agbẹjọ́rò Sunday Igboho
- Wọ́n ti rí òkú obìnrin ẹni ọdún 22 tó dàwátì nínú ọkọ̀ BRT l'Eko
- Ọkọ̀ tó rìn gba "one way" gbá ọmọ ìyá mẹ́rin lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo l'Eko, ọ̀kan kú
- Odindi ọdún mẹ́ta ni ọkọ mi ti ń fipá bá ìbátan mi ọmọ òrukàn ọdún mọ́kànlá lò pọ̀
Kini osere naa wi?
Oṣere naa to n ṣi ile rẹ kẹrin sọ pe ẹni ti oun ti figba kan ṣe oore fun pada le oun jade nile rẹ lakoko kan sẹyin, amọ ọpọn oun ti sun bayii.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Laide ni "Ẹni ti mo ran lọwọ lati jẹ eeyan laye sọ fun mi pe 'jade kuro ninu ile mi' amọ lonii yii mo ti di onile to le ni mẹrin laarin ilu Eko."
Ṣaaju ni oṣere naa ti kọkọ ṣafihan maluu atawọn owo ti awọn kan fi ranṣẹ si fun iṣile ọhun.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
O ni ọkan lara awọn ọrẹ oun lo fi maluu naa ranṣẹ ko to kede pe ọrẹ rẹ miran fi owo iṣile ranṣẹ si.
Lẹyin to gba owo ati maluu naa tan lo sọ loju opo Instagram rẹ pe "Ẹ jọmi loju gidi gan fun owo ti ẹ fi ranṣẹ simi, inu mi gidi lati jẹ ọrẹ yin."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3
Ta ni Laide Bakare?
Laide Bakare jẹ ọkan gboogi lara awọn arẹwa obinrin ti irawọn rẹ tan nidi iṣẹ tiata Yoruba ni Naijiria.
Wọn bi Laide Bakare lọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun 1980 niluu Eko.
Irawọ rẹ bẹrẹ si n tan nigba to kopa ninu ere "Mi O Foworola" ti wọn gbe jade lọdun 2003 ati ere "Love You Forever" to jade lọdun 2005.
Lara awọn ere mii to ti Laide Bakare ti kopa ni Ofin kokanla, Mafi Wonmi, Èsè, Atelewo eda, Ebo isinmi, Femi Oko Mummy, Royal Battle, ati bẹẹ bẹẹ lọ.