Oníṣòwò ọ̀ọ̀nì àti ejò ní ẹran náà ń ṣe ara lóore láì wo èèwọ̀ àṣà àti ẹ̀sìn tó rọ̀ mọ

Àkọlé fídíò, Oníṣòwò ọ̀ọ̀nì àti ejò ní ẹran náà ń fún ara lóore láì wo èèwọ̀ àṣà àti ẹ̀sìn tó rọ̀ mọ

Awọn eeyan lo maa n sọ pe ohun to jẹ ounjẹ fun ẹnikan, lo jẹ majele fun ẹlomiran.

Ọpọ ounjẹ ati ẹran lo wa nile aye, ti awọn ẹ́-ya kan maa n jẹ ni awọn agbegbe kan amọ to jẹ eewọ tabi majele fun awọn ẹya miran lati jẹ.

Nigba miran, bi irufẹ ounjẹ naa tabi ẹran ọhun ko ba a tiẹ ma jẹ majele, sibẹ awọn eeyan miran maa n korira irufẹ ounjẹ tabi ẹran bẹẹ.

Irufẹ ẹran bẹẹ ni ẹran ejo ati ẹran Ọ̀ọ̀nì.

Ọpọ ọmọ Yoruba ni kii fẹ ri ẹran ejo tabi ti ọọni soju debi pe wọn yoo jẹ, eyi to n se afihan bi wọn se korira awọn ẹran mejeeji yii to.

Koda, oniruuru itan ti ko fidi mulẹ lo rọ mọ awọn ẹranko mejeeji naa, eyi to sọ ẹran wọn di ikorira fun ọpọ eeyan.

Sugbọn ni akoko yii, ọkanjuwa ti dagba, ọgbọn ti rewaju, ti awọn ẹran mejeeji yii si ti wa lori atẹ fun tita fawọn eeyan to ba nifẹ lati jẹ wọn.

Ta ba si lọ si ode inawo tabi ọpọ ayẹyẹ lasiko yii, a ri tabili kan ni ẹgbẹ kan nibudo ayẹyẹ naa, ti wọn patẹ ẹran ejo ati ọọni si fawọn eeyan to ba nifẹ lati jẹ wọn.

Lọpọ igba si ni wọn maa n fi ẹran ejo ati Ọọni yii mu gaari pẹlu omi tutu ati suga.

O gba wa to osu mẹrin lati se iwadii nipa ẹran ọsin ati ejo ka to maa taa:

Ọkan lara awọn eeyan to n ta awọn ẹran mejeeji naa, Adedoyin Odunlami, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori katakara ẹran naa.

O ni o gba awọn ni osu mẹsan lati se iwadii lori bi wọn se le se awọn ẹran naa, ko to di pe awọn bẹrẹ okoowo naa.

Odunlami ni kii se pe awọn n wọ inu odo lọ pa ọọni tabi wọ inu igbo lọ pa ẹran ejo amọ awọn maa n sin awọn ẹranko naa ni.

O ni o maa n ya ọpọ eeyan lẹnu pe obinrin lo n sin ọọni, to si tun n pa tabi yan ta.

Onisowo ọọni naa sọ pe okoowo naa n pese isẹ oojọ fun ọpọ eeyan, ti ọjọ ọla rere si wa fun.