Snail Slim Soap: Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú lílo ọ̀ṣẹ tí wọn fi omi ìgbín ṣe láti fọ ojú
Ara meeriri ree, a ti ri oju ologbo lori atẹ, paapaa nidi oge sise.
Gẹgẹ bẹẹ se mọ pe awọn obinrin kii fi oge sise sere rara, paapaa nidi ohun ti yoo ba mu ki awọ ara wọn jọlọ, ti oju wọn yoo si gun rege.
Boya eyi lo mu ki ọkunrin kan se iwadii, to si gbe esi iwadi rẹ sita nipa amulo omi ara igbin, ti yoo mu ki oju gun rege.
- Ìdẹ̀ra dé, Gẹnẹrátọ̀ tó ń lo omi dé, a bọ́ lọ́wọ́ òkùnkùn
- Èèmọ̀! Eyín akọ̀ròyìn fò yọ lásìkò tó n ka ìròyìn lọ́wọ́ lórí tẹlifísàn
- Abúlé tí wọn kìí ti sọ ọmọ ní orúkọ, ohùn arò ni wọ́n fi ń pè wọ́n
- Èèmọ̀ rèé o, Dókítà yọ eyín 526 lẹ́nu ọmọ ọdún méje
- Wo àwọn nǹkan tí o kò mọ̀ nípa 'Church of Satan'
- ''Pásítọ̀ ní kí n gbé ọwọ́ lé ǹkan ọkùnrin ọ̀un, ní ejò dúdú bá jádé...''
Ọkunrin onisẹ iwadii naa, Damien Desrocher, tii se ọmọ ọdun mejidinlọgbọn lati ilẹ Faranse jẹ ara eeyan mẹta to n fi omi igbin se ọsẹ ifọju.
Awọn igbin to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọta ni Damien n sin, to si tun n gbero lati pese ọsẹ omi igbin bii ẹgbẹrun mẹta lọdun yii.
Nigba to n ba BBC sọrọ, Damien salaye pe awọn kii pa igbin kankan lara lasiko ti wsn ba n yọ omi ara wọn, ti awọn omi igbin naa si wulo fun iwosan.
Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Igbo Olodumare rèé, níbi tí Ìgbín ti tóbi ju Ìjàpá lọ
- Ìdílé márùn-ún tó gbajúmọ̀ fún òwò ẹrú nílẹ̀ Yorùbá
- Wo ìtàn ayé gbajúmọ̀ adigunjalè méje nílẹ̀ Yorùbá
- Jimoh Odutola, akọni oníṣòwò tí kò kàwé, àmọ́ táwọn Ààrẹ orílẹ̀-èdè ń ké sí láti wá dá iléesẹ́
- Njẹ́ o mọ̀ pé bíi ọdún 700 sẹ́yìn ni wọ́n ti ń bọ Osun-Osogbo? Mọ̀ síi nípa ìtàn ojúbọ̀ nàá
- Adunni Olorisa, obìnrin òyìnbó tó di ìyàwó òrìṣà nílẹ̀ Yorùbá títí di ọjọ́ ogbó
- Alimotu Pelewura, Ìyálọ́jà akọ́kọ́ l’Eko tó mi amúnisìn àti ìjọba tìtì
O fikun pe omi ara igbin ni eroja ti wọn n pe ni Collagen ati Elastin, ti kii jẹ ki oju eeyan tete gbo.





