Yoruba Nation: Ẹgbẹ́ Ilana Omo Oodua ní arúmọjẹ ló pilẹ̀ ìwé òfin 1999, INEC kò gbọdọ̀ lò ó fún ìbò Ekiti, Osun

Ní Ọjọbọ ni iroyin jade pe ẹgbẹ ilana Ọmọ Oodua ti pe ẹjọ niwaju ile ẹjọ giga kan nilu Ado Ekiti ati Osogbo.
Afojusun igbesẹ naa ni lati paṣẹ fun ajọ eleto idibo, INEC pe ko gbọdọ ṣeto idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ekiti ati Ọsun.
Idi ree ti BBC Yoruba fi tọ ọba alaye kan lọ nilẹ Yoruba lati mọ ero rẹ si igbesẹ ti ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua naa gbe pe ibo ko gbọdọ waye nipinlẹ Ekiti ati Osun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ohun tí mo fẹ́ rèé tí ìkọlù sí Ukraine yóò bá dópin - Putin
- "Ọlọ́pàá ló pe mí láti wá gbé òkú Timothy Adegoke lẹ́sẹ̀ títì"
- Gómìnà ànà ní Anambra, Obiano bọ́ sí gbaga EFCC lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tó gbé ìjọba sílẹ̀
- Ogunsua ìlú Modakeke, Ọba Moses Oladejo Oyediran wàjà
- Ẹ wo àṣírí tó wà nìdìí ìròyìn pé ìjọba Gẹ̀ẹ́sì kò fún ọmọ Nàìjíríà ní “visa” mọ́?
- Wọ́n tan bàbá 85 kúrò nílé, fọ́ igi mọ lórí, ju òkú rẹ̀ sétí odò l‘Ogun
Ninu ọrọ rẹ, Ọba Adetokunbo Tẹjuoso tii se ọba alaye ni orile Kemta nipinlẹ Ogun ṣalaye pe, bi ọrọ ṣe n lọ yii, o yẹ ki atunyẹwo waye lori agbekalẹ iwe ofin Naijiria tọdun 1999.
A n sun ọjọ ija siwaju ni - Ọba Adetokunbọ Tẹjuosho
Ọba Tẹjuosho ni bi awọn ẹya kan ṣe n jẹ gaba lori awọn ẹya miran lori iṣakoso ọkọọkan awọn ileeṣẹ ijoba apapọ kun ara ohun to fa ikunsinu.
Ọbalaye naa fi kun un pe igbesẹ ti ilana ọmọ Oodua n pe fun ni eto idibo bẹẹni tabi bẹẹkọ ti oyinbo mọ si 'Referendum'.
Oba ilu Orile Kemta naa tun salaye siwaju pe, ipe fun ayẹwo ni ipe naa ati pe ko di dandan pe ti wọn ba ṣeto idibo naa tan, o seese ki awọn oludibo ni ẹya kọọkan o dibo pe awọn ṣi fẹ wa labẹ isakoso orilẹede Naijiria.
Ọba Tẹjuosho ni gbogbo bi awon adari ṣe n fi tipatikuuku mu gbogbo ẹya mọra bayii kan da bi igba ti eeyan ba n sun ọjọ ija siwaju ni.

Oríṣun àwòrán, Adetokunbo Tẹjuoso
Iwe ofin Naijiria lo n fa iwa ijẹkujẹ awọn oloṣelu:
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to gbe ẹgbẹ Ilana Omo Oodua rele ẹjọ, agbẹnusọ fun ẹgbẹ naa, Maxwell Adeleye salaye ohun to fa a.
Adeleye ni iwe ofin orilẹede Naijiria ko ba ofin mu nitoripe araalu ko lọwọ ninu agbekalẹ rẹ.
O ni gbarọgbudu lasan ni ofin ọdun 1999 ti wọn fi n ṣe akoso orilẹede Naijiria lọwọ yii.
O ni idi niyi ti ẹgbẹ ilana ọmọ oodua fi n pariwo pe ko ni si eto idibo gomina ni ipinlẹ Ekiti ati Ọṣun.
" Ofin irọ lẹ fi n ṣe eto idibo lorilẹede Naijiria. Idi si niyi ti awọn oloṣelu fi n kowojẹ."

Ilana Omo Oodua mórílé ilé ẹjọ́ pé kó wọ́gilé ìbò gómìnà ní Ekiti, Osun àti àpapọ̀ ilẹ̀ Yorùbá

Loju ọna lati mu ki ijọba Naijiria pe ipade apero lori atunto ijọba ati ọna lati gba ominira ilẹ Yoruba, ẹgbẹ ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Ilana Omo Oodua, ti pe ijọba apapọ lẹjọ lori eto idibo ti yoo waye ni ipinlẹ Osun ati Ekiti.
Ninu iwe ipẹjọ ọhun ti agbẹjọro wọn, Tolu Babaleye kọ, wọn ni ajọ to n ri si eto idibo ni Naijiria, INEC, ati adajọ agba Naijiria, Abubabakar Malami ni awọn yoo ba ṣe ẹjọ ọhun.
Olori ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye, igbakeji rẹ, Ọjọgbọn Wale Adeniran atawọn marundinlogun mii ni, awọn n fẹ ki ijọba apapọ wọgile ofin ọdun 1999.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wọ́n fi abẹ dá ọgbẹ́ sí Timothy Adegoke lára ni, kí ẹ̀mí tó bọ́ lára rẹ̀ - Onímọ̀ ìwádìí
- Ọ̀kan lára àwọn afurasí mẹ́rin tó gé orí Sofiat Okeowo láti fi ṣẹ́ṣó gba ìtúsílẹ̀
- Kìnìún yawọ ìlú, ṣe ọlọ́dẹ méjì léṣe
- 1200 èèyàn rì sábẹ́ ilẹ̀ bí Russia ṣe yin àdó ikú mọ́ gbọ̀ngàn nlá kan ní Ukraine
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ní àwọn awakọ̀ èrò fẹ́ ṣe ìwọ́de lónìí l‘Eko torí yíyọ MC Oluomo nípò?
- Kí ló fa rògbòdìyàn tó gbòde ní Ajah, tí ẹ̀mí méjì fi bọ́, tí ọ̀pọ̀ dúkìá sì bájẹ́?
- "Sylvester Oromoni tọ̀ mí wá pé itan ń ro òun kó tó kú, mo sì ba fi ọwọ́ ra á pẹ̀lú òògùn ara ríro"
- Ìwà àtakò sí ìjọba ní bí ọlọ́pàá bá da iṣẹ́ sílẹ̀, kò tọ̀nà - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Kò pọn dandan fún akẹ́kọ̀ọ́bìnrin láti lo hijab nílé ẹ̀kọ́ - Ilé ẹjọ́
Bakan naa ni wọn tun n fẹ ki ijọba pe ipade apero lọna ati le gba ominira fun ilẹ Yoruba, gẹgẹ bii orilẹ-ede to da duro.
INEC ko ni ofin to dantọ lati seto idibo nilẹ Yoruba:
Ninu atẹjade kan ti akọwe ẹgbẹ naa, Maxwell Adeleye fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni ofin ti Naijiria n lo lọwọ funra rẹ ko lẹsẹ nilẹ nitori ko si ipade apero kankan to waye ki wọn to kọ ofin ọhun.
Maxwell ni ajọ INEC ko ni ofin to dantọ lati ṣe eto idibo kankan nilẹ Yoruba, to jẹ ọkan lara orilẹ-ede Naijiria, nitori naa, ki ile ẹjọ wọgile eto idibo ti INEC n mura rẹ ni ipinlẹ Osun ati Ekiti, tii ṣe ilẹ Yoruba.
Ilana Omo Oodua ni eto idibo kankan ko gbọdọ waye nilẹ Yoruba ayafi ti wọn ba kọkọ ṣe ipade apero pẹlu awọn ọmọ Yoruba, nibi ti wọn yoo ti sọ oun ti wọn n fẹ, yala wọn fẹ da duro ni o tabi wọn ṣi fẹ wa lara Naijiira.
Wọn ni "Lai si ipade apero, to jẹ ọkan gboogi lara irinṣẹ ti wọn fi n kọ ofin, ofin ọdun 199 funra rẹ ko ba ofin mu nitori awọn to kọ ofin ọhun kuna lati ṣe ohun to yẹ ki wọn to kọ ofin ọhun."

Oríṣun àwòrán, Ilana Omo Oodua
Awọn ohun ti Ilana Omo Oodua n fẹ ki ile ẹjọ ṣe ree:
Lakọkọ, wọn ni awọn n fẹ ki ile ẹjọ wọgile ofin ọdun 1999.
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, ofin naa bẹrẹ pẹlu akọle "Awa ọmọ Naijiria" amọ kii ṣe apapọ awọn aṣoju awọn ọmọ Naijiria lo korajọ pọ lati kọ ofin naa.
Ilana Omo Oodua tun n fẹ ki ile ẹjọ wọgile gbogbo eto idibo ti yoo waye labẹ ofin ọdun 1999 naa, gẹgẹ bii eyii ti ko ba ofin mu nitori ofin ti wọn yoo ti ṣe eto idibo naa ko ni gbongbo.
Yatọ si eyii, ẹgbẹ naa ni eto idibo to n bọ nipinlẹ Ekiti ko gbọdọ waye labẹ ofin ọdun 1999, nitori naa ki ile ẹjọ gbẹsẹle eto idibo ọhun.
Ko tan sibẹ, wọn tun ni adajọ agba Naijiria ati ajọ INEC ko gbọdọ fi ẹsẹ tẹ ipinlẹ Ekiti labẹ asia eto idibo kankan.
Maxwwell pari atẹjade naa pe eto ibibo ọhun ko gbọdọ waye nitori pe ofin to gbe eto naa kalẹ labuku.
Lẹyin naa lo rọ gbogbọ ọmọ ilẹ Yoruba lati yọju sile ẹjọ ni gbogbo awọn ọjọ ti igbẹjọ naa yoo maa waye.















