Portable-MC Morris Canada Show: Àlàyé rèé lórí ìdí tí olórin Zazzu fi pàdánù eré tó yẹ kó lọ ṣe ní Canada

Oríṣun àwòrán, portablebaeby/Instagram
Gbajúgbajà olórin Zazzu nnì, Habeeb Okikiola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Portable, ti pàdánù láti lọ ṣeré níbi ayẹyẹ kan ní Canada, èyí tí adẹ́rìnpòṣónú MC Morris ṣe agbátẹrù rẹ̀.
MC Morris tó kéde ọ̀rọ̀ náà lórí Instagram rẹ̀ pé Portable kò ní le kópa níbi ayẹyẹ naa nítorí ìkéde tí Portable ṣe wí pé òun ti dá ẹni to n se akoso ẹgbẹ olorin oun, ìyẹn ìjọba danku, dúró fún ìgbà kan ná.
Nínú àtẹ̀jáde tí MC Morris fi sórí Instagram rẹ̀ náà, ló ti ṣàlàyé ìdí tí ó fi gbé ìgbésẹ̀ láti yọ Portable kúrò lára àwọn òṣèré olórin tí yóò kópa níbi ayẹyẹ náà.
Ọpọ awọn ololufẹ Portable lo wa n bi MC Morris leere pe ki lo de to se yọ orukọ olorin naa kuro ninu awọn amuludun to n ko lọ si Canada.
Nigba to n dahun ibeere wọn, MC Morris ni o nidi ti oun fi se bẹẹ .
"Fún gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń bèèrè ìdí tí mo fi yọ Idamu Adugbo yin kúrò nínú àwọn tí yóò kópa níbi ayẹyẹ tí mo fẹ́ ṣe ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù karùn-ún, idi ni pé o dá àwọn aláàkóso rẹ̀ dúró ni."
Ó ní kí ènìyàn ní ẹ̀bùn orin kíkọ nìkan kò tó, ènìyàn ko bá mọ orin kọ dáradára ṣùgbọ́n tí kò níwà daadaa, kò dára rárá.
"Mánéjà méjì láì tíì pé ọdún kan, ó tún lé DJ tí iṣẹ́ rẹ̀ nitori kò ju pé kó gbe orin si, kó sì ṣe ṣakaṣáká lọ, mi ò lè kóṣì mérò, ẹ má bínú."
"Mo ti wọ́gilé gbogbo ìdúnàádúrà tí a ti ṣe, Ijọba danku má bínú".

Oríṣun àwòrán, iammcmorris/Instagram
Kílódé ti Portable dá àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ dúró?
Nínú fọ́nrán kan tí Portable ṣe lórí Instagram ló ti kéde wí pé òun ti dá àwọn tó ń bá òun ṣiṣẹ́ ìyẹn Mánéjà, DJ àti ẹni tí ó ń ṣe agbátẹrù ìpolongo rẹ̀ dúró lẹ́nu iṣẹ́ wọn.
Portable ní gbogbo àwọn wọ̀nyí ni wọ́n wà pẹ̀lú òun nítorí lásán nítorí owó.
Ó ní òrìṣà bó ò le gbàmí ṣemí bó ṣe bámi ni òun fi ọ̀rọ̀ náà ṣe wí pé tí àwọn òṣìṣẹ́ náà kò bá máa ríjẹ lára òun kí wọ́n kúkú fi òun kalẹ̀.
Ó ní "ṣe èmi ni bàbá tàbí ẹ̀gbọ́n yín ni? Mánéjà, DJ, pòmótà, èmi ni mò ń bọ́ ọ yín, ra aṣọ sí i yín lọ́rùn, fi owó sínú akoto báńkì yín".
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Adájọ́ gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹ̀bẹ̀ Rahmon Adedoyin tó ní òun kò ní ẹjọ́ láti jẹ́
- Ẹ wo orúkọ àti ojú àwọn èèkànlú tó forí sọta ìkọlù rélùwéè àti ipò tí wọn dì mú
- Aráàlú bínú tán l‘Okeho, wọ́n ti iléeṣẹ́ amúnáwá pa torí ségesège iná ọba
- Kemi Afolabi ti nílò ìtọ́jú pàjáwìrì, a ń gbe lọ sókè òkun - Yomi Fabiyi bú sẹ́kún
- À ń wá láti Ibadan, wá jí ọ̀pọ̀ ọmọ gbé l‘Eko fún ètùtù ọla - Afurasi ajọmọgbe
- Wo bí òògùn lílò àtàwọn nǹkan mìí ṣe le mú kí nkan oṣù obìnrin dáwọ́ dúró láìpé ọjọ́
"Tí mo bá wá ṣe bí ẹni pé kò sí owó lọ́wọ́ mi pẹ́rẹ́, kí mánéjà yámi lówó díẹ̀ yóò ní òun kò lówó lọ́wọ́ bí ẹni tó ń fowó kọ́lé."
"DJ náà á sọ pé kò sówó, wọ́n rò pé ògo mí yóò tètè tán ni ṣùgbọ́n kò le parẹ́ láéláé, tí ẹ kò bá jèrè lárá mi, ẹ kúkú fimílẹ̀."
Ó ní ẹni tí ó bá wà pẹ̀lú òun láàárín oṣù kan tí ìgbé ayé rẹ̀ kò sì yí padà nílò láti lọ bọ orí ará rẹ̀, kí wọ́n fún ẹlòmíràn láyè láti jẹ lára òun.
Bẹ́ẹ̀ náà ló ní kí gbogbo wọn wá tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn tí wọ́n yóò bà bá òun ṣiṣẹ́.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Mi ò fìgbà kankan gbowó lọ́wọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ń ṣe agbátẹrù ìpolongo rẹ̀ - Ijoba Danku fèsì
Nígbà tó ń fèsì sí ẹ̀sùn tí Portable fi kàn án, ẹni tí ó ń ṣe agbátẹrù ìpolongo rẹ̀ tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ijoba Danku ní òun kò fi ìgbà kankan gba sísì lọ́wọ́ Portable fún gbogbo ìgbà tí òun fi ṣe iṣẹ́ fún un.
Ó ní òun dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tí òun kìí ṣe pòmótà tó máa ń lọ́ni lọ́wọ́ gbà, gbogbo ayẹyẹ tí òun bá sì gba fùn ní òun máa ń kó owó rẹ̀ jíṣẹ́ pé fun.
"Mi ò ní tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn kankan pẹ̀lú rẹ̀, di iṣẹ́ rẹ mú, kódà ó tún jẹmí lówó nítorí o yá owó lọ́wọ́ mi, máa fi akoto báǹkì mi ráńṣẹ́ sí ẹ kí o dá owó mi padà."
"Bákan náà ni Eti DMW, Eti Davido tó san mílíọ̀nù méjì fún ayẹyẹ ṣùgbọ́n tí o lọ, dá owó náà padà fún ni kí n da padà fún Eti."

















