Omi Adio Robbery: Èèyàn márùn-ún tí kò mọwọ́-mẹsẹ̀ ló kú lásìkò ìdigunjalè PoS l‘Omi Adio
Ọba oke mase jẹ ka rin lọjọ eti ebi yoo pa ọna.
Laipẹ yii la mu iroyin wa fun yin nipa isẹlẹ idigunjale to waye ni agbegbe Omi Adio nilu Ibadan lopin ọsẹ to kọja.
Awọn adigunjale naa lo lọ ka ọkunrin kan to n lo ẹrọ ayarabiasa PoS ba onibara fi owo ransẹ tabi san owo naira fun wọn, eyi ti wọn n pe ni PoS Operator.
Lẹyin isẹlẹ naa, awọn adigunjale meji naa, ti wọn gun ọkada wa sisẹ ibi ọhun fi ọpọ ẹmi lo sofo, ti wọn si ji owo gbe lọ pẹlu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn ti a jọ ń 'robb' lo pa Ìyá mi sínú ẹ̀jẹ̀ ní 'Mission House'- Alufaa Oluwasegunfunmi
- Ìtàn ayé Shina Rambo, adigunjalè tó fi ahọ́n èèyàn 100 mu ẹ̀kọ́, fi oyún 27 gún ọṣẹ
- Ẹ wo ọ̀nà àbáyọ tí adigunjalè bá kọ lẹ́tà sí yín pé àwọn fẹ́ ẹ́ wá jà yín lólè
- Ọwọ́ sìkún ọlọ́pàá tẹ Bolanle afurasí adigunjalè làyájọ́ òmìnira Nàìjíríà
- Adigunjalè kọlu Kemi Afolabi, wọ́n fi àdá ṣá òun àti awakọ̀ rẹ̀
- Àwọn ọlọ́ṣà sùn lọ nínú ọkọ̀ tí wọ́n jí, lọ́wọ́ agbófinró bá tẹ̀ wọ́n
Idi ree ti BBC Yoruba se kan si Omi Adio lati fidi isẹlẹ naa mulẹ, ka le se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin nipa bi isẹlẹ naa se waye.
Mo di eepo ẹgẹ sinu apo, wọn ro pe ọpọ owo lo wa nibẹ, ni adigunjale se wa ja mi lole – Oni PoS
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, ọkunrin to n se PoS tawọn adigunjale wa ja lole ni eepo ẹgẹ lasan ni oun di sinu apo amọ awọn adigunjale ro pe owo nla ni.
O ni wọn wa digun ka oun mọ ile itaja, ti wọn si gba gbogbo owo to wa lọwọ oun, eyi ti ko to ẹgbẹrun lọna aadọrin naira.
“Akẹkọjade nile ẹkọ giga ni mi, awa mẹfa si la niwe ẹri ile ẹkọ giga ninu ẹbi mi sugbọn gbogbo wa ni ko ri isẹ osu se.
Idi ree ti mo se bẹrẹ isẹ PoS, ti mo si n fi eto ọgbin diẹdiẹ kun.”
Ọkunrin naa ni Ọlọrun lo yọ oun , ti ko jẹ kawọn adigunjale mejeeji naa pa oun ati iyawo oun.
Eeyan marun la padanu ninu isẹlẹ idigunjale naa:
Bakan naa ni olugbe agbegbe Omi Adio ti isẹlẹ naa soju rẹ sọ pe eeyan marun ti ko ni nnkan se pẹlu isẹlẹ idigunjale naa lo ba isẹlẹ naa lọ.
O ni ẹni akọkọ ni obinrin kan to n gbe lẹba titi ti wọn ti n digunjale, to ni aisan ẹjẹ riru, to si wa lori idubulẹ aisan amọ bo se n gbọ iro ibọn lakọlakọ, ni ẹmi rẹ bọ lojiji.
Ẹnikeji ni ọkunrin kan to gbe ear piece si eti, to n gbọ redio, amọ awọn adigunjale naa ro pe o n pe ọlọpaa ni, ti wn si fun nibọn.
Ẹni kẹta ni ọkunrin kan to n wa ọkọ Micra to wa ki awọn obi rẹ, ti wọn si gbe ibọn fun.
Bakan naa ni awọn eeyan meji miran to n re ode ayẹyẹ amọ ti wọn fẹ lọ ra fila pade ọlọjọ wọn, tawọn adigunjale naa si yinbọn mọ awọn ọkunrin mejeeji naa.
Ọmọ to n dun mi ninu ni adigunjale pa:
Iya ọkan lara awọn ọmọ ti awọn adigunjale ọhun pa sọ fun BBc Yoruba pe ọmọ daada ni ọmọ oun naa, tawọn aladugbo naa si n jẹri si.
O ni oun sare jade lọ, nibẹ si ni oun ti gbọ pe isẹlẹ idigunjale n waye, ni oun ba pe ọmọ oun lati gburo alaafia rẹ amọ wọn sọ fun oun pe ibọn ti baa.
Ọkunrin naa, ti a ri sare rẹ niwaju ile ni wọn lo n pese jijẹ mimu fun iya rẹ naa, ti iya rẹ si ni aridunnu ni ọmọ naa jẹ fun oun.
A n bẹbẹ fun aabo to peye lati ọdọ ọlọpaa:
Asoju agbegbe naa wa bẹbẹ pe kijọba ati ileesẹ ọlọpaa pese aabo to peye si agbegbe naa lati dena irufẹ isẹlẹ bayii lọjọ iwaju.
O ni lootọ lawọn ọlpaa sa ipa wọn lasiko isẹlẹ naa amọ o ku si ni ibọn n ro





