Toyin Adegbola: Bí wọn ṣe pariwo olè lé ọmọ mi ní ibùdó ìgbọ́kọ̀sí Shoprite, ló jẹ́ kí ń lọ kojú wọn

Oríṣun àwòrán, Yeye Toyin Tomato/Facebook
Gbajugbaja osere tiata nni, Toyin Adegbola, ti ọpọ eeyan mọ si Asewo to re Mecca ti sọrọ sita lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti wọn fi kan ọmọ rẹ.
BBC Yoruba kan si osere tiata naa lati mọ hulẹhulẹ isẹlẹ to kan ọmọ rẹ nile itaja Shoprite to wa ladugbo Ring Road nilu Ibadan naa lalẹ ọjọ Satide.
Bẹẹ ba gbagbe, ninu iroyin kan ta mu wa fun yin lọjọ Aiku, ni Toyin Adegbola ti fara ya ninu fidio kan lori ẹsun pe wọn parọ ole mọ ọmọ oun obinrin to jẹ iyawo ile.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Toyin Asewo to re Mecca fa wàhálà nílé ìtajà ShopRite n‘Ibadan lórí ẹ̀sùn ìbanilórúkọ jẹ́
- Ìjàmbá ọkọ̀ gbẹ̀mí ènìyàn mẹ́jọ l’Ékòó lópin ọ̀sẹ̀
- Ènìyàn mẹ́rin kú lásìkò tí wọ́n ń lé olè tó ja àwọn oní PoS lólè n'Ibadan
- Ìjàmbá ọkọ̀ gbẹ̀mí ènìyàn mẹ́jọ l’Ékòó lópin ọ̀sẹ̀
- Ǹ jẹ́ ó ṣeéṣe kí ìyáwò rẹ gbé ọmọ àlè wá sílé láì mọ̀?
- Ọ̀rẹ́kùnrin sanwó ẹ̀mí ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ fún agbanipa torí pé ó lóyún fún-un
- "N kò ṣẹ̀wọ̀n ọdún méjì o, ₦1m nílé ẹjọ́ ní kí ń san"
Ọmọ rẹ naa si lo lọ ra ọja nile itaja Shoprite ọhun amọ ti wọn ni ko sanwo eroja kan, Bio Oil, bi o tilẹ j pe eroja naa wa ninu akọsilẹ risiti ti wọn fun obinrin naa.
N ko mọ ibi ti fidio ti wọn fi parọ mọ ọmọ mi le de, ni mo se lọ koju wọn:
Ninu alaye rẹ, oyin Adegbola ni bi o tilẹ jẹ pe ori ibusun nile iwosan ni oun wa nigba ti oun gbọ nipa isẹlẹ naa, oun dide kia lọ sibẹ ni.
O ni ọrọ naa ko ba ma ti dun oun to ba jẹ pe awọn osisẹ ibudo itaja naa gbọ alaye ọmọ oun pẹlu ẹri to daju, to n fi han wọn ni.
Osere tiata naa ni lẹyin ti ọmọ oun fi risiti han ẹsọ oju ọna, lati tọka si eroja keji to wa nibẹ pe oun ti sanwo fun Bio Oil, lo kọja lọ sibudokọ ile itaja naa, to gbe mọto rẹ si.
"Amọ se ni osisẹ alaabo yii tun ke si awọn akẹẹgbẹ rẹ, ti wọn si lọ ka ọmọ mi, iyawo ile sibi to gbe ọkọ rẹ si nibudokọ wọn.
Se ni wọn bẹrẹ si ni pariwo le ọmọ mi lori pe awọn yoo yẹ inu ọkọ ati baagi rẹ wo, tori o ji eroja kan, ti ọpọ eeyan si pe le wọn lori.
N ko mọ iye eeyan to ti ya fido tabi aworan wọn nibi ti wọn ti n parọ ole mọ ọmọ mi, ni ko le jẹ ki n dakẹ lori ọrọ naa."
Toyin Adegbola ni idi ree ti oun fi dide lori ibusun nile iwosan lọ koju awọn osisẹ ile itaja naa, ki awọn le yanju ọrọ naa.
O ni eti to ba gbọ alọ, kọ ni yoo gbọ abọ, oun si mọọmọ pariwo fun gbogbo agbaye, paapaa awọn to ti gbọ nipa isẹlẹ naa tẹlẹ, lati mọ okodoro ọrọ nipa rẹ.
Awọn osisẹ Shoprite yari pe awọn fẹ ri ọmọ mi ni kọrọ, lo fi yari mọ wọn lọwọ:
Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, Asewo to re Mecca ni awọn osisẹ ile itaja Shoprite to parọ ole mọ ọmọ oun ni wọn yari pe awọn fẹ ri ni kọrọ lori ọrọ naa.
O ni ọmọ oun yari pe oun ko le ri wọn ni kọrọ, gbogbo ohun ti wọn ba fẹ sọ tabi se, ki wọn jẹ ko waye ni ita gbangba, kii se ni kọrọ.
Asiko yii lo fi wọn silẹ, gba ibudokọ to gbe mọto rẹ si lọ, ti wọn si gba tẹle, maa pariwo le lori pe o ji ọja kan.
O fikun pe ọpọ eeyan gan lo jẹri si nibẹ pe bi awọn osisẹ ile itaja naa se maa n se lọ̀pọ igba niyi, ti wọn yoo maa parọ ole mọ alaisẹ.
Koda, "o gbe baagi rẹ silẹ fun wọn lati wo inu rẹ amọ sibẹ, se ni wọn yari, ti wọn si n ni o sa ji eroja kan ni.
Nigba ti mo yọju sibẹ, mo ko awọn osisẹ ti wọn ko sẹnu ọna wọn naa, to yaju si ọmọ mi pamọ.
Amọ mo yari pe wọn gbọdọ ko wọn yọju sita lati bẹbẹ, n ko si kuro nibẹ afi igba ti wọn ko wọn jade sita si mi, ti mo si fi oju kan wọn."
Awọn alasẹ ibudo itaja Shoprite lati Eko ti wa bẹbẹ nile mi:
Nigba to n sọrọ nipa ibi ti wọn ba ọrọ naa de bayii, gbajumọ osere tiata naa ni o wu oun lọkan lati gbe ibudo itaja naa lọ sile ẹjọ ni.
Amọ se ni awọn alasẹ ibudo itaja Shoprite n sa kijokijo kiri lori isẹlẹ naa, ti ọga wọn pata pata gan ti ba mi pe awọn ko fẹ ki n pe awọn lẹjọ.
"Wọn ni awọn yoo kọ iwe ẹbẹ aforijin, ti awọn yoo si mu lọwọ nigba tawọn ba wa se abẹwo aforijin si mi nile mi.
Agbẹjọro mi gan ko ba ti kọwe si wọn loorọ oni ọjọ Aje amọ wọn sa n bẹbẹ ni pe ki n se suuru fun awọn."
Awọn alasẹ Shoprite ni awọn osisẹ awọn ni ko mọ ohun ti wọn n se:
Toyin adegbola fikun ọrọ rẹ pe awọn alasẹ ibudo itaja Shoprite ni awọn ti se iwadii gbogbo bi isẹlẹ naa se waye.
Wọn ni awọn osisẹ awọn lo dabi ẹni pe wọn ko mọ ohun ti wọn n se, koda awọn ọga wọn nilu Ibadan ti wa.



















