Lagos Accident: Ìjàmbá ọkọ̀ gbẹ̀mí ènìyàn mẹ́jọ l’Ékòó lópin ọ̀sẹ̀

Ní ọjọ́ tí ebi bá ń palé, ká má báwọn sí nílé, ní ọjọ́ tí ebi bá ń pọ̀nà, ká má báwọn sí lájò, ní àdúrà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń ṣe ní ojoojúmọ́.
Kò dín ènìyan mẹ́rin tó pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní agbègbè Eleko ní òpópónà márosẹ̀ Lekki sí Epe, ìpínlẹ̀ Eko.
Ní alẹ́ ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹta ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi wáyé.

Ọkọ̀ ńlá agbépo kan, tí ó gbé epo bẹntiróòlù ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n àti ọkọ̀ ńlá ilé iṣẹ́ Dangote ni ìròyìn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé wọ́n kọ lu ara wọn.
Akọ̀wé àgbà àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko, LASEMA, Olufemi Oke-Osanyintolu ní bí àwọn ọkọ̀ méjéèjì ṣe kọlu ara wọn ni wọ́n gbiná.
Oke-Osanyintolu ní àwọn ènìyàn tó wà nínú àwọn ọkọ̀ há sínú iná náà tí wọ́n sì jóná ráúráú.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Toyin Asewo to re Mecca fa wàhálà nílé ìtajà ShopRite n‘Ibadan lórí ẹ̀sùn ìbanilórúkọ jẹ́
- Wike tí kéde èròngbà rẹ láti gbé àpótí ìdìbò ààrẹ Nàìjíríà
- O fi owó wa jókòó sí Dubai, o sì ní ká máa gbàdúrà fún Nàìjíríà-Aráàlú fèsì sí Aisha Buhari
- Àlàyé rèé lórí bí ayédèrú ìwé ẹ̀rí NYSC ṣe dé ọwọ́ mi - Kemi Adeosun
- O fi owó wa jókòó sí Dubai, o sì ní ká máa gbàdúrà fún Nàìjíríà-Aráàlú fèsì sí Aisha Buhari
- Mo ohun mẹ́wàá pàtàkì nípa Abdullahi Adamu, alága tuntun fẹ́gbẹ́ òṣèlú APC
- Ǹ jẹ́ ó ṣeéṣe kí ìyáwò rẹ gbé ọmọ àlè wá sílé láì mọ̀?
Ó ṣàlàyé pé ọkùnrin ní àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó há sínú àwọn ọkọ̀ náà.


Ènìyàn mẹ́rin mìíràn tún pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀ Eko afárá Eko bridge.
Bákan náà Oke-Osayintolu tún ṣàlàyé pé ènìyàn mẹ́rin mìíràn tí ṣáájú pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta lórí afárá Eko bridge nígbà tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Toyota Camry, EPE 583 GT àti Lexus 300, SMK 478 AV kọlu ara wọn.
Ìròyìn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé awakọ̀ Lexus 300, Yusuf Ambali ló pàdánù ìjánu ọkọ̀ rẹ̀ tó sì lọ kọlu ọkọ̀ Toyota Camry tó jẹ́ ọkọ̀ akérò lórí ẹ̀rọ ayélujára tí gbogbo èrò tó wà nínú ọkọ̀ náà sì jẹ́ Ọlọ́run nípè.
Ṣùgbọ́n orí kò Ambali tó wa ọkọ́ Lexus náà yọ.
Oke-Osayintolu ní nígbà tí àwọn fi máa de ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé àwọn ènìyàn mẹ́rin náà ti kú tí àwọn sì ti gbé àwọn òkú náà fún àwọn àjọ woléwolé.
Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko, Benjamin Hundeyin ní Ambali tó ṣokùnfà ìjàmbá ọkọ̀ náà ti wà ní àgọ́ àwọn.
Hundeyin ní àwọn ti ń wá ọ̀nà láti wá àwọn mọ̀lẹ́bí àwọn ènìyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá nítorí ẹ̀rọ fóònù alágbèká wọn ti bàjẹ́ àyàfi kan tó sì wà ní títì pa.

















