Toyin Adegbola: Ìdí rèé tí gbajúmọ̀ òṣèré ṣe fa wàhálà nílé ìtajà n‘Ibadan lórí ọ̀rọ̀ ọmọ rẹ̀

Toyin Adegbola yari nile itaja igbalode ni Ibadan

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Abawọn nla ni ole jija, ko si sẹni to jẹ gba, ki wọn parọ ole mọ oun nitori bi ẹnikan ba jale lẹẹkan soso, to ba da aran bori, asọ ole lo da bora.

Eyi lo mu ki gbajumọ osere tiata kan lagbo awọn osere lede Yoruba, Toyin Adegbola, ti ọpọ eeyan mọ si Toyin Asewo to re Mecca, fi yari nile itaja igbalode kan, ShopRite to wa ni Ring Road nilu Ibadan.

Ninu fidio kan to gbe soju opo Instagram rẹ, Asewo to re Mẹcca n pariwo pe oun setan lati gbe ile itaja naa lọ sile ẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ, ti oun yoo si ba wọn fa whala.

Ki lo sẹlẹ ti Asewo to re Mecca fi fa wahala nile itaja:

Ninu fidio naa ni Toyin Asewo to re Mecca ti n lọgun pe awọn osisẹ ile itaja naa parọ ole mọ ọmọ oun obinrin.

Osere tiata naa ni ori ibusun nile iwosan ni oun wa, nibi ti wọn ti n fa omi si oun lara nitori pe ara oun ko le, ki wọn to wa kesi oun pe wọn n fiya jẹ ọmọ oun.

O ni gbogbo igba tawọn ọmọ oun ba wa sile lati oke okun, ni wọn maa n lọ sile itaja ShopRite lati ra awọn eroja kan tabi omiran.

"Nigba to de ẹnu ọna abajade ti ẹsọ alaabo ibudo itaja naa yoo ti yẹ awọn eroja to ra wo, ni osisẹ naa ba figbe ta.

Osisẹ alaabo naa ni oun ko ri eroja kan ti ọmọ mi ra lara akọsilẹ owo to san, to si kesi awọn osisẹ alaabo yoku.

Wọn ni iwa ti ọmọ mi hu fihan pe o ji eroja kan mu nile itaja wọn ni

Se ni wọn bẹrẹ si ni ti ọmọ mi nitikuti, wọn n na a lori ẹsẹ ti ko sẹ, ti wọn si n fi ọwọ tẹ lara, ti wọn si mọ pe iyawo ile ọkunrin kan ni.

Nibikibi ni onibara ba ti wọ ile itaja, o le tọ ohunkohun wo lai sanwo fun, ti ko si si ọlọpaa to le mu.

Mo fẹ ki wọn safihan akasilẹ aworan to foju ọmọ mi han nibi to ti ji ja wọn, bibẹẹkọ maa gbe wọn lọ sile ẹjọ"

Àkọlé fídíò, Mama Rainbow: Toyin Adegbola àti Razak Olayiwola ní ìyá rere àti àwòkọ́ṣe gidi ní

Mo fẹ fi oju kan awọn osisẹ alaabo to na ọmọ mi:

Osere tiata naa wa yari pe oun fẹ fi oju kan osisẹ alaabo to se agbatẹru bi wn se na ọmọ oun naa.

Osisẹ naa, ti wọn pe orukọ rẹ ni Destiny, ni Toyin Asewo to re Mecca ni ki wọn jẹ ko yọju sita lati wa salaye idi to se na ọmọ oun.

"Mo fẹ ki wọn fa sita,ko si wa salaye idi to se n tẹ iyawo ile nitẹkutẹ lara.

Wọn ni wn ko sẹsẹ maa se bẹẹ nile itaja naa amọ eyi ni wọn yoo fi jofin nitori ọmọ mi ko jale, bẹẹ ni ko ji ọja wọn.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Alaye ọmọ Toyin Asewo to re Mecca lori isẹlẹ naa:

Nigba to n salaye bi isẹlẹ naa se waye ninu fidio ọhun, ọmọ Toyin Adegbola to foju han ranpẹ salaye bi isẹlẹ adurunmọ naa se waye.

Obinrin naa, to n tako ọrọ ti ọga ile itaja naa sọ ni lootọ lo sọ fun oun pe oun ji ọja nile itaja wọn ni.

"O sọ fun mi nigba ti wọn ko ọrọ naa wa sọdọ rẹ pe mo ji ọja lootọ tabi ko jẹ pe ọja naa jẹ eroja ti eeyan le jẹ.

Mo si sọ fun ẹ pe ko si eroja ohun jijẹ ninu baagi mi, ti osisẹ alaabo naa si ni ororo Bio oil ni mo mu.

Lẹyin naa ni mo wa fi han yin ninu risiti ti mo fi sanwo pe Bio oil yii gan lo jẹ eroja keji ti wọn se akọsilẹ rẹ lori risiti nibi ti mo ti sanwo.

O daju pe osisẹ naa ko mọ awọn ohun to wa ninu risit ti mo fi sanwo amọ to wa n se bii ẹni to mọ nipa rẹ."

Asewo to re Mecca wa yari pe isẹlẹ to waye naa ko tii to eyi to yẹ ki wọn fi maa na eeyan lai se iwadi to yẹ.

O ni ẹni ti wọn tun wa n na jẹ iyawo ile eyi to buru jai, ọlọpa ati ofin si gbọdọ ba awn da si ọrọ naa

O wa n leri pe oun yoo pe amofin oun lati gbe ibudo itaja ShopRite rele ẹjọ.

Àkọlé fídíò, Samuel Ajirebi ọmọ ọdún mẹ́rin àtijọ́ rèé, ó bojú wo fíìmù rẹ̀ ní kékére, máàkì tó fún ara rẹ̀ rèé

Ki ni ile itaja ShopRite se lori isẹlẹ naa:

Ninu fidio naa lo ri foju han pe apa awọn osisẹ ibudo itaja ShopRite ja bọ lori isẹlẹ naa, ti ọpọ wọn si n bẹbẹ.

Wọn n bẹbẹ pe ki osere tiata naa mase gbe isẹlẹ naa sori afẹfẹ lasiko to n se fidio naa sita fun araye ri.

Bakan naa ni wọn n bẹ gbajumọ osere naa pe ko ma binu, asise ni, ko si jẹ ki awn pari ọrọ naa labẹle.

Lẹyin o rẹyin, Asewo to re Mecca sọ fun awọn ololufẹ rẹ to n tọpinpin bi isẹlẹ naa se n waye ninu fidio naa pe awọn ti yanju ọrọ naa.

O ni awọn osisẹ naa ti tọrọ aforijin, ti wọn si ti fa awọn osisẹ to na ọmọ oun sita lati wa bẹbẹ.

Awọn osisẹ ShopRite n bẹ Toyin Adegbola

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Ta ni Toyin Adegbola (Asẹwo to re Mecca)?

Gbajumọ osere tiata ni Oluwatoyin ọmọ Babatope aya Adegbola ti ọpọ eeyan mọ si Asẹwo to re Mecca ninu isẹ tiata lede Yoruba.

Ọdun 1984, eyiun ọdun mejidinlogoji lo bẹrẹ isẹ tiata to si ti di ilu mọọka.

Ọmọ bibi ilu Ilesa nii se amọ Ibadan lo ti lọkọ.

Orukọ ọkọ rẹ ni Anthony Kolawole Adegbola, ti ọba oke si fi ọmọkunrin kan ati ọmọbinrin kan ta awọn mejeeji lọrẹ.

Ilu Dublin lorilẹede Ireland ni awọn ọmọ mejeeji n gbe,wọn ti se igbeyawo, ti ọba oke si ti fi ọmọ ta wọn lọrẹ.

Toyin Adegbola ni wọn fi oye Yeyemesọ da lọla nilu Oke-Irun lọjọ Satide, ọjọ karun osu kẹta ọdun 2016.

Bakan naa lo ti gba ọpọ ami ẹyẹ gẹgẹ bi osere tiata, to si ti gbe ọpọ ere sinima ti ara rẹ jade.