Tshegofatso Pule: Ilé ẹjọ́ ní lóòótọ́ ọ̀rẹ́kùnrin olóògbé ló sanwó pé kí wọn pa aláboyún naá

Tshegofatso Pule ati ọrẹkunrin rẹ, Ntuthuko Ntokozo Shoba
    • Author, Pumza Fihlani
    • Role, BBC News, Johannesburg

Ọrẹkunrin arabinrin kan lorileede South Afrika, ti iroyin iku rẹ ba ọpọ eeyan ninu jẹ lọdun meji sẹyin, ni ile ẹjọ ti sọ pe o jẹbi pe o ṣeto ki wọn gbẹmi alaboyun naa.

Ile ẹjọ kan nilu Johannesburg gbe idajọ kalẹ pe arakunrin Ntuthuko Ntokozo Shoba, jẹbi ẹsun pe o pete pero lati ṣeku pa Tshegofatso Pule, to si sanwo fun agbenipa to da ẹmi rẹ legbodo.

Wọn ba oku arabinrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn naa, ti wọn yin nibọn laya, nibi to ti n rọ lori igi lọdun meji sẹyin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iṣẹlẹ ipaniyan yii mu inu bi ọpọ eeyan, koda aarẹ Cyril Ramaphosa naa dasi ọrọ ọhun.

Ṣaaju ni aarẹ ti sọ pe ilẹ South Afrika jẹ ọkan lara awọn orilẹede agbaye to ṣe pe ''o lewu lati jẹ obinrin''

Iku arabinrin Pule jẹ nkan to fọwọ kan ọpọ eeyan lẹmi pupọ, ti ọpọ si fara ya lori rẹ.

Àkọlé fídíò, World TB Day: Funkẹ Dosunmu ni ikọ́ ife kìí pani, ta bá lo òògùn rẹ̀ déédé

Bawo ni iwa ipaniyan naa ṣe ṣẹlẹ?

Ọjọ mẹrin ni wọn fi n wa arabinrin Pule ki wọn to pada ri oku rẹ.

Arakunrin to jẹwọ pe oun loun ṣeku pa, Muzikayise Malephane lo pada wa di olujẹri fun ijọba, to si naka si ọrẹkunrin arabinrin oloogbe naa gẹgẹ bi ẹni to sanwo ẹmi rẹ pe ki oun pa a.

Lasiko to fi jẹwọ yii, o n ṣẹwọn ogun ọdun lọgba ẹwọn .

O sọ fun ile ẹjọ pe Shoba san owo fun eeyan kan pe ko tan arabinrin naa lọ si ibi tawọn ti pa.

O ni igba keji ree ti ọkunrin naa yoo gbiyanju lati ṣeku pa Pule.

Malephane sọ pe Shoba fẹ ki wọn pa arabinrin Pule, ki aṣiri pe o fun loyun ma baa tu si ọwọ iyawo rẹ to wa nile.

Nkan taa gbọ ni pe Shoba n bẹru pe iyawo rẹ le fi i silẹ ati pe ko ni le raye pin ninu owo kan to wọ ọwọ obinrin naa laipẹ.

Oniṣowo nipa pasipaarọ owo (Forex) ni Shoba jẹ, to si sọ fun ile ẹjọ pe oun ko jẹbi ẹsun naa ati pe wọn fẹ koba oun ni.

Aworan afurasi to ṣeku pa arabinrin Pule lasiko to wa ni ile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Muzikayise Malephane ni ọdaran to ni ọrẹbinrin arabinrin Pule sanwo pe ki oun ṣeku pa

Ki ni adajọ sọ ninu idajọ rẹ?

Lasiko to n gbe idajọ kalẹ, adajọ Judge Stuart Wilson sọ pe ẹri to wa ni iwaju oun to lati fidi rẹ mulẹ pe Shoba lo wa nidi iku ọrẹbinrin rẹ.

Ni oṣu Karun un ni wọn yoo gbe idajọ yii kalẹ lẹkunrẹrẹ.

Ni ita ile ẹjọ, n ṣe ni awọn mọlẹbi arabinrin Pule ti wọn ṣeku pa n sunkun, ti wọn si n kọrin ayọ pe idajọ ododo ti fẹsẹ mulẹ.

Wọn ni oyun akọkọ ni oloogbe naa gbe sinu ki wọn to da ẹmi rẹ legbodo.

Iku arabinrin Pule mu ki awọn eeyan bẹrẹ ipolongo loju opo Twitter pẹlu hashtag #JusticeForTshego

Ninu esi rẹ si ọrọ yii, aarẹCyril Ramaphosa fi atẹjade sita, to si ni ajakalẹ Coronavirus ti jẹ ki awọn obinrin wa ninu ewu ju tatẹyinwa lọ.

O ni idi ni pe ''awọn ọkunrin alaburu n lo asiko yii lati fiya jẹ tabi ṣe ikọlu si awọn obinrin ati ọmọde nitori wọn ko ribi jade sita kuro ninu ile''

Atẹjade aarẹ tẹsiwaju pe ''O kere tan ida mọkanlelaadọta ninu ọgọrun obinrin to wa ni South Afrika, lo ti koju ijiya kan tabi omiran lọwọ awọn ti wọn dijọ n fẹra .''

Ntuthuko Ntokozo Shoba

Oríṣun àwòrán, Twitter/ @NPA_Prosecutes

Àkọlé àwòrán, Aworan arakunrin Shoba ti wọn ni ko fẹ ki iyawo ile rẹ mọ pe oun funeeyan loyun nita