APC National Convention: Àwọn olóyè APC tuntun fojú hàn lẹ́yìn ìpàdé àpapọ̀ ní Abuja

Lọjọ Satide ni awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP panupọ kede pe gomina tẹlẹ nipinlẹ Nasarawa, Abdullahi Adamu ni alaga apapọ fẹgbẹ oselu naa.
Adamu si ni awọn oludije yoku panupọ fi ohun sọkan le lori lẹyin ti wọn yọwọ yẹsẹ kuro ninu idije naa.
Awọn alatako Adamu to juwọ silẹ ni George Akume lati Benue, Tanko Al-Makura lati ipinlẹ Nasarawa ati Abdul'Aziz Yari lati Zamfara.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ajá pa ọmọ olówó rẹ̀ láàrin ọ̀sẹ̀ kan tí wọn rà á
- "N kò ṣẹ̀wọ̀n ọdún méjì o, ₦1m nílé ẹjọ́ ní kí ń san"
- Ọ̀rẹ́kùnrin sanwó ẹ̀mí ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ fún agbanipa torí pé ó lóyún fún-un
- Abdulahi Adamu di alága àpapọ̀ tuntun fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC
- Lẹ́yìn ò rẹyìn, Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ ìpèsè ìrànwọ́ fún Ukraine lórí ìkọlù Russia
- Fayemi, Oyetola, Ganduje gúnlẹ̀ síbi ètò ìdìbò láti yan adarí APC l'Abuja
- Ọwọ́ tẹ Pásítọ̀, afurasí tó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn búrọ́dà ṣọ́ọ̀sì mẹta láti ìdí ẹ̀yìn
- Agbébọn ṣé ikọlù sí pápákọ̀ òfurufú Kaduna, èèyàn kàn kú níbẹ
- Ọ̀rọ̀ tí Kemi Afolabi sọ síta lẹ́yìn táwọn kan ráńṣẹ́ síi torí ìtọ́jú àìsàn Lupus tó ní
- Olùdásílẹ̀ ìjọ méjì di afurasí tó pa ọmọ ìjọ lásìkò ìsìn, wo bí wọ́n ṣe sin òkú rẹ̀ láì sọ f'Ọ́lọ́pàá
Awọn yoku ni Sani Musa lati Niger, Saliu Mustapha lati Kwara ati Etsu Muhammed lati Niger.
Bakan naa ni igbakeji gomina tẹlẹ nipinlẹ Osun, Iyiola Omisore ti di akọwe apapọ fẹgbẹ APC.
Ọpọ awọn oloye ẹgbẹ tuntun miran si lo foju han nibi ipade apapọ ẹgbẹ oselu APC naa to waye lọjọ Satide nilu Abuja.
Awọn oloye ẹgbẹ APC tuntun:
- Abdullahi Adamu - Alaga apapọ ẹgbẹ APC
- Iyiola Omisore - Akọwe apapọ APC
- Ijeoma Arodiogwu - Igbakeji Alaga fẹkun ila oorun guusu
- Victor Giadom - Igbakeji Alaga fẹkun aarin gbungbun guusu
- Senator Abubakar Kyari (Borno) - Igbakeji Alaga fẹkun Ariwa
- Emma Eneukwu (Enugu State) - Igbakeji Alaga fẹkun guusu
- Festus Fuanter - Igbakeji Akọwe apapọ
- Isaac Kekemeke - Igbakeji Alaga fun ẹkun iwọ oorun guusu
- Muhazu Rijau - Igbakeji Alaga fẹkun aarin gbungbun Ariwa
- Mustapha Salihu - Igbakeji Alaga fẹkun ila oorun Ariwa
- Salihu Lukman - Igbakeji Alaga fẹkun iwọ oorun Ariwa
- Ahmed El-Marzuk - Amofin apapọ fẹgbẹ APC
- Uguru Ofoke - Akapo apapọ ẹgbẹ
- Bashir Gumel - Akọwe Olusiro owo
- Suleiman Argungu - Akọwe alaato ẹgbẹ
- Abubakar Maikafi - Oluyẹwe Owo Agba fun APC
- Ibrahim Salawu - Igbakeji Amofin apapọ fẹgbẹ APC
- Omorede Osifo - Igbakeji Akapo ẹgbẹ
- Beta Edu - Olori apapọ fun igun awọn obinrin fun APC
- Abdullahi Israel - Olori igun awọn ọdọ
- Tolu Bankole - Asaaju awọn akanda ẹda
- F.N Nwosu - Akọwe apapọ feto idẹrun awọn ọmọ ẹgbẹ
- Felix Morka - Akọwe Ipolongo ẹgbẹ

Fayemi, Oyetola, Ganduje gúnlẹ̀ síbi ètò ìdìbò láti yan adarí APC l'Abuja

Oríṣun àwòrán, Facebook/Gov. Abdullahi A. Sule Mandate
Awọn eekan lẹgbẹ oṣelu APC ti n de sibi eto idibo lati yan awọn adari apapọ ẹgbẹ oṣelu naa lorilẹede Naijiria.
Eto idibo naa to n waye ni gbagede Eagle Square nilu Abuja ni wọn yoo ti yan awọn adari bii alaga apapọ, igbakeji alaga apapọ akọwe apapọ atawọn ipo miran nigbimọ isakoso ẹgbẹ oṣelu naa.
Lara asiwaju ẹgbẹ oṣelu naa to ti de Ni alaga apapọ tẹlẹ, Adams Oshiomole, gomina ipinlẹ Ọṣun, Isiaka Oyetọla; gomina ipinlẹ EkitiKayode Fayẹmi, minisita feto iroyin, Lai Mohammed; pẹlu Gomina ipinlẹ Ẹbonyi David Umahi.
Awọn miran to tun ti wa ni gbagede naa bayii ni gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje ati igbakeji rẹ; omina Bello ti ipinlẹ Kogi; Gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ, Rochas Okorocha, minisita tẹlẹ, Fani Kayode; gomina ipinlẹ Plateau, gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ, to ti wa di minisita feto irinna bayi, Rotimi Amaechi atawọn eekan miran.
Fọfọ ni gbagede naa kun bayii fun awon aṣoju kaakiri ipinlẹ mẹrẹẹrindinlogoji to wa ni Naijira ati olu ilu rẹ Abuja.
Gbogbo eto naa ti n gbinaya ati bẹrẹ bayii.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Gov. Abdullahi A. Sule Mandate


Ètò ìdìbò láti yan adarí APC kò tíì bẹ̀rẹ̀ l'Abuja
Eto ṣi n lọ nibi idibo lati yan awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC ni gbagede Eagles Square nilu Abuja.
Lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, awọn aṣoju lati ipinlẹ kọọkan ṣi n wole si gbagede naa ni eneeni ejeeji.

Lara awọn ti yoo wa nikalẹ ti wọn si n reti nibi eto naa ni aarẹ, Ọgagun fẹyinti Muhammadu Buhari, igbakeji rẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo, aarẹ ile aṣofin, Sẹnatọ Ahmad Lawan, olori ile aṣofinṣoju Họnọrebu Femi Gbajabiamila, awọn gomina ipinlẹ atawọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC lorilẹede Naijiria.

Bi gbogbo eto ati igbaradi ṣe n lọ labẹ lawọn olugbe ilu Abuja pẹlu n fi oko kan pẹyẹ meji ti wọn sọ agbegbe gbagede naa di ibi ipatẹ oniruuru ọja.

Bẹẹ si lawọn miran to ba awọn aṣoju kọọkan pẹlu wa n ṣe oniruru ayẹyẹ lati fi aṣa ibi ti wọn ti wa han.
Gbagbagba lawọn agbofinro wa kaakiri lati rii pe eto abo ko mẹhẹ, paapaa julọ bi o ṣe jẹ wipe aarẹ orilẹede Naijiria Pẹlu yoo wa nibi eto naa.

Wó àwọn nǹkan tí àwọn ènìyàn ń f'ojú sọ́nà fùn ún níbi àpérò ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó ń wáyé lónìí

Lónìí ọjọ́ Àbámẹ́ta ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹta, ọdún 2022 ní àpérò àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) yóò wáyé ní gbọ̀ngán ńlá Eagles Square tó wà ní Abuja.
Gbogbo ètò ló sì ti to láti mú kí àpérò náà níbi tí wọn yóò ti máa àwọn adarí ẹgbẹ́ tuntun tí yóò máa darí ẹgbẹ́ APC fún ọdún mẹ́ẹ̀rin mìíràn.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èrò ló ti ń rọ́ tìkẹ́ tìkẹ́ níbi àpérò náà èyí tí wọ́n ti sún fún ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún ìdí kan tàbí èkejì.
Kò dín ẹgbẹ̀rún méjìlá aṣojú ọmọ ẹgbẹ́ APC káàkìri àwọn ìpínlẹ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni ìrètí wà wí pé wọn yóò kópa níbi àpérò náà.
- Ìdìbò àwọn adarí ẹgbẹ́ APC yóò wáyé ní Sátidé, wo àwọn ọmọ Yorùbá tó ń díje
- Ọmọ ìyá kan nàá mẹ́ta di àwátì ní ilé-ẹ̀kọ́ aládàní nílùú Abuja
- Igun ìkejì ẹgbẹ́ òṣèlú APC ìpínlẹ̀ Oyo ṣé ibura sípò fún alága tí wọ́n
- Ọwọ́ tẹ Pásítọ̀, afurasí tó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn búrọ́dà ṣọ́ọ̀sì mẹta láti ìdí ẹ̀yìn
- Olúwa mi, kò tọ́ ká bẹ ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ wò lára baba; Ẹ ṣọ́ra fún ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn lórí ayelujára o!- Agbẹjọ́rò Ramon Adedoyin
- Ọkùnrin kan fípa bá obìnrin tó sùn sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ̀ lòpọ̀! Wo bí gbẹgẹdẹ ṣe gbiná
- Olùdásílẹ̀ ìjọ méjì di afurasí tó pa ọmọ ìjọ lásìkò ìsìn, wo bí wọ́n ṣe sin òkú rẹ̀ láì sọ f'Ọ́lọ́pàá
Àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ ń forí korí láti fa ọmọ ẹgbẹ́ kan kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alága
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé BBC News Yorùbá kò ì tíì le fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ̀ ni ẹgbẹ́ ti pinnu láti fa ọmọ ẹgbẹ́ kan kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alága gẹ́gẹ́ èrò Ààrẹ́ Muhammadu Buhari, ohun tí à ń gbọ́ ni pé àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ APC ti ń forí korí láti fẹnukò lórí èrò Ààrẹ.
Ipò mẹ́rìndínláàdọ́rin ní gbogbo ipò tó ṣí sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ láti dìmú.
Ètò àpérò yìí yóò kó ipa ńlá lórí ìjáwé olúborí níbi ètò ìdìbò àpapọ̀ ọdún 2023 àti [pé ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ẹgbẹ́ yóò ṣe àpérò àpapọ̀ lẹ́yìn tí Adam Oshiomole fi àpèrè kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alága ẹgbẹ́.
Kìní àwọn nǹkan láti fojú sọ́nà fún níbi àpérò náà?
Kò sí àníàní wí pé àárín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC kan kò gún pàápàá ní àwọn ìpínlẹ̀ tí ẹgbẹ́ APC ti ń ṣe ìjọba.
Ní irúfẹ́ àwọn ìpínlẹ̀ yìí, àwọn ètò ìdìbò tó wáyé sí àwọn ní wọ́ọ́dù, ìjọba ìbílẹ̀ àti ìpínlẹ̀ ló ní kọ́nú n kọ́họ nínú tó sì ń fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye láàárín àwọn ẹgbẹ́.
Kódà ní àwọn ìpínlẹ̀ yìí, igun oríṣi méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ń fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí alákóso ẹgbẹ́.
Ìbéèrè tó ń wá sọ́kàn àwọn ènìyàn ni wí pé báwo ni àwọn ènìyàn tí ìfa nfà ń wáyé láàárín yìí yóò ṣe ṣe ọ̀kan níbi àpérò yìí.
Lára wọn nìyìí:
Gómìnà Abulrahmon Abdulrasaq ti ìpínlẹ̀ Kwara àti Mínísìta fétò ìròyìn orílẹ̀ èdè yìí, Lai Mohammed.
Kò sí àríyànjiyàn wí pé àwọn igun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn èèkàn méjéèjì nínú ẹgbẹ́ òsèlú APC ìpínlẹ̀ Kwara ń ṣe, tí oníkálùkù wọn sì ní àwọn alága tí wọ́n ń tẹ̀lé.
Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn méjéèjì ti ju òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn.
Báwo ní àwọn méjéèjì yóò ṣe ara wọn sí níbi àpérò àpaps yìí ní ìbéèrè yó gba ọkàn àwọn ènìyàn.
Gómìnà Gboyega Oyetola àti Mínísítà Rauf Aregbesola
Àwọn méjéèjì lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí kò kòólà rárá lórí ta ni yóò máa darí ẹgbẹ́ ní ìpínlẹ̀ Osun.
Láìpẹ́ yìí ni àwọn méjéèjì tahùn síra lórí ètò ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà bní ìpínlẹ̀ náà kí Oyetola tó jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò díje fún ipò gómìnà fún sáà kejì níbi tó ti fi ìdí Moshood Adeoti ti Aregbesola fa kalẹ̀ janlẹ̀.
Àwọn mìíràn tí àwọn ènìyàn yóò tún fojú sọ́nà fún ni:
- Rotimi Amaechi àti Magnus Abe
- Dapo Abiodun àti Ibikunle Amosun
- Yari, Matawale àti Marafa
- Ganduje àti Shekarau




















