John Oyegun kò ní dije Alága APC

Oríṣun àwòrán, @APCNigeria
Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC lorílè-èdè Nàìjíríà Ọgbẹni John Odigie-Oyegun ní òun ko ni du ipò Alága ẹgbẹ́ nínú ìpàdé gbogboògbò ẹgbẹ́ tó n bò lónà.
O kéde ọrọ̀ náà nígbà tí o n ba àwọn akoroyin sọrọ l'Abuja.
Oyegun ni òun o fe je ìṣòro tí ẹgbẹ́ yóò máa wa ona abayọ si.
"Fún ìdí èyí ni mo fi jáwọ kúrò nínú ìdíje fún ipò Alága ẹgbẹ́"
Odigie-Oyegun ní eléyìí ko ni jẹ idiwọ fún titẹsi waju ṣíṣe iṣẹ òun gẹ́gẹ́ bíi Alága ẹgbẹ́ títí di ọjọ keedogbon, osu kefa ti sáà òun yóò wá sí òpin.
Kò tíì dájú òun tó mú gbé ìgbésẹ yi lẹyìn alaye tó ṣe ṣùgbọ́n àwọn kan ní ọ gbe ìgbésẹ náà lẹyìn tó ṣe ìpàdé pẹlú Ààrẹ Buhari lọjọ kerindinlogbon, oṣù kẹrin.








