Husand, wife kidnap baby: Tọkọtaya kó sí gbaga ọlọ́pàá fẹ́sùn jíjí ọmọ ọjọ́ mẹ́fà gbé

Àwọn afurasí

Oríṣun àwòrán, Punch

Àkọlé àwòrán, Àwọn afurasí

Ìyàwó ilé kan ní ìlú Iwo, ìpínlẹ̀ Osun, Ganiyat Abass àti ọkọ rẹ̀ Olatunbosun ti kó sí gbaga àjọ ọlọ́pàá fẹ́sùn jíjí ọmọ ọjọ́ mẹ́fà gbé.

Ní ọjọ́ Ẹtì ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ọdún 2022 ní Kọmíṣọ́nà àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun, Wale Olokode fojú àwọn afurasí tọkọtaya náà hàn.

Olokode ṣàlàyé pé àwọn afurasí tọkọtaya náà jí ọmọ náà gbé ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹrìnlélógún lọ́wọ́ ìyá rẹ̀, Jemilat Musa ẹni tí ó ní ìpèníjà ìlera nígbà tí wọ́n fún un ní ẹ̀kọ àti igba náírà láti fi ra àkàrà.

Ó ní ní kété tí Jemilat dìde láti lọ ra àkàrà ni Ganiyat gbé ọmọ náà sínú àpò tó sì sá lọ ṣùgbọ́n tí ọwọ́ tẹ̀ ẹ́ pẹ̀lú àjọṣepọ̀ JTF.

Mí ò gbèrò láti jí ọmọ náà gbé - afurasí

Nígbà tí ó ń dáhùn ìbéèrè lọ́wọ́ àwọn akọ̀ròyìn, Ganiyat, tí kò ì tí bímọ, ní òun kò gbèrò láti jí ọmọ náà gbé.

Ganiyat ṣàlàyé pé ilé kan náà ni òun àti ìyá ọmọ náà ń gbé, àti pé òun ra ẹ̀kọ fún un ó sì bèrè owó tí yóò fi ra àkàrà.

"Mo fun ní igba náírà láti lọ fi ra àkàrà, ṣùgbọ́n ní kété tó lọ tán ni ọmọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún, gbogbo ọgbọ́n tí mo dá láti fi rẹ̀ ẹ́ dákẹ́ ló jásí pàbó."

"Ìdí nìyí tí mo fi gbe láti máa lọ sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi ní agbègbè Agbowo ní nǹkan bí aago mẹ́jọ alẹ́ ṣùgbọ́n mó sọnù lọ́nà níbi tí mo ti ń bèrè ọ̀nà ni wọ́n ti fẹ́sùn kàn mí wí pé mo jí ọmọ gbé ni."

Àkọlé fídíò, Sanni Iyabo Paramount Komedy: Ibi tí mo ti rí àwọn ọfọ̀ apanilẹ́rìín tí mò ń lò nínú 'skit

Wọn yóò fojú balé ẹjọ́ láìpẹ́

Yàtọ̀ sí àwọn tọkọtaya yìí Kọmíṣọ́nà tún fi ojú àwọn afurasí gẹ́gẹ́ bí oníjìbìtì mìíràn , Olaolu James àti Favour Ige hàn.

Bákan náà ló tún fojú àwọn afurasí gẹ́gẹ́ bí ìgárá ọlọ́ṣà mẹ́rin, Agbebaku David, Olubunmi Adewale, Oderinde Oluwaseun àti Oluwaseun Adejuyigbe hàn.

Olokode ní gbogbo àwọn afurasí ni wọn yóò fojú ba ilé ẹjọ́ ní kété tí ìwádìí bá ti parí.

Àkọlé fídíò, Ọwọ́ mi méjèjì ni Fulani gé jábọ́, wọn ò tilẹ̀ jẹ́ kí n rí ìbọn gbèjà ara mi - Fijilante