World TB Day: Àwọn nǹkan tó ṣe koko tó o le má mọ̀ nípa ikọ́ọfe

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarun ikọ fee jẹ ọkan gbogi ailera ti o maa n ṣakoba fun ẹdọ fooro lara awọn to ba lugbadi rẹ.
Kokoo aifojurikan lo maa n fa aarun yi taa mọ si Mycobacterium tuberculosis.
Yatọ si ẹdọ fooro, a tun maa ṣe akoba fun kidinri, ẹgun ẹyin ati ọpọlọ eeyan.
O ni awọn nkan miran tio o y ki o mọ nipa aarun yi, di ree ninu wọn.
Orisi meji ikọ fee lo wa
Ninu alaye tawọn onim sayẹnsi sọ, meji ni ikọ fee pin si.
Akọkọ leleyi ti kii ran taa mọ si LatentTB ti ẹlẹkeeji si jẹ eyi to maa n ran ka,
Ẹni to ba ni eleyi ti kii ran yi kii se afihan apẹr kankan koda o le ma rẹ iru ni bẹẹ.
Ko wọpọ ki ẹni to ni iru ikọ fee yi ko ran lomiran.Pupọ awọn to ni iru ikọ yi, aywo ẹjẹ tabi awọ wọn lo le fihan pe wọn ni iru ikọ yi
Itọju ṣe pataki fun iru ẹni bayi ki ikọ to ni yi ma ba di eleyi ti yoo tan kaakiri.
Lalae gba itọju ida 5-10 awọn to ni ikọ fee yi lo le pada wa ni ikọ fee gangan lọjọ iwaju.
Two types of TB exist - Latent TB infection (non-infectious) and TB disease (infectious).
Ikọ fee ojulowo
Ninu awọn apẹrẹ to maa n se afihan pe eeyan ni ikọ fee ni pe yoo maa wukọ ẹjẹ ti aya a si maa ta iru eeyan bẹẹ.
Irufẹ awọn to ni iru ikọ yi a maa ru, wn a maa laagun lalẹ, iba a maa daamu wọn pẹlu otutu ti yoo si maa tete rẹ wọn.
Itọju wn a maa gba to nkan bi oṣu mẹfa ti wọn a si maa fun wọn ni orisirisi oogun lati fi koju ikọ yi
Ikọ yi jẹ ọna kan gbogi to n fa iku awọn to ni aisan HIV.Awọn to ba ni itọ ṣuga naa wa ninu ewu ikọ fee
Inu afẹfẹ lawọn eeyan n gba ko ikọ fee
Bieeyan ba sin lẹgbẹ rẹ towukọ to sọrọ tabi to kọrin, ti o ba ni ikọ fee, ọna ree ti wọn fi le tan kokoro aifojuri ikọ yi ka.
Bi eeyan ba pin ounjẹ to ba ọwọ tabi to fọwọ kan awo ile igbọnsẹ ko le ti atibẹ ko ikọ fee.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọdun 2019 nkan bi miliọnu mẹwaa eeyan lagbaye lo ko ikọ fee ti awọn miliọnu 1.4 to fi mọ awọn to ni HIV padanu ẹmi wọn gba tọwọ ikọ yi
Okere tan eeyan biliọnu meji, ida kan iye eeyan to wa lagbaye ni wọn ni ikọ fee eleyi ti kii foju han.
Naijiria ati ikọ fee
Lọdọọdun ni Naijiria eeyan 245,000 lo maa n padanu ẹmi wọn lọwọ ikọ fee .
Awọn to maa n ṣẹṣẹ lugbadi rẹ si jẹ nkan bi 590,000.Ninu onka yi, awọn to ni HIV ninu wọn a si maa to 140,000.
Ni akọsilẹ TB ko ida mẹwaa ninu ida ọgọrun aisan to n ṣeku pa awọn eeyan ni Naijiria.
Njẹ abẹrẹajẹsara wa fun ikọ fee?
Ajọ ilera lagbaye WHO d gba awọn eeyan ni imọran lati gba abẹrẹ ajẹsara BCG nigba kigba ti wọn ba ṣi wa ni ikoko.
Ṣugbọn ni orileede Naijiria to se pe ajakalẹ aarun yi peleke, ni kete ti wọn ba ti bi ọmọ ni wọn ti maa n gba fun wọn ni ile iwosan ki ọmọ naa to ṣalabapade kokoro to n fa ikọ yi.















