Diabetes treatment and management: Wo àwọn ọ̀nà tí o lè gbà dènà gígé ẹsẹ̀ rẹ bí o bá ní ìtọ̀ ṣúgà

Àkọlé fídíò, Diabetes Ulcer

Osarekhoe Ethel Chima Onwugwugwu to ti ni aisan ito suga lati ogun ọdun o le, lo gbalejo BBC to si sọ iriri rẹ́.

Osarekhoe gba awon eeyan niyanju lori ohun ti aisan naa n fa si ara ati igbesẹ to yẹ ni gbigbe ni kete too ba ti ni aisan naa.

O salaye pe ninu oyun ọmọ rẹ keji lo ti kọ́kọ́ ni aisan naa ki o to di pe o pada bi ọmọ marun un ti wọ́n jẹ obinrin lantilanti lapapọ̀.

Osarekhoe jẹ́ ẹni ọdun mejilelaadota

Kini awon eleto ilera sọ nipa itọ ṣuga?

Dokita Afoke Isiawen to jẹ́ akọṣẹmọṣẹ nipa itọju aisan itọ ṣuga ṣalaye ni kikun lori itọju to yẹ

Bakan naa lo sọ nipa irufẹ bata to yẹ ki ẹni to ni itó ṣuga maa wọ.

Ati iru ohun to yẹ ki alaisan itọ ṣuga maa ṣe fun ara rẹ nile ati nile iwosan pẹlu awọn ohun ti ko yẹ ni ṣiṣe bii fifi bileedi ge eekanna rẹ.

Akosemose yii salaye fun Oyeyemi Gbenga-Mustapha to jẹ́ akoroyin BBC siwaju sii nipa igbese to ye ki eni to ni itọ suga maa gbe ni kete to ba ti mọ̀.