Man rapes sleeping woman: Wo bí ọkùnrin yìí ṣe ríbi fípa bá obìrin kan lòpọ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ̀

Aworan ọkunrin ati obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

"Mo rán o ní ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà nítorí o bá obìnrin yìí lòpọ̀ níbi tó sùn sí lẹ́gbẹ́ ọkọ rẹ̀, o tún ya fídíò rẹ̀".

Okùnrin naa tó ya fídíò bó ṣe bá obìnrin kan lòpọ̀ lẹ́gbẹ́ ọkọ rẹ̀ lo n fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà jura.

Arakunrin ọhun ri ẹwọn ọdun mẹfa he lẹyin to ya fidio ara rẹ nibi to ti n ba obinrin kan ni ibalopọ nibi to sun si lẹgbẹ ọkọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Sanni Iyabo Paramount Komedy: Ibi tí mo ti rí àwọn ọfọ̀ apanilẹ́rìín tí mò ń lò nínú 'skit
Àkọlé fídíò, Tóò bá fún ọkùnrinn lóúnjẹ́ tóo tẹ́ kiní yẹn sílẹ̀ fún un dáadáa... - Yinka TNT

Daniel Smith fi ipa ba obinrin ọhun lopọ lẹyin ti obinrin naa ati ọkọ rẹ gba a laaye lati sun mọju nile wọn lọjọ kejila, oṣu Kinni, ọdun 2020.Bo tilẹ jẹ pe o ni oun ko jẹbi ẹsun naa, adajọ ni o jẹbi lẹyin to foju ba ile ẹjọ.

Ọkunrin ati obinrin

Oríṣun àwòrán, Fox

Àkọlé fídíò, 'Tóo bá lè bá mi jà, ìwọ wá!' Ademodi Maria tó lu ọmọdékùnrin mìí lálùbami rèé

Adajọ Lord Beckett ti ile ẹjọ giga kan ni Glasgow ni ikọlu ti Smith ṣe si obinrin naa lọjọ naa lọhun ti yi igbe aye rẹ pada kuro ni bo ṣe n gbe tẹlẹ ati pe nnkan ko rọrun fun un mọ lati ọjọ naa wa.Adajọ ni "wọn fun ọ ni ibusun to rọ ọ lọrun, o jẹun yo tan amọ o tun n bẹkun-bẹkun kiri.""O kọkọ ba obinrin naa ni ibalopọ nibi to sun si lẹgbẹ ọkọ rẹ.""Lẹyin naa, o tun ya aworan fidio ati fọto bi o ṣe n hu iwa ọdanran naa."

Ile Ẹjọ

Oríṣun àwòrán, PA Media

Ile ẹjọ sọ pe ẹri fi han pe ọdaran naa ba obinrin ọhun ni nnkan pọ, amọ o ni kii ṣe ipa ni oun fi ba obinrin naa ni ajọṣepọ."Yatọ si pe adajọ ran an ni ẹwọn ọdun mẹfa, wọn tun fi orukọ rẹ si inu iwe orukọ awọn afipabanilopọ.Ẹwẹ, iwadii fi han pe ọkunrin naa maa n hu iwa ipa ninu ile tẹlẹ ki akara rẹ to tu sepo.

Àkọlé fídíò, 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'