OAU VC: Wọ́n lù wá, wọ́n gbé ẹbọ wọ OAU, àfi kí wọ́n dáwọ́ ìfẹ̀hónùhàn oníṣẹ̀ṣe yìí dúró o - SUG

Awọn ọmọ ile-iwe Obafemi Awolowo ti jade lati rawọ ẹbe sí awọn ọmọ abinibi ati awọn olugbe ilu ile Ife lori rògbòdìyàn to waye ni ile ẹkọ wọn.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ṣe pẹlu BBC Yoruba, alukoro ẹgbẹ awọ ọmọ ile ẹkọ Fasiti OAU ni oriṣiriṣi nkan to ba ni ninu jẹ lo n tara ifhonuhan naa jade.
"Wọn ko fi ifhonuhan wọn mọ nibi ki wọn pariwo nikan, wọn n daya ja oriṣiriṣi akẹkọọ, ohun taa fẹ ni ki wọn yanju ọrọ laarin ara wọn ki wọn jẹ ki awọn akẹkọọ ri imu mi".
A ri wọn ti wọn wọ inu gba pẹlu oriṣiriṣi nkan bii ẹbọ egungun ti wọn si n pe awọn ede ibilẹ koda, wọn n lu awọn akẹkọọ".
Awọn akẹkọọ Ile Iwe giga Obafemi Awolowo University, OAU Ile-Ife wa rawọ ẹbẹ sí awon ọmọ araalu Ife lati tẹle ilana to yẹ ki wọn le ri ọmọ bibi ilu gẹgẹ bi igbakeji ọga agba ile iwe giga naa.
Awon ọmọ ile iwe giga yii n bẹbẹ lẹyin ifehonuhan to n lọ lọwo ninu ọgbà ile iwe wọn ti awọn ọmọ onílùú ati awọn oloosa n fi ifẹhonuhan lori yiyan ọga àgbà tuntun ti ile-ẹko giga naa.
Gẹgẹ bi Ogunperi Taofeek Olalekan (TAO) Alukoro awọn akẹkọ ile-iwe naa to ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ, o wi pe isẹlẹ naa ko ba idagbasoke eto ẹkọ ati awọn iṣẹ ti kii ṣe ara eto-ẹkọ ti ogba ile iwe naa.
Ki ni iha ti awọn akẹkọọ kọ si VC ti kii ṣe ọmọ ilu ti wọn ṣẹṣẹ yan?
Taofeek sọ lorukọ awọn akẹkọ to ku pe ọga agba ileewe ti wọn ba yan lee jẹ ara ilu o si le jẹ ara ita amọ eyi ko yọ awọn akẹkọọ lẹnu niwọn igba ti awọn to wa nidi akoso rẹ ba ti ṣe iṣẹ bo ṣe tọ labẹ ofin amọ ko jẹ ohun to maa tu awọn lara.
Alukoro awon akẹkọ náà fi ye wa wipe awọn Ọmọ onílù ti ikede ọga agba tuntun fún ile-iwe gíga Obafemi Awolowo ti ko tẹ lọrun n di ẹnu-ọna ile-iwe to ṣe idiwọ fun ọkọ ati eniyan lati wọle ati jade kuro ninu ọgba naa.
A o ranti pe wahala naa bere lọsẹ to kọja lẹyin ti wọn yan Ọjọgbọn Adebayo Bamire gẹgẹ bii Ọga agba ile-ẹko giga Obafemi Awolowo, OAU nigbati Ọjọgbon Eyitope Ogunbodede pari saa tirẹ.
Awọn akẹkọ rawọ ẹbẹ si àwọn ọmọ ìlú Ilé-Ifẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe gbé apẹrẹ búburú kalẹ̀ ní ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́.
Gbogbo igbinyànjú wa lati ba oṣiṣẹ to jẹ alukoro ile-ẹko giga Obafemi Awolowo s'ọrọ lo ja si wipe awọn ko le ba oniroyin kankan sọrọ fún àwọn ìgbésẹ tó n lọ lọwọ lati dẹkùn rògbòdìyàn náà.
Ìkọ Iroyin BBC Yoruba tẹsiwaju lati bá àwọn olooṣa to fehonuhan ninu ọgbà ile ẹko naa sọrọ ti a sì gbọ wipe wọn ní ìpàdé pẹlu Ọba Adeyeye Ogunwusi Ojaja keji amọ pabo lo ja si.
Taofeek wa rọ awọn akẹkọ ẹgbẹ rẹ pe ki wọn sa kuro nibi ti wahala ba wa.















