Church founders allegedly kill member in fellowship: Bí olùdásílẹ̀ ìjọ méjì ṣe sin òkú ọmọ ìjọ láì sọ f'Ọ́lọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Ogun Police
Àwọn olùdásílẹ̀ ìjọ tó ṣekúpa ọmọ ìjọ àtàwọn afurasí míì kó sí gbaga ọlọ́pàá l'Ogun
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi oju afurasi ọdaran marundinlogun lede lori oniruru ẹsun bii idigunjale, ipaniyan, ijinigbe atawọn ẹsun mii.
Kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Lanre Bankole to fi oju awọn afurasi naa lede ni Eleweran, niluu Abeokuta sọ pe ọwọ awọn tẹ awọn afurasi naa kaakiri ipinlẹ ọhun.
O ni awọn oṣiṣẹ oun mu awọn afurasi marundinlogun pẹlu oniruru ohun ija oloro lọwọ wọn.
Bankole ni awọn mu afurasi kan to pa okunrin kan to jẹ Fulani, to si sin oku rẹ sinu oko rẹ niluu Ewekoro.
O ni awọn ti wu oku naa, awọn si ti gbe lọ si ile igbokupamọsi to wa niluu Ifo fun ayẹwo ati iwadii.
Kọmiṣọna naa tẹsiwaju pe "Nigba ti o ta siwa leti pe okunrin kan, Saheed Ogudahun to jẹ ọdẹ, lọwọ ninu ipaniyan naa, ni a lọ fi ṣikun ofin mu."
"Ninu ifọrọwanilẹnuwo ni agọ wa, o jẹwọ pe lootọ ni oun dana ibọn ya oloogbe naa ti oun si sin oku rẹ sinu igbo."
Kàyééfì! Àṣírí ìyá àti ọmọkùnrin rẹ̀ tó jí ọmọ ọlọ́mọ gbé fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó f'ọ́dún mẹ́ta tú l'Ekiti
Ileeṣẹ ọlọpaa naa tun fi oju awọn ajinigbe meji lede, Sulaimon Mohammed ati Jato Bello, ti awọn mejeji jẹ ẹni ogoji ọdun.
Bakan naa ni wọn fi oju awọ afurasi mii lede, Chidi Samuel ati Paul Zakari, ti wọn jẹ oludasilẹ ijọ Life Builders Network, lori ẹsun pe wọn ṣekupa ọmọ ijọ wọn, Favour Okumazor, ni abule Oyan, to wa ni Imala, ni iha Ariwa Abeokuta.
Bankole ni awọn afurasi naa ko awọn ọjẹ wẹwẹ kan bii meje kuro ni akata awọn wọn lọ fun ẹkọ Bibeli lọna ati ji wọn gbe lọ.
Amọ aṣiri wọn tu lẹyin ti ọkan lara awọn ọmọ naa ke gbajare lọ ba awọn obi rẹ.
Amọ ni igbẹyingbẹyin, akara wọn tu sepo, gbogbo si ti wa ni akata awọn ọlọpaa bayii ti wọn yoo si boju bale ẹjọ lẹyin iwadii.

















