Mother allegedly set daughter ablaze in Ogun: Ó gbẹnután! Ìyá da bẹntiró sí ará ọmọ ọdún mẹ́wàá tó sì dáná sun ún

Oríṣun àwòrán, Ogun Police Command
Bi wọn ba pe eeyan ni abiyamọ, gbogbo ọna ni onitọun yoo maa wa lati fi daabo bo ọmọ rẹ.
Koda ki aburu fẹ se ọmọ naa, iya rẹ ni yoo fi ara rẹ lelẹ lati faragba irufẹ ijamba yi.
Aimọye iroyin la si ti gbọ nipa iya to fẹmi rẹ dipo ti ọmọ wọn ki nkankan ma ba se ọmọ naa.
- Wo ọkùnrin tó dáná sun ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ torípé kó gbà látí jẹ́ aya rẹ̀
- 'Dẹ́rẹ́bà BRT tí Bamise wọ̀ ti fipá bá obìrin míì lòpọ̀ rí ní 2021', ohun tí ìwé ẹ̀sùn rẹ̀ tún ṣàfihàn lónìí rèé
- Ẹrin Ijesa, Ọ̀ṣun Oṣogbo, àtàwọn ibùdó ìgbafẹ́ omi nílẹ̀ Yorùbá tó yẹ kí o mọ̀
- 'Ẹnikẹ́ni tó bá leè fihàn mí pé oògùn owó ń jẹ́, mo máa fún ní #2.5m!'
Pẹlu ohun taa sọ ṣaaju yi, niṣe lo jẹ iyalẹnu fawọn ara adugbo Mowe ni ipinlẹ Ogun nigba ti iroyin gbode pe wọn fura si iya kan to da bẹntiroo si ara ọmọ rẹ to si dana sun un.
Iya taa n wi yi bi ọmọ marun un ṣugbọn ṣaadede lo kan da ina sun ọkan ninu wọn to jẹ ọmọdebinrin ẹni ọdun meji .

Kini ọlọpaa sọ si ọrọ yi?
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun lo fidi ọrọ yi mulẹ fun ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba nipa atẹjade kan ti alukoro Abimbola Oyeyemi fi sita.
Oyeyemi ṣalaye pe afurasi naa, Aisha Tijani ni eeyan kan wa fẹjọ rẹ sun ni agọ ọlọpaa toi wa ni Mowe pe o ti ṣe nkan to gbẹnutan.
Moroof Ayinde lorukọ alabagbe Aisha Tijani yi to sọ fun awọn ọlọpaa pe Aisha fi ibinu da bntiroo si ara ọmọde naa to si dana sun un.
Gẹgẹ bi alaye rẹ, Aisha n binu tori pe ọmọde naa lmu foonu to gbe pamọ kuro nibi to wa to si gbe fun ọmọ ti mama rẹ gba lọwọ rẹ ṣaaju.
Kete ti ọrọ yi de eti igbọ awọn ọlọpaa ni wọn gbe ọmọ naa lọ si ile iwosan to wa ni itosi ti wọn si ti ati ibẹ ni ki wọn gbe lọ si ile iwosan fasiti Olabisi Onabanjo.

Mi o mọ ohun to mu mi hu iru iwa yii
Ki ni o mu iya hu iwa bayii ni ibeere ti ọpọ n tẹnumọ nigba ti wọn gbọ iroyin kayeefi yi.
Nigba ti iya ọmọ yi arabinrin Aisha yoo tẹnu bọ alaye, o ni oun ati baba awọn ọmọ wọnyi ko si papọ mọ.
Bakan naa o ni oun ko mọ nkan to mu ki oun hu iwa yi si ọmọ bibi inu rẹ.
Ọpọ igba la maa n gbọ nipa bi awọn to yẹ ko tọju ọmde ṣe maa n fi iya jẹ awọn ọmọ to wa lab akoso wọn.
Pupọ iṣẹlẹ bayi lo mu ki awọn ijọba labẹ ajọ bi NAPTIP maa tọ pinpin itọju ọmde paapa awọn ti wọn fi n se ọmọọdọ.
Labẹ ofin Naijiria, ijiya orisi ni ofin la kalẹ fawọn to ba fiya jẹ tabi dẹyẹsi ọmọde.
















