Bamise Ayanwola Vs BRT driver: Ìwé ẹ̀sùn ìgbẹ́jọ́ Dẹ́rẹ́bà BRT tí Bamiṣe wọ̀ ti ṣàfìhàn ẹ̀sùn rẹ̀

Bamise

Adajọ agba Sherifat Shonaike ti ile ẹjọ giga ilu Eko ẹka ti gbagede Tafawa Balewa l'Eko ti ju awakọ BRT, Andrew Nice Ominikoro si ẹwọn bayii.

Ọgbẹni Nice ni afurasi ti iroyin sọ pe o lọwọ ninu ijinigbe ati iku arabinrin Bamise Ayanwola to di awati ni ọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu Keji.

Bamiṣe jẹ arabinrin ẹni ọdun mejilelogun to n gbe n ṣe iṣẹ ranṣọ-ranṣọ ni ipinlẹ Eko to si wọ ọkọ BRT lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye.

Wọn fi ẹsun kan ọgbẹni Nice pe o fipa ba Bamise lopọ ni ọjọ naa ti Bamise wọ ọkọ rẹ lati agbegbe Chevron, Lekki ni nkan bii ago meje alẹ.

Àkọlé fídíò, Samuel Ajirebi ọmọ ọdún mẹ́rin àtijọ́ rèé, ó bojú wo fíìmù rẹ̀ ní kékére, máàkì tó fún ara rẹ̀ rèé

Ninu iwe ẹsun ti ile ẹjọ to jokoo loni ka sita, wọn fi ẹsun kan Nice pe oun ati awọn mẹrin mii lo hu iwa ọdaran yii ti awọn yẹn si ti na papa bora.

Bakan naa ni wọn ni awọn mẹrin yii lo pa Bamise nigba ti wọn ju u sita latinu ọkọ to n sare lọ.

Iwe ẹsun naa tun sọ pe Dẹrẹba Nice yii kan naa ti fipa ba obinrin kan Odezelu Nneka Mary ni ọjọ Karun oṣu Kọkanla lọdun 2021 lagbegbe Lekki Conversation Centre.

Amọṣa, Nice ti ni oun ko jẹbi gbogbo ẹsun mẹrin ti wọn fi kan an.

Àkọlé fídíò, Ẹ má fún mi l'ówó bárà, mò ń bọ́ ẹnu púpọ̀, aya àtọmọ mẹ́ta - Oladapo Okalawon Shonde

Adari ikọ agbẹnusọ awọn agbofinro, Babatunde Martins beere lọwọ ile ẹjọ fun ipẹjọ ati pe ki wọn da Nice pada si atimọle.

Agbẹjọro fun Nice, IK Ezekwem naa wa ni ibi igbẹjọ naa bakan naa si ni agbẹjọro fun idle Bamise naa wa nibẹ.

Nibayii, ababọ igbẹjọ toni ni pe Adajọ agba Shonaike paṣẹ ki Nice wa ni ọgba ẹwọn yatọ fun ọjọ Kẹsan, ọjọ Kẹwa ati ọjọ Kọkanla fun itẹsiwaju igbẹjọ.