Bola Tinubu: Kanu Nwankwo, Taribo West sọ ìdí tí wọ́n fi ń kọ orin ìyìn Tinubu tó ń ṣe ọjọ́ ìbí 70

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Nigba ti awọn agbabọọlu ikọ Super Eagles tẹlẹri, Jay-Jay Okocha, Kanu Nwakwo, Victor Ikpeba ati Tribo West ṣe ibẹwo si eekan ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, wọn ko mọ pe yoo di ranto mọ awọn atawọn Naijiria lọwọ lori ayelujara.
Ọpọ eeyan lo ti n sọrọ lori ayelujare pe o kọja ibẹwo nikan ti awọn ti ko lodi si wọn naa si n fesi.
Ẹwẹ, ọkan awọn agbabọọlu tẹlẹri yii naa ti bọ sori ayelujara lati fesi ki ọrọ lee ye awọn eeyan daadaa.
'Ọjọ́ méjì àti wákàtí díẹ̀ péré la fún Ramon Adedoyin láti gbé ìwée 'a kò ní ẹjọ́ jẹ́' wá sílé ẹjọ́'
Awọn to lọ ṣe ibẹwo si ile Tinubu to wa ni agbegbe Bourdillon l'Eko ni awọn gbajugbaja agbabọọlu Austin Jay-Jay Okocha, Kanu Nwakwo, Victor Ikpeba ati Taribo West.
Wọn pawọpọ fun Tinubu ni ami ẹyẹ koda wọn tun gba bọọlu alayẹyẹ lati yẹ Asiwaju Tinubu si fun ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ ti yoo waye ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹta.
Ki ni Kanu sọ?
Ẹwẹ, Kanu Nwako to jẹ oludasilẹ ajọ ẹlẹyinju aanu naa ti ko dara le ijọba, Kanu Heart Foundation ti fi esi sita loju opo facebook rẹ lati fọwọ sọya nipa ibaṣepọ to wa laarin oun ati Tinubu.
Kanu ranti pe Bola Tinubu ran an lọwọ ni ọdun mejilelogun sẹyin.
"Ọpọ eeyan lo ti n sọrọ amọ ninu gbogbo ẹ, gbogbo wa la ni ẹtọ si erongba wa, a si gbudọ sọrọ".
"Agbabọọlu ni mi, iwuri si lo jẹ fun mi, akọni ni mo jẹ ti mo si mo ohun to dara yatọ si eyi ti ko dara".

Oríṣun àwòrán, Twitter
Kanu tun sọ pe ni ọdun mejilelogun sẹyin ti ajọ Kanu Heart Foundation n wa awọn eeyan fun iranwọ lati lee fọwọ tọ aye awọn eeyan, gomina mẹta pere lawọn ri ti Ahmed Tinubu si wa lara wọn.
"O fun ajọ naa ni owo; o ti wa lẹyin, nibayii o ti wa n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi aadọrin ọdun, a gbudọ wa nibẹ lati tii lẹyin, a ni bọọlu alayẹyẹ lati gba fi yẹ si".
Kanu ṣe iṣẹ abẹ ọkan nigba to pari iṣẹ gẹgẹ bii Balogun ikọ Super Eagles to si jawe olubori ni idije Olympic Atlanta 96.
Eyi lo mu ki o da ajọ silẹ ti yoo maa tọju awọn eeyan to to ni aisan ọkan.
Eekan agbabọọlu wa n funpe si gbogbo ọmọ Naijiria ki wọn lọ gba kaadi idibo wọn ṣaaju idibo ọdun 2023 ki wn lee dibo yan awọn to tọ sipo.
Amọ pẹlu gbogbo atotonu Kanu yii, kii ṣe bẹẹ lawọn eeyan ṣe rii, awọn iroyin n sọ pe ibẹwo wọn ni nkankan ṣe pẹlu ipinu Tinubu lati di aarẹ.
Ibẹrẹ dun yii ninu oṣu kini ni Tinubu sọ fun aarẹ Buhari pe oun yoo du ipo Aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Adura ti Taribo West gba fun Tinubu to fa ayelujara ya
Ninu fidi kan ati aworan to wa lori ayelujara, ṣe ni agbabọọlu Taribo West di Pasitọ to n rọjo adura le Tinubu lori.
Agbabọọlu fun ẹgb AC Milan tẹlẹ yii n tọrọ̀ lọwọ Ọlọrun ko gbe Naijiria dide pada latọwọ̀ Tinubu.
Ẹwẹ, adura yii ti di gbas gbos lori ayelujara tawọn eeyan si n yanju ọrọ rẹ lọwọlọwọ.














