Police searching for bear: Kí ló le fàá tí àwọn ọlọ́pàá fi ń wá ẹranko Bíárì?

Bíárì
Àkọlé àwòrán, Bíárì

Àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ California ń wá ẹranko igbó kan "Bear" tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ "Hank the Tank" tó ń yawọ ilé àwọn ènìyàn ní agbègbè Lake Tahoe láti ìgbà ooru tó kọjá.

Ẹranko náà ló wọn kílógírààmù mẹ́tàdínléníọ̀tàlénígba, èyí tó tóbi ju iye bí àwọn ẹranko náà ṣe máa ń tóbi mọ nítorí bí ó ṣe máa ń jẹun àjẹjù.

Àwọn aláṣẹ ìpínlẹ̀ California ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé àwọn yóò pa ẹranko náà tí wọ́n bá ri tán ṣùgbọ́n wọn yóò mú kí ikú rọ̀ ọ́ lọ́rùn nítorí ó ti gbádùn wíwà pẹ̀lú àwọn ènìyàn.

Àkọlé fídíò, Wòlíì ni ọmọ táà bá bí ni ago kan géérégé ni...Bàbá tó bí Ooni Adeyeye Ogunwusi sọ àṣírí àkọsẹ̀jayé rẹ̀

Ṣùgbọ́n àwọn tó ń ṣètọ́jú ẹranko igbó ti ń pè fún dídá ẹranko náà padà sínú ọgbà.

Tank ń yawọ ilé àwọn ènìyàn, ṣe àwọn ènìyàn léṣe

Àwọn aláṣẹ́ ní kò dín ní àádọ́jọ ìpè tí àwọn ti gbà lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn lórí bí Hank ṣe ti ń ya wọ ilé àwọn ènìyàn.

Ní báyìí ó ti tó àwọn ilé ogójì tí ẹranko yìí ti yawọ̀ tó sì ti ṣe ọṣẹ́ ńlá láti bí oṣù mẹ́fà sẹ́yìn.

Agbẹnusọ ẹ̀ka tó ń rí sí àwọn ẹja àti ẹranko igbó, Peter Tira ní Hank gba orúkọ rẹ̀ látara bó ṣe máa ń yọ ilé àwọn ènìyàn.

Tira ní Hank máa ń lo bí ó ṣe tóbi to àti kìmí rẹ̀ ní láti fi já ilẹ̀kùn, fèrèsé àti géètì láti fi ya wọ ilé onílé.

Bákan náà ni wọ́n rọ àwọn ará ìlú Lake Tahoe láti wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí kí wọ́n sì máa ṣe oúnjẹ wọn lọ́jọ̀ dáadáa nítorí pé Tank kìí jẹ́ kòkòrò àti èso tí àwọn bíárì tí ẹgbẹ́ rẹ̀ máa ń jẹ́.

Tira fi kun pé àwọn oúnjẹ àjẹkù dùn ùn rí ní Tahoe jú kí Tank ṣẹ̀ṣẹ̀ láti máa wá àwọn kòkòrò tí yóò jẹ kiri.

Tank tóbi ju bí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ lọ

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ẹkùn gúúsù Lake Tahoe ní kò ṣòro dá mọ̀ nítorí bó ṣe tóbi tó àtí pé ó dúdú biribiri.

Wọ́n ní gbogbo ọgbọ́n tí àwọn fi máa ń pé ẹranko ẹgbẹ́ rẹ̀ bíi fífọn fèrè àti àwọn nǹkan mìíràn tí àwọn ẹranko kìí fẹ́ ní àwọn ti gbìyànjú ṣùgbọ́n kò ṣiṣẹ́ láti pe Tank padà kúrò láàárín ìgboro.

Ẹgbẹ́ "The Bear League", tí wọ́n wà fún títọ́jú àwọn ẹranko igbó Hank tóbi tó bó ṣe wà nítorí tó fẹ́ràn láti máa jẹ àwọn oúnjẹ tí ènìyan ń jẹ.

Ẹgbẹ́ náà pè fún wíwá Tank, kí wọ́n sì da padà sí inú igbó tàbí ibi tí wọn yóò ti máa ṣe ìtọjù rẹ̀ láàyè dípò tí wọn yóò fi pá á.

Àkọlé fídíò, Oluwo‘s Wedding: Àwọn èèyàn ìlú Iwo ní àwọn ń fojú sọ́nà láti tẹ́wọ́gba aya tuntun

Àwọn ará ìlú ń kọminú lórí ọsẹ́ tí Hank ti ń ṣe

Tim Johnson tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní láti bí ogójì ọdún tí òun ti ń gbé ìpínlẹ̀ náà, òun kìí ti ilẹ̀kùn òun rárá ṣùgbọ́n láti ìgbà tí Hank ti ń ṣọṣẹ́ ní òun ti ń tilẹ̀kùn.

Bákan náà ló ní bí àwọn kò bá fún wọn lóúnjẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni kò sí ọ̀rọ̀ wà nílẹ̀.