Police-Corps Member Fracas: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Oyo àti NYSC sọ̀rọ̀ lórí aáwọ̀ tó wáyé láàrin ọlọ́pàá àti àgùnbánirọ̀

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Ọjọ nla, ọjọ manigbagbe fun igba pipẹ ni Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlogun osu Kẹta ọdun 2022 jẹ fawọn olugbe adugbo New Garage nilu Ibadan.
Eyi ko si sẹyin isẹlẹ nla to waye nibẹ nigba ti ariwo ta pe awọn osisẹ ọlọpaa kan ti fi ibọn da ẹmi agunbanirọ kan legbodo?
Irọ ni, awada ni, ero ti pejọ, ti ohun gbogbo si di rudurudu, eyi to se idiwọ fun lilọ ati bibọ awọn eeyan ati ọkọ pẹlu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Báwo ní àláfíà ara Iyabo Oko, ipò wo ní ìlera rẹ̀ wà?
- Àìsàn tó ń ṣe ọ ní ohun ṣe pẹlú oorun rẹ - Onímọ
- Ohun tí mo fẹ́ rèé tí ìkọlù sí Ukraine yóò bá dópin - Putin
- ₦7trn àti díẹ̀ ló gun gbèsè Nàíjíríà láàrin ọdún 2020 sí 2021 - DMO
- Olùdásílẹ̀ ìjọ tí ọlọ́pàá FBI ti ń wá fọ́jọ́ pípẹ̀, kó sí gbaga EFCC lórí ẹ̀sùn wáyá-wayà
- Nàíjíríà ń sún ọjọ́ ìjà síwájú ni, mo gbà pé ìpàdé àpérò gbọdọ̀ wà - Ọba Tejuosho
- "Ọlọ́pàá ló pe mí láti wá gbé òkú Timothy Adegoke lẹ́sẹ̀ títì"
- Wọ́n tan bàbá 85 kúrò nílé, fọ́ igi mọ lórí, ju òkú rẹ̀ sétí odò l‘Ogun
Bakan naa ni ẹgbẹlẹgbẹ awọn agunbanirọ to wọ asọ ẹgbẹjọda wọn, ti pe biba sibi isẹlẹ naa, ti wọn si dara pọ mọ awọn araalu kan lati se iwọde lori isẹlẹ yii.
Bawo ni isẹlẹ naa se waye:
Iroyin to kọkọ jade si igboro lati ẹnu awọn eeyan kan ti isẹlẹ naa soju wọn sori ayelujara, lo ni ipade ọlọsọọsẹ ti awọn agunbanirọ to n sinru ilu maa n se ni gbogbo Ọjọbọ ni ọkunrin naa lọ fun.
Wọn ni agunbanirọ yii lo n wa mọto Camry funfun kan, bo si se n bọ lati ibi ipade naa lo pade awọn ikọ ọlọpaa to n se ayẹwo ọkọ loju popo.
Awọn ọlọpaa naa ni wọn lo da ọkọ agunbanirọ naa duro amọ ti onitọun ko da wọn lohun rara.
A gbọ pe idi ree tawọn ọlọpaa fi gbe ọkọ sare tẹle lẹyin, ti wọn si mu ọkọ agunbanirọ naa mọlẹ ni ibudo kan.
Wọn ni itakurọsọ bẹrẹ laarin igun mejeeji, ti inu si bi ọlọpaa kan kọja aala, to si yin ibọn mọ agunbanirọ naa.
Awọn agunbanirọ lo kede sita pe aya ati ori ni ọlọpaa naa ti gbe ibọn fun akẹẹgbẹ awọn, eyi to gbẹmi rẹ.
Ọrọ di rogbodiyan ni agbegbe naa, ti ogunlọgọ awọn agunbanirọ to wa nibi ipade ti akẹẹgbẹ wọn naa ti n bọ, si ya bo ibi ti isẹlẹ naa ti waye.
Koda, mọto ti agunbanirọ naa gbe lo bajẹ, ti awọn gilaasi kan lara rẹ si fọ.
Amọ wọn papa pẹtu si aawọ naa, ti awọn ọga ọlọpa si wa si agbegbe ọhun lati bawọn agunbanirọ ọhun sọrọ, pe ki wọn fi ọwọ wọnu.

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Ko si ọlọpaa kankan to yin ibọn rara mọ agunbanirọ nibi isẹlẹ naa:
Osisẹ alarena fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Adewale Osifeso, ninu atẹjade kan to fisita lọjọ Ẹti kede pe ọlọpaa kankan ko yin ẹyọhoro ọta ibọn nibi isẹlẹ naa.
Atẹjade naa ni se ni awakọ Camry naa, tii se agunbanirọ wa ọkọ rẹ lọna aitọ, to si n sare asapajude.
Asiko naa si lo fi mọto gba ọkan lara awọn ọlọpaa to n sisẹ oojọ rẹ, Bright Agbadahun lasiko ti wọn da duro, ti ko si duro.
O ni iyanju lati sa mọ awọn ọlọpaa naa lọwọ, lo mu ki agunbanirọ ọhun kuro loju ọna tiẹ lati dojukọ awọn ọkọ miran to n bọ.
Asiko naa si lo kọ lu kẹkẹ Maruwa kan, eyi si lo mu ko seese fawọn ọlọpaa lati ri mu.
Agunbanirọ to fi mọto rẹ kọlu ọlọpaa, lo tun kigbe sita pe ọlọpaa yinbọn lu oun:
Osifeso salaye siwaju pe agunbaniro yii lo sadede mu ariwo bọnu pe awọn ọlọpaa ti yinbọn mọ oun.
Idi si ree ti awọn akẹẹgbẹ rẹ to n ti ibi ipade wọn ọlọsọọsẹ bọ se ya bo ibi isẹlẹ naa, ti wọn ko si gbọ alaye kankan mọ.
O ni bi awọn agunbanirọ yoku naa se ri ọlọpaa ti mọto kọlu nilẹ, ni wọn gun ni ọbẹ ni ẹrẹkẹ, ko to di pe wọn doola ẹmi rẹ lọwọ wọn, ti wọn si gbe lọ fun itọju.
"Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo wa n kede pe irọ to jinna sootọ ni pe ọlọpaa yinbọn mọ agunbanirọ tabi ọkọ rẹ saaju ati lẹyin isẹlẹ naa.
Ọlọpaa ko yinbọn mọ agunbanirọ kankan - NYSC
Wayi o, ileesẹ to wa fawọn agunbanirọ to n sinru ilu, NYSC,ẹka ti ipinlẹ Oyo ti fi atẹjade kan sita pe lori isẹlẹ naa.
Atẹjade ọhun ti alukoro NYSC nipinlẹ Oyo, Christy Olatoye fisita naa ni iroyin to n lọ lori ayelujara pe ọlọpaa yinbọn mọ agunbanirọ jinna sootọ.
O ni ko si agunbanirọ ti wọn yinbọn mọ ni ori tabi aya, ti ẹmi kankan ko si bọ si isẹlẹ naa.
Olatoye kede pe ọpẹlọpẹ awọn alasẹ ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo to dede da si aawọ naa, lo jẹ ki alaafia pada jọba.
O wa mu da awọn agunbanirọ to wa nipinlẹ Oyo loju pe Kọmisana ọlọpaa ti gbe iwadii dide lati tanna wadii isẹlẹ naa.





















