Roheem Bamimore: Ará àdúgbò ní àwọn afurasí tó pa ọmọ náà ti máa ń jalè tẹ́lẹ̀, àwọn sì ti lé wọn kúrò

Àkọlé fídíò, Roheem Bamimore: Ará àdúgbò ní àwọn afurasí tó pa ọmọ náà ti máa ń jalè tẹ́lẹ̀

Laipẹ yii ni ariwo ta nipa iku ọmọ ọdun mẹjọ kan ti wọn ba oku rẹ nile akọpati kan nilu Saki nipinlẹ Oyo.

Orukọ ọmọ naa ni Roheem Bamimọrẹ.

Iroyin naa si fidi rẹ mulẹ pe awọn ọdọ meji kan, ti wọn ko ti to ogun ọdun, ni wọn tan ọmọde naa lati ji gbe gba owo lọwọ baba rẹ.

Amọ lẹyin o rẹyin, wọn fun ọmọ ọhun ni majele jẹ, to si ku nile akọpati ti wọn so mọlẹ si lẹyin ọjọ kẹta ti wọn ji gbe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọna lati mọ ẹkunrẹrẹ iroyin si nipa isẹlẹ ọhun lo gbe BBC Yoruba de ilu Saki lati tọpinpin isẹlẹ naa.

Bakan naa la ba baba ọmọde to salaisi naa sọrọ, Abdulazeez Bamimọre Olawale, ẹni to salaye bi ọmọ naa se di awati ati bi wọn se ri oku rẹ.

Omi Pure Water ni wọn ni ki ọmọ mi mu wa ninu ile, ti wọn fi tan gbe lọ:

Baba ọmọ naa, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni awọn ọdọ adugbo meji lo pade Roheem lẹnu ọna abawọle awọn, ti wọn si ni ko lọ wo boya ẹgbọn rẹ wa nile.

Bakan naa lo ni wọn rọ pe ko mu omi inu ọra wa fun awọn to ba n pada bọ wa jisẹ fun awọn.

Bamimore ni bi ọmọ oun se pada de ọdọ wọn ni wọn tan lọ sile akọpati kan nibi ti wọn so mọlẹ si.

O ni ibeji Roheem ti wọn jọ n bọ lati ile ẹkọ, lo da awọn ọdọ meji to ran ekeji rẹ nisẹ naa mọ, to si sọ fun awọn.

Amọ gbogbo iyanju awọn lati jẹ ki awọn ọdọ naa jẹwọ lo ja si pabo, ti wọn si taku pe awọn ko mọ ibi ti Roheem wa

Awọn afurasi jẹwọ pe oogun eku ati ganmọle ni awọn fun ọmọ mi mu:

Bamimore ni awọn fi isẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti, ti wọn si ko awọn afurasi mejeeji yii amọ wọn ko sọ ibi ti wọn so Roheem mọ.

“Oorun kan to n jade nile alapa to wa lẹyin ile awọn ọmọ naa kọja sisọ, a si n beere pe ki lo n run, amọ baba awọn ọmọ naa ni oku adiẹ ni.

Aago meji oru la lọ yọju wo ile naa, ta si ri oku ọmọ mi nibẹ. Asiko yii ni awọn afurasi mejeeji naa to wa jẹwọ pe awọn lo fun ni oogun eku ati ganmọle jẹ.

Awọn afurasi naa n jale ladugbo tẹlẹ, a si ti le wọn kuro amọ a ko mọ pe wọn ti pada de:

Aladugbo kan to ba BBC Yoruba sọrọ ni odu ni awọn afurasi mejeeji naa, awọn si mọ wọn bii isana ẹlẹẹta.

O ni ọmọ lile ni wọn, ti wọn si ti maa n jale tẹlẹ amọ awọn ko mọ pe wọn le se ohun to to bayii.

“Awọn ọmọ naa ti ji ẹya ara ọkọ mọto onimọto ri, ti wọn si ta danu.

Asiri wọn tu, ta si le wn kuro ni adugbo amọ a ko mọ pe wọn ti pada de.

Ipanle ni wọn, ta si maa n fi ẹjọ wọn sun baba wọn lai mọ pe wn lee se aburu to to bayii.”

Nibayii, awọn afurasi mejeeji naa ati baba wọn ti wa ni ahamọ ọlọpaa lori isẹlẹ naa.