Money Ritual: Ẹnìkan tó ṣe òògùn owó ní èèyàn kò gbọdọ̀ bèèrè ìrúfẹ́ ẹ̀jẹ́ tí wọn bá gbé lé àwọn lọ́wọ́ torí ọ̀rẹ́ òun tó bèèrè irú rẹ̀ kú ni

Àkọlé fídíò, Money Ritual: Ǹ kò le bèèrè

Yoruba ni ẹda ti ko ba mọ ibi ti ẹgbẹ rẹ ti la, yoo sare asaku nitori isalẹ ọrọ ni ẹgbin.

Ni akoko yii, isẹlẹ fifi eeyan se oogun owo lo gbode kan, ti ọpọ ọdọ si n kanju wa owo nipa gbigba ọna ẹburu lati ni owo.

Ọpọ ọmọbinrin ni wọn ti ri oku wọn, ti ẹya ara wọn ko pe mọ, eyi ti wọn fura si pe wọn fi wọn se etutu ọla ni.

Bakan naa, ni aimọye ọdọkunrin ti ya were soju popo nitori wọn ni wọn se oogun owo.

Awọn isẹlẹ akanilaya yii lo mu ki BBC se iwadii nipa oogun owo sise, ta si ba eeyan kan to ti gbinyanju tẹlẹ lati se oogun owo sọrọ.

Bakan naa la ba iya ọmọbinrin kan ti wọn fi furasi pe wọn fi se oogun owo sọrọ ati Babalawo kan to sọrọ nipa atubọtanfun onisegun to ba se oogun owo fun eeyan.

Orisirisi oogun owo to wa:

Gẹgẹ bi ẹnikan ta fi orukọ bo lasiri, to ti se etutu ọla sọyin ti salaye fun BBC, orisi oogun owo mẹta to mọ ni iwọnyi:

  • Fifi orukọ ẹni ti wọn fẹ lo ransẹ si Babalawo
  • Jijẹ asejẹ pẹlu Gbẹrẹ
  • Lilo eeyan lati fi se etutu.

Babaláwo fún mi ní igbá tó kún fún ẹ̀jẹ̀, ọsẹ dúdú àti Ajá ààyè fún ètùtù ọlà:

Bakan naa ni ẹni yii sọ fun BBC pe nigba ti oun gbiyanju lati se etutu ọla, Babaláwo fún oun ní igbá tó kún fún ẹ̀jẹ̀, ọsẹ dúdú àti Ajá to wa ni ààyè fún ètùtù ọlà.

Amọ o ni oun ko le sọ boya ẹjẹ eeyan lo wa ninu igba naa tabi ti ẹranko.

O ni ẹru n ba oun lati beere pe iru ẹjẹ wo lo wa ninu igba nitori ọrẹ oun to beere iru rẹ saaju, ya were ni.

“Babalawo ni ki n maa fi ọsẹ dudu wẹ ni alaalẹ, ti wọn yoo si pa awọn eeyan ti wọn ba lo, lẹyin ti wọn ba ti lo asiki ara wọn tan.”

O ni eyi ni ko ni jẹ ki onitọun lọ fi isẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti.

Ilegbe ni ọmọ mi wa lọ si ọgba fasiti, ki wọn to dumbu rẹ - Elizabeth Gege

Elizabeth Gege tii se mama ọmọbinrin kan, Elozino ti wọn ri oku rẹ lọdun 2018 ba BBC sọrọ lori bi wọn se lo ọmọ rẹ gun oogun owo.

O ni ilegbe ni ọmọbinrin naa wa lọ si ọgba fasiti ipinlẹ Delta, ki wọn to dumbu rẹ.

O ni awọn ẹya ara rẹ kan ti di awati, awọn si fura si pe awọn agbenisowo ọmọ Yahoo lo lo ọmọ oun fun etutu ọla.

Elizabeth wa n kerora pe isẹlẹ naa ti mu ki aye su oun bayii.

Babalawo to ba se etutu ọla fun ọmọ Yahoo ko ri aye wa – Oluwo

Nigba to n ba BBC sọrọ, Oluwo Olakunle Olawole, tii se babalawo ni adahunse to ba se etutu ọla fun ọmọ Yahoo ko ri aye wa rara.

Bakan naa lo fikun pe yoo dara ki iru ẹni bẹẹ lọ yii iwa pada, ko le ni ọjọ ọla.

“Kii se pe awọn ọmọ Yahoo kii wa si ile mi, wọn maa n wa lorisirisi amọ mo maa n yi wn lọkan pada ni.

Mo maa n se eyi nipa sisọ fun wọn pe wọn si le lowo lai lu jibiti tabi lo ẹya ara eeyan.

Mo si maa n gba wọn ni imọran lati yi wọn lọkan pada, ki wọn maa ba lọ si ọdọ ẹlomiran ti yoo se oogun owo fun wọn.

Bakan naa ni BBC ba alukoro tẹlẹ́ fun ileesẹ ọlọpaa ilẹ wa, Frank Uba sọrọ, to si salaye igbesẹ ti wọn n gbe lati fopin si iwa fifi eniyan se owo.