Jaruma Vs Ned Nwoko: Ọ̀rọ̀ Kayamata yìí tún dá Hauwa Saidu to ń amárajípépé fún ìbálòpọ̀ padà sẹ́wọ̀n

Jaruma, Regina, Ned

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ile ẹjọ giga kan ni ilu Zuba ni Abuja ti da idajọ gbigba beeli nu eyi ti wọn da tẹlẹ fun gbajumọ oniṣowo oogun ifẹ fun ialopọ, Hauwa Saidu ti gbogbo eniyan mọ si Jaruma.

Adajọ agba ile ẹjọ naa, Ismail Abdullahi Jibrin ninu idajọ rẹ sọ pe ki awọn ọlọpaa tun pada lọfofin mu Jaruma ti wọn ti da silẹ pada ki wọn si fi si ẹwọn to wa ni Suleja titi di ọjọ Kẹtadinlogun oṣu Kẹta ọdun 2022 ti wọn sun igbẹjọ si.

Adajọ naa fi ibinu han nipa bi Jaruma ati agbẹjọro rẹ ṣe kọ lati yọju si ile ẹjọ ti wọn ko si ran aṣoju kankan leyi to jẹ wipe adajọ ti kọkọ da ẹjọ naa duro pẹlu ero pe wọn n bọ, agbẹjọro kan tun bẹ ile ẹjọ naa ki wọn tun fun wọn ni akoko diẹ, adajọ tun duro fun o le ni wakati meji ko to wa di pe o dajọ, koda wọn o tun ko firi wọn lẹyin igba naa.

Àkọlé fídíò, Bukola Odufuwa: Mo ń ta oúnjẹ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́, gbálẹ̀, fọ aṣọ, pọnmi láì tọrọ agbe jẹun

Adajọ binu pe iwa ifiniṣe yẹyẹ ni eyi jẹ fun ile ẹjọ ati ẹka idajọ nitori naa ile ẹjọ gbudọ gbe igbesẹ.

Jaruma n jẹjọ lori ẹsun ibanilorukọ jẹ ati lilo oogun oloro.

Ki lo kan ọrọ tita oogun ifẹ ninu ọrọ yii?

Awọn ọlọpaa ti ṣaaju gbe Jaruma lọ si ile ẹjọ giga ilu Abuja nibi ti wọn ti dajọ gbigbe e lọ si ọgba ẹwọn Suleja.

Jaruma ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, agbẹjọro rẹ si beere fun gbigba beeli.

Ile ẹjọ fọwọ si gbigba beeli rẹ ni ọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Kini ọdun 2022 lẹyin to ti lo ọjọ mẹ́rin lẹwọn.

Lasiko yii, Jaruma tilẹ fi fidio sita lati fi oko ọrọ ranṣẹ si awọn ọta rẹ to ni wọn ti oun lọ sẹwọn to si tun pada lọ pin ounjẹ atawọn nkan elo fawọn iyalọmọ to ni oun pade lẹwọn ti iya n jẹ.

Jaruma jade lẹwọn

Oríṣun àwòrán, Jaruma Empire

Adajọ to wa lori ọrọ sọ ọ nigba yẹn pe lootọ ẹjọ yii ṣee gba beeli fun amọo kilọ fun awọn ti ọrọ kan pe ki wọn ṣọra ki wọn ma tẹ oju ofin mọlẹ tori ẹjọ ọhun kii ṣe ẹjọ lasan.

Ṣe ni oniṣowo Kayamata ọhun atawọn ọrẹ rẹ n ho yee fun ayọ nigba ti idajọ naa gbe wọn ti wọn si n ṣa a gẹgẹ bii "Aarẹ obinrin akọkọ ni Naijiria" t'oun naa si n fi bi inu rẹ ṣe dun to da wọn lohun pe oun yoo du ipo Aarẹ lọdun 2023.

Ki lo da wahala silẹ laarin Jaruma, baba agba olowo Ned Nwoko ati ọdọbinrin to fẹ ni iyawo?

Fa ki n faa laarin wọn bẹrẹ laarin Jaruma ati idile Nwoko nigba to gbe ọrọ kan jade loju opo Instagram rẹ pe oun san miliọnu mẹwa naira fun iyawo Ned Nwoko, Regina Daniels lati ba a polowo ọja to n ta - Kayamata, amọ ti ko ṣe iṣẹ naa.

Ẹwẹ ninu oṣu Kọkanla ni Regina naa jade sita lati sọ pe oun ko lo Kayamata ri laye oun atipe oun ti fopin si gbogbo ibaṣepọ rẹ pẹlu Jaruma.

Ṣe ni Jaruma naa ba fesi si ọrọ yii pe Regina nioun o lo Kayamata to si tun tọka si awọn iyawo Ned to ti fi igbeyawo naa silẹ.

O da gbogboẹ ẹbi oun to ṣẹlẹ laarin wọn le ai mu adehun pipolowo ọja rẹ ṣẹ.

Bakan naa ni Jaruma tun sọ ninu fidio kan pe ko dara bi olowo ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin yii ti oun bu iyi fun ṣe le bọ sori ayelujara lati maa sọ aidaa nipa iyawo rẹ to ti fẹ fun ọdun pipẹ.

Lasiko yii ni Ned Nwoko fọ ọwọ rẹ kuro ninu ẹjọ naa ti o si fi ikilọ fa Jaruma leti.

Ọrọ ọhun gba ibomii yọ nigba ti olowo naa, Ned kọ iwe ipẹjọ latọwọ agbẹjọro rẹ ti wọn si fi ofin lọ mu Jaruma lati gbe e lọ ile ẹjọ.

Taa gan ni Jaruma?

Hauwa Saidu Mohammed ti ọpọ eeyan mọ si Jaruma jẹ oniṣowo ati onimọ nipa ibalopọ laarin ọkunrin ati obinrin.

Wọn bi i ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹwa ọdun 1993.

O wa lati ipinlẹ Gombe ti ọpọ eeyan si ri i gẹgẹ bi gbajumọ to ti laluyọ to si jẹ onimọ nipa ibalopọ to n gba owo gọbọi ju ni Naijiria.

Orilẹede Naijiria ati Turkey ni Jaruma ti kawe.

Lọdun 2010 lo bẹrẹ si ni ṣe owo oriṣiriṣi amọ ọdun 2016 gan lo ja si gbangba lẹyin to ṣe fidio kan jade fun awọn ọmọ Naijiria ninu eyi to ṣalaye iwulo egboogi kan Azanza Garckeana (Silky Kola).

O bẹrẹ si ni ta awọn nkan to n mu ara jipepe fun ibalopọ, "Kayamata" to ṣalaye pe o n ran awọn obinrin lọwọ lati bori igbeyawodidaru tori aile koju osuwọn iru ibalopọ ti ololufẹ wọn n fẹ.

Bo tilẹ jẹ pe awọn kan ti pe e nija peo n fi oogun ibilẹ kun nkan to n ṣe ki awọn onibara rẹ le maa fa ori ọkunrin ti wọn ba yan laayo sabẹ lati maa ṣe gbogbo ohun ti wọn ba fẹ ni kete to ba ti ba wọn lopọ.