Mide Funmi-Martins àtí Olamide àbúrò rẹ̀ ti ayé ń bú u lé lórí ti wà papọ̀

Mide Martins ataburo rẹ

Oríṣun àwòrán, Mide Funmi MArtins

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ọmọ ìyá kìí yà, ọmọ baba ní ń báni dalẹ́.

Nínú oṣù kejì, ọdún 2021 ní àwọn ènìyàn lórí ẹ̀rọ ayélujára Instagram yọ sùtì ètè sí gbajúgbajà òṣèré Mide Martins nítorí tí ìròyìn kan pé ó pa àbúrò rẹ̀ tí ìyá rẹ̀, Funmi Martins bí fún Shina Peters kó tó kú tì.

Àwọn ènìyàn lásìkò náà bú Mide Martins pé pẹ̀lú bí Ọlọ́run ṣe kẹ́ ẹ tó kò lè mú àbúrò rẹ̀, Damilare sọ́dọ̀ rẹ̀.

Mide ati Olamide

Oríṣun àwòrán, Mide Funmi Martins

Ẹ ó rántí pé Damilare fi síta lọ́dún náà lọ́hùn ún pé òun kò ṣetán láti gbé ọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n òun tí kò bèrè òun fún ọdún mọ́kàndínlógún.

Àkọlé fídíò, Bukola Odufuwa: Mo ń ta oúnjẹ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́, gbálẹ̀, fọ aṣọ, pọnmi láì tọrọ agbe jẹun

Èyí mú kí Mide Martins náà jáde síta lásìkò náà wí pé òun kò mọ̀-ọ́n-mọ̀ pa Damilare ti nítorí pé ẹ̀jẹ̀ òun ni.

Mide Martins ní Damilare ni kò fẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ òun.

Ẹ̀wẹ̀, ọdún kan lẹ́yìn rẹ̀, Mide Martins fi àwòrán kan sórí ẹ̀rọ Instagram lónìí léyìí tó ń ṣàfihàn pé Damilare ti wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga ti Mide Martins ẹgbọn rẹ si wa nibi ayẹyẹ naa.

Ko si aridaju boya Mide Martins kọ pé mọ̀lẹ́bí ṣaájú ohunkóhun tí òun àti Damilare sì dì mọ́ ara wọn.

Kòdá èyí tí ń mú kí àwọn ènìyàn máa gbóríyìn fún un fún ipa tó kó nínú ìgbésí ayé ọmọ náà.

Esi si Mide Martins ataburo rẹ

Oríṣun àwòrán, Mide Martins

Esi si Mide Martins ataburo rẹ

Oríṣun àwòrán, Mide Funmi-Martins

Esi si Mide Martins ataburo rẹ

Oríṣun àwòrán, Mide Funmi-Martins