Oja Odan ritual: Ìwádìí tó kúná ni a fẹ́ láti mọ̀ àwọn Onígbọ̀wọ́ olóògùn owó ní Oja Odan- Oba Oladiipo Oyebamiji

Oja Odan

Ọ̀rọ̀ pipa awọn eeyan ati ki wọn maa kun wọn si wẹlẹwẹlẹ nitori ọna lati di olowo ojiji ni Naijiria ti n bi Ige ati Adubi ni asiko yii.

Ni agbegbe Oja Odan ni ipinle Ogun ni guusu Iwo Oorun Naijiria ni ọwọ ti tẹ awọn meji pe wọn ṣe iku ọdọ kan lati fi ṣe etutu ọla.

Lẹyin naa ni awọn ọdọ Oja Odan fariga ti wọn si kọlu agọ ọlọpaa ti wọn ko awon afurasi yii si ti wọn si fi agidi ko wọn sita ti wọn si pada dana sun wọn nibẹ ni ojutaye.Ará àdúgbò dáná sun afurasí méji tí wọ́n bá orí èèyàn lọ́wọ́ wọn ní àgọ́ ọlọ́pàá ní ọjà ọ̀dàn

Oja Odan
Àkọlé àwòrán, Bayii ni wọn se dana sun afurasi meji ni Oja Odan

Nibo ni ọ̀rọ̀ dé duro bayii ni Oja Odan?

Nigba ti BBC Yoruba kan sibẹ lati mọ ibi ti ọrọ de duro lori iṣẹlẹ yii ni a ri awọn kan ba sọrọ.

Àkọlé fídíò, Abeokuta murder

Oba Oladiipo Oyebamiji to jẹ Kabesi to n jọba ni Oja Odan sọrọ ilẹ kun lori ohun to ṣẹlẹ naa.

Kabiesi koro oju si idajo owo eni pefun iwadi to peye.

Àkọlé fídíò, Segun iberu

Awon Odo ilu oja odan ni opin ose yii ya wo ago olopaa to wa ni Oja-Odan nijoba ibile ariwa Yewa nipinle Ogun ti won si gbe awon meji ti won fura si pe won seku pa odo kan ni ilu naa ti won si dana sun won ni waju ago olopa ilu na.

Àkọlé fídíò, OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n...

Kini awọn elomii tun sọ lori iṣẹlẹ naa?

Eni kan to jẹ Osoju mi koro se lalaye pe àwọn odo ilu náà borí àwọn ọlọ́pàá, tí wọ́n sì kó àwọn afurasí náà kúrò ní àtìmọ́lé, tí wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú àgọ́ olppa náà.

Oja Odan

Oba ilu na Oba Oladipo Oyebamiji oloja ti ilu ojo odan ba bbc yoruba soro to si koro oju si iwa odaju awon odo ilu naa.

Ope fun iwadii to kuna lati fi oju awon onigbowo awon onise labi na han ati lati dekun iseku pani ni agbe naa.

Oja Odan

Kini awọn ọlọpaa sọ fun BBC nipa bi awọn ọdọ ṣe dana sun afurasi?

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ naa, Abimbola Oyeyemi, fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan naa yabo ibudo naa, ti wọn ba awọn oṣiṣẹ ọlọpaa ti wọn wa ni ibi iṣẹ, ti wọn si ji awọn afurasi naa gbe, ti wọn lu wọn pa, ti wọn si dana sun oku wọn.

Àkọlé fídíò, Olaiya Igwe: Àwọn ọmọde tí mò ń bá ṣe ‘skit’ ló dáwó jọ fún mi nígbà tí àìsàn inú dé sí mi

Oyeyemi ṣe apejuwe igbese naa gẹgẹ bi "idajọ owo are eni" o sọ pe ko ni aaye ninu ofin Naijiria..