Àgbẹ̀ kan rèé tó ń ka owó nídìí ọ̀sìn aáyán.Wo ọ̀nà tó gbée gbà

Aworan aayan lori igba

Oríṣun àwòrán, Thinkstock

''Awọn eeyan ro pẹ mo ya were ni nigba ti mo bẹrẹ si ni sin aayan amọ nisinyi mo ti n ri owo nibẹ.''

Ọrọ ree lati nu arakunrin Lusius Kawogo nigba to n ba ileeṣẹ iroyin wa BBC sọrọ.

Agbẹ yi to wa lati orileede Tanzania ti ṣalaye fun BBC boun ṣe lu aluyọ to si ti bẹrẹ si ni pawo wọle nipasẹ ọsin aayan.

Ohun nikan kọ, o jọ pe ọsin aayan yi ti n gbalẹ kaakiri lorileede Tanzania

Ilumọọka akọrin to n fi aayan ṣe ara rindin

Loṣu to kọja iroyin nipa ilumọọka akọrin ati arinrinoge nii Saumu Hamisi gbode lori bo ti ṣe nifẹ si aayan jijẹ.

Saumu ti inagijẹ rẹ n jẹ Ummy Doll sọ fun BBC Swahili pe aayan dabi igba pe eeyan n jẹ ẹja tabi ẹran ni.

Aworan Ummy Doll to nfe si aayan

O fi kun pe oun a maa fi ororo agbọn yan aayan naa ki oun to jẹ tabi ki oun din tabi koun si ṣe bi suya.

Arakunrin Kawogo taa fi bẹr apilẹkọ yi ṣalaye fun wa pe awọn onibara lati ibomiran yatọ si Tanzania ti nkan si oun tori pe wọn fẹ ra aayan.

Amọ o ni iru iṣẹ ọgbin yi ko ti di atẹwọgba lọdọ awọn eeyan ilẹ Tanzania.

Aworan aayan ati arakunrin to n sin aayan

''O wu mi ki ọpọ eeyan darapọ mọ iṣẹ ọgbin aayan yi ki a baa le ribi pese rẹ lọpọ yanturu fawọn to n beere lọwọ wa''

Àkọlé fídíò, OLota

Ki lawọn onimọ sọ nipa eronja to wa lara aayan jijẹ

Nile iwosan Dar es Salam taa mọ si Muhimbili National Hospital,ọnimọ kan nibẹ sọ pe ọpọ eronja to n ṣe ara loore lo wa lara aayan ti wọn ba sin daada.

Onimọ nipa ounjẹ Scolastica Mlinga s pe ''Ayan kun fun eronja to n se ara loore bi ọra,vitamin B12 ati zinc to maa n jẹ ki ara le koju awọn aisan''

Àkọlé fídíò, Snake Market: Àwọn òńtàjà ẹran ejò ní ẹran ejò dùn ju ẹran adìẹ lọ

Lọpọ ibi, awọn eeyan a maa foju wo aayan pe nkan gbin ni wọn nitori ibi ti wn maa n gbe bi inu baluwe, ile idana tabi ninu ṣalanga.

Ni ilu Havana,awọn araalu a maa tọju aayan alawọ ewe bi nkan ọsin.Koda ninu awọn aalọ ti wọn maa n pa fọmọde, aayan yi maa n wa ninu itan.

Àkọlé fídíò, Ìdíje ata tútù: Jẹ ata 50, ko gba góólù gírámù mẹ́ta

Awọn nkan ti wọn le lo aayan fun

Nilẹ oni to mọ awọn ileewosan kan ni China a maa fi ipara ti wọn peelo rẹ lati ara aayan ṣe itọju awọn ti ina ba jo tabi ti nkan gbona da si lara.

Sirọọbu ti wọn ṣe lara aayan naa maa n wulo fawọn alaisan to n koju gastroenteritis.

Arakunrin kan Wang Fuming nigba to ri pe awọn eeyan n beere aayan gan, niṣe lo da oko aayan silẹ ni agbegbe ibi to n gbe ni China.

Abọ ti wọn ko aayan sinu rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Yatọ si pe wọn n jẹ aayn, wọn a tun maa lo aayan lawọn ile iwosan China fun itọju alaisan

Miliọnu mejilelogun aayan lo n sin lab aja ilẹ ile rẹ to si ni lati ọdun 2010 iye owo tawọn n ta aayan ti lekun ni ilọpo mẹwaa.

Awọn eeyan a maa jẹ aayan ni China. Bi wọn ba sun wn pẹlu ororo, a maa mu ki ẹyin wọn gbẹ daadaa.

Àkọlé fídíò, Adunni Ade: Lóòtọ́ọ́ ní àwọn adarí eré máa ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré-bìnrin

Wọn a tu maa n fi ata yẹri si aayan yi ko baa le ta lẹnu daada.

Pẹlu bi ounjẹ ti ṣe jẹ ipenija fawọn eeyan lagbaye o ṣeeṣe ki awọn eeyan ya sidi aayan jijẹ gẹgẹ bi orisi ounjẹ aladun mii.

Aayan

Oríṣun àwòrán, Getty Images