2022 ASUU strike: Ẹgbẹ́ Olùkọ́ Fásitì ASUU bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì olóṣù kan lónìí

ASUU

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, ASUU

Ẹgbẹ́ Olukọ awọn ile ẹkọ giga Fasiti Naijiria bẹrẹ iyanṣẹlodi oloṣu kan lonii ọjọ Aje, ọjọ kẹrinla, oṣu keji, ọdun 2022.

Ojogbon Musa Abdullahi tó jẹ akọwe iṣẹ iwadii ati eto gbogbo fun ẹgbẹ ASUU ṣalaye fun BBC pe iyanṣẹlodi naa jẹ ikilọ fun ijọba Naijiria lati mu adehun wọn ṣẹ.Ẹgbẹ́ Olùkọ Fásitì ASUU bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì olóṣù kan lónìí

Ki tun ni ASUU tun sọ lori iyanselodi naa?

Ojọgbọn Musa Abdullahi sọ pe ni ọrọ UTAS ti wọn jọ n fa lati 2009 ati adehun ti ijọba sọ ni wahala.

Egbẹ Olukọ naa ni pe ohun lo ṣokunfa ipade ọlọjọ meji ni ipinlẹ Eko ni eyi ti wọn ti wa fi ẹnu ko lori iyanṣẹlodi naa.

ASUU

Oríṣun àwòrán, @ASUU

Ǹjẹ́ lóòótọ́ ni ASUU yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì lónìí? ni ibeere ti ọpọ n beere kaakiri Naijiria bayii.

Ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ilẹ̀ Nàìjíríà (ASUU) ti ní lónìí làwọn yóò forí ìkokò sọ̀ọ́dún lórí ìpinu wọn láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì.

Àkọlé fídíò, OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n...

Láti ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ẹgbẹ́ náà ti bẹ̀rẹ̀ ìpàdé ọlọ́jọ́ méjì láti fẹnukò lórí ìpinu wọn bóyá wọn yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

Ó ṣeéṣe kí ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì, ASUU bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì láìpẹ́

Kini ẹgbẹ ASUU n sọ bayii?

Ṣé lóòtọ́ ní ẹgbẹ́ Olùkọ́ Fásiti, ASUU ti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì?

Ní àṣálẹ́ ọjọ́ Àìkú ni Ààrẹ ẹgbẹ́ ASUU, ọ̀jọ̀gbọ́n Emmanuel Osodeke fi àtẹ̀jáde kan sórí ẹ̀rọ ayélujára Twitter rẹ̀ pé àwọn yóò gùnlé ìyanṣẹ́lódì ṣùgbọ́n ìfẹ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn ṣe pàtàkì.

Àkọlé fídíò, Plights of Widows in Nigeria: Abosede Ilori ní N16,000 ni òun ń gbà fi tọ́jú ọmọ méjì

Osodeke ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹrìnlá , oṣù kejì ni ìyanṣẹ́lódì náà yóò bẹ̀rẹ̀ títí di ìgbà tí ìjọba bá dáhùn gbogbo ohun tí àwọn ń bèèrè fùn ún.

Láti ìgbà pípẹ́ ni ASUU àti ìjọba àpapọ̀ ti ń ṣe ìfaǹfà láàárín ara wọn lórí àdéhùn tí ìjọba ṣe fún ẹgbẹ́ ASUU lọ́dún 2009.

Àkọlé fídíò, Ìdíje ata tútù: Jẹ ata 50, ko gba góólù gírámù mẹ́ta

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá, ASUU ní kí àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga káàkiri orílẹ̀ èdè má wọ yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ láti fi ẹ̀hónú wọn hàn sí ìjọba lórí ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n ń gbèrò.

Ilé ẹ̀kọ́ gíga Bayero, Kano ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ èyí lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ keje, oṣù kejì tí àwọn ilé yòókù náà sì tẹ́wọ́ gbàá nínú ọ̀sẹ̀ kan náà.

Àkọlé fídíò, Olaiya Igwe: Àwọn ọmọde tí mò ń bá ṣe ‘skit’ ló dáwó jọ fún mi nígbà tí àìsàn inú dé sí mi

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù kọkànlá, ọdún 2021, ASUU fún ìjọb àpapọ̀ ní gbèdéke ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti dáhùn gbogbo ìbéèrè àwọn ṣùgbọ́n tí ìjọba kùnà láti ṣe.

Àkọlé fídíò, Adunni Ade: Lóòtọ́ọ́ ní àwọn adarí eré máa ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré-bìnrin

Kini ASUU sọ fun BBC ni pato?

Nígbà tó ń ikọ̀ ìròyìn BBC sọ̀rọ̀, ọ̀jọ̀gbọ́n Osodeke ní láti oṣù kìíní ọdún 2021 ní ìjọba àpapọ̀ ti ṣe àdéhùn fún àwọn ṣùgbọ́n tí wọn kò ṣe àmúṣẹ rẹ̀ títí inú oṣù kejìlá.

Àkọlé fídíò, Bunmi Akinnanu: Ọlọ́run kìí fún èèyàn méjì ní orin ẹ̀mí kan ṣoṣo, ẹ jẹ́ ká ṣe sùúrù

Ósodeke ní láti ìgbà náà ni ìjọba ti ń fi òní dá ọ̀la fún àwọn tí àwọn sì fọwọ́ lẹ́rán nítorí ìfẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn òbí wọn.

Ó fi kun pé gbogbo ọ̀nà tí àwọn mọ̀ ní àwọn ti sà láti fi bá ìjọba sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n kò so èso rere, fún ìdí èyí ìyanṣẹ́lódì ló kù láti lò.

Àkọlé fídíò, Yinka Ayefele: Ìrọ́ ni pé ń kò le ṣe bíi ọkùnrin, mò ń ta pútú dàadáa

ASUU kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa lọ ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ pípẹ́

Ní ọdún 2020, oṣù mẹ́jọ ni ASUU fi yan iṣẹ́ lódì, ìyanṣẹ́lódì náà bẹ̀rẹ̀ nínú ọsù kẹta tó sì parí nínú oṣù kejìlá lẹ́yìn tí ìjọba àti ASUU tọwọ́bọ àdéhùn.

Àkọlé fídíò, Bad Boy Timz: Fásitì ni mo wà tí mo fi kọrin ‘Gbẹ́sẹ̀ lọ́kọ̀ọ́ọ̀kan’ tó sọ mi di gbajúmọ̀

Lẹ́yìn èyí ni ìjọba kéde pé àwọn ti fún ASUU ní ọgbọ̀n bílíọ̀nù Náírà ṣùgbọ́n ASUU ní àwọn kò rí omira débi tí wọn yóò rí ẹ̀jẹ̀ títí di àsìkò yìí.

ASUU ní ìjọba kò ì tíì mú àdéhùn wọn ṣẹ.