Fuel Scarity in Nigeria: NNPC kó èpo tuntun wọ Nàìjíríà, o kéde bí epo àdàlù bẹntiró ṣe wọ Nàìjíríà

ileepo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ko din ni ọkọ oju omi akepo mẹfa ti ajọ elepo rọbi ni Naijiria, NNPC ti ko wọ Naijiria bayii pẹlu bi ọrọ ọwọn gogo epo bẹnito ṣe n de araalu mọlẹ.

Ileeṣẹ aarẹ lo kede eyi lati fi ọkan araalu balẹ pe igbesẹ n lọ lati rii daju pe wahala ọwọn gogo epo rọbi naa tete jẹ rodo lọ mu omi.

Bashir Ahmad, amugbalẹgbẹ fun aarẹ lori ọrọ ayelujara, Bashir Ahmad ṣalaye loju opo twitter rẹ pe, ọọdunrun miliọnu lita epo bẹntiro ni awọn ọkọ oju omi akepo naa n ko wọ Naijiria bayii lati fi bomi pa ina ọwọn epo bẹnitro to n lọ ni Naijiria.

Lati bi ọjọ diẹ sẹyin ni ọrọ ọwọn gogo epo ti gbode kan lorilẹede Naijiria, ti ila gbọrọọgbọ awọn awakọ pẹlu tun ti sun kan iwọnba awọn ile epo to ni epo lati ta.

Awọn alẹnulọrọ lẹka epo rọbi lo jẹ ko han sigboro aye pe amulumala epo nijba apapọ ko wọ Naijiria to si ti n ba awọn ọkọ to ra wọn jẹ.

Àkọlé fídíò, Yinka Ayefele: Ìrọ́ ni pé ń kò le ṣe bíi ọkùnrin, mò ń ta pútú dàadáa

Alamojuto eto majẹobajẹ ninu ẹgbẹ awọn ontaja epo IPMAN, Mike Ọṣatuyi ṣalaye fun BBC nigba naa pe kikọ ti awọn kọ lati gba epo naa ta, lo mu ki ijọba ko wọn kuro lọja lati le e tete ra omiran wọle.

Bakan naa ni ajọ elepo rọbi lorilẹede Naijiria, NNPC ti fi da araalu loju peko si giri, awọn to gbangba sun lyẹ lori ọr okoowo, ipamọ ati karakata epo lorilẹede Naijiria.

Ninu atẹjade kan to fi sita, ọga agba j naa, Kyari ṣalaye pe kii ṣe ohun babara fun aj naa lati pese iye epo ti orilẹede Naijiria le lo laarin asiko perete, eleyi to mu ki gbigbe epo miran wọle si Naijiria o ya ni kiakia ju bi awọn eeyan ṣe ro .

Ikede ti agbẹnusọ fun ileesẹ aarẹ se

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Alaye NNPC lori bi amulumala epo bẹntiro ṣe wọ Naijiria:

Ninu atẹjade naa ti NNPC fi sita, ni ogunjọ oṣu kini ọdun 2022 ni ajọ naa gba iroyin latọd awọn oṣiṣẹ ayẹwo rẹ lori bi wọn ṣe kẹẹfin awọn adalu ninu epo bẹntiro ti wọn ko w Naijiria lati Atwerp-Belgium.

O ṣalaye siwaju sii pe iwadi ajọ NNPC fidi rẹ mulẹ pe eroja Methanol farahan ninu epo ti mẹrin ninu ọkọ ojuomi agbepo to wọ Naijiria naa ko.

O darukọ awọn ileeṣẹ mẹrin to ko awọn epo naa wọle:

1. MRS ---------------------MT Bow pioneer-------------LITASCO Terminal, Antwerp- Belgium

2. Emadeb/Hyde/AY Maikifi/Brittania-U Consortium—-MT Tom Hilde—- (LITASCO Terminal, Antwerp- Belgium

3. Oando—-MT Elka Apollon—-(LITASCO Terminal, Antwerp-Belgium) 4. Duke Oil—-MT Nord Gainer—-(LITASCO Terminal, Antwerp, Belgium)

O fi kun un pe gbogbo iwe aṣẹ to yẹ ni wọn gba to si sọ pe epo ti wọn gbe ba ilana Naijiria mu

"Awọn akọṣẹmọṣẹ ayẹwo ti ajọ NNPC n lo bii GMO, SGS, GeoChem ati G&G ni wọn ṣe ayẹwo to fihan pe wọn ba ilana Naijiria mu,"

Oludari agba ajọ NNPC fidi rẹ mulẹ pe gbogbo ilana ayẹwo gbogbo to yẹ ni wọn tẹle, ṣugbọn kete ti wọn kẹfin pe o n ba awọn ọkọ jẹ ni Oludari ajọ naa ti tete paṣẹ ki wọn ko epo to ku kuro nilẹ.

Ikede ti ileesẹ NNPC se

Oríṣun àwòrán, @NNPCgroup

Alakoso ileesẹ elepo MRS fariga, o ni ibanilorukọ jẹ gba a ni ikede NNPC:

Awọn alaṣẹ MRS ti fariga lori atẹjade NNPC to fi tọka si wọn gẹgẹ bi ọkan lara awọn ileeṣẹ oniṣowo epo to ko lara awọn epo adamọdi wọlu.

Ninu atẹjade to fi sita ṣalaye pe pẹlu ilana eto iranwọ epo ti NNPC fi sita, "NNPC nikan lo n gbe epo bẹntiro wọ Naijiria. Nipasẹ eyi, NNPC latọw onibara rẹ, Duke Oil lo ko epo to ra lọwọ ileeṣẹ iṣowo epo agbaye, Litasco ti wọn si jaa si ebute pẹlu ọkọ ojuomi akepo MT Nord Gainer."

Ileeṣẹ MRS tun ṣalaye pe ọjọ kẹrinlelogun si ọgbọnjọ oṣu kini ọdun 2022 ni wọn ja epo naa si ebute ni Apapa nibi ti awọn oniṣowo epo bii OVH, MRS, NIPCO, ARDOVA, TOTAL ti tẹwọ gba iwọn epo to tọ si wọn.

Atẹjade naa tẹsiwaju pe nigba ti wọn bẹrẹ si ni pin epo naa ni wọn ṣakiyesi pe epo naa n wo bakanbakan, ti wọn si gbe igbesẹ ayẹwo lori rẹ ti wọn wa rii pe o ni ida ogun eroja Methanol ninu rẹ.

"Nitoripe a mọ pe ko yẹ ki eroja ogogoro ethanol o maa wa ninu epo. Kia la fi to ajọ NNPC, NMDPRA ati MOMAN leti ti wọn si ni loot lawn oniṣowo epo yoku n koju iṣoro yii kan naa."

O wa sọ yanya pe ẹsun ti wọn fi kan ileeṣẹ naa pe o ko ayederu epo wọlu kii ṣe otitọ rara.

"MRS kii ṣe oniṣowo to ko epo yii wọle lati ilẹ okeere, ko si ta ọja epo ti ko dara ri rara."

Atẹjade ti ileesẹ elepo MRS fisita

Oríṣun àwòrán, MRS Oil Nigeria PLC

Amin iyasọtọ kan

Fuel Scarity in Nigeria: Òǹtàjà epo àti ìjọba tako ara wọn lórí ọ̀wọ́n epo tó ń wáyé

Ayederu epo

Gbọọrọgbọ bayii lawọn ọkọ n to kaakiri ile epo lawọn ipinlẹ bii Eko, Ogun, Niger, Nasarawa ati olu ilu Naijiria, Abuja.

Ko si idi meji ju bi ọwọgogo epo tun ṣe bẹ silẹ lorilẹede Naijiria bayii lati nnkan bii ọjọ melo kan sẹyin.

Bakan naa pẹlu, lawọn eeyan n to ni kaakiri iwọnba awọn ileepo to ni nilu Eko.

Pupọ awọn ileepo lo gbe iloro ileeṣẹ wọn ti pa ti awọn oṣiṣẹ ibẹ si n sọ fun awọn awakọ ati ero araalu pe awọn ko ni epo.

Bakan naa ni ọrọ ṣe ri ni olu ilu Naijiria, Abuja atawọn ipinlẹ to sun mọ ọ bii Niger ati Nasarawa.

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo n ro pe boya ijọba n gbimọran ati yọ owo iranwọ ori epo ni ki wọn si wa fowo lowo epo nigba naa.

Kini ẹgbẹawọn ontaja epo ni Naijiria sọ?

Awọn eeyan to lati ra epo

Bi ọrọ ba ri bayii lara awọn majẹobajẹ ẹka nepo rọbi lorilẹede Naijiria ni awọn ẹgbẹ ontaja epo wa.

Ninu ọrọ ti awọn ẹgbẹ ontaja epo IPMAN ṣe lalaye lori ọrọ naa, wọn ni ẹbi ajọ epo rọbi Naijiria ni nitori awọn lo ko amulumala epo wọ orilẹede Naijiria eleyi ti awọn ontaja epo faake kọri pe awọn ko ni ta.

Epo ti NNPC gbe sita n ba ọkọ jẹ la se dẹkun epo tita - IPMAN

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Ọgbẹni Michael Ọṣatuyi to jẹ alamojuto iṣẹ gbogbo lẹgbẹ IPMAN lorilẹede Naijiria ṣalaye pe epo ti ajọ epo ijọba gbe sita naa lee ba ọkọ jẹ.

Ọgbẹni Ọṣatuyi ni epo ti wọn ko wọ Naijiria lati oke okun yii ni aniju eroja ifọpo Methanol ti apọju rẹ n ba ọkọ jẹ.

O ni idi niyi ti awọn ontaja epo fi fariga pe awọn ko ni ta epo naa mọ nitoripe lẹyin o rẹyin, yoo ṣe ọpọ akoba fun ọrọ aje wọn ni.

O fi kun pe idi niyi ti ajọ NNPC fi gba lati ko awọn epo naa pada, ki wọn lee gba omiran pada wọle fun tita.

"Ohun to ṣẹlẹ ni pe epo ti ijọba gbe wọle jẹ amulumala. O ni awọn eroja kan to le ba ọkọ jẹ. O si da mi loju wọn ti ko o kuro lọja.

"Ẹ mọ pe iru igbesẹ bẹẹ yoo gba asiko diẹ lati ṣe irọpo rẹ."

Ọgbẹni Ọṣatuyi fi kun un pe ka ni ijọba fi aye silẹfun awọn ontaja epo miran lati maa ko epo wọ Naijiria ni, ti wọn ko jẹ ko jẹ awọn nikan, oṣeeṣe ki ọrọ naa maa ri bo ṣe ri yii.

Awọn eeyan n ra epo sinu ladugbo onike

Alaye ijọba lori ọwọgogo epo naa:

Ajọ to n ri siakoso tita ati rira epo lorilẹede Naijiria, Nigerian Midstream and Downstream Petroleum Regulatory Authority (NMDPRA) ṣalaye pe lootọ ni epo to ni eroja abọkọjẹ naa wa lorilẹede Naijiria ṣugbọn ko fi bẹẹ pọ.

Ninu atẹjade kan ti ajọ ijọba naa fi sita lọjọ Iṣẹgun, Ajọ to n ri siakoso tita ati rira epo lorilẹede Naijiria, Nigerian Midstream and Downstream Petroleum Regulatory Authority (NMDPRA) ṣalaye pe awọn ti ya awọn epo naa sọtọ kuro lara awọn to jẹ ojulowo lọja.

"A ti ri oju ibi ti amulumala epo naa gba wọle, igbesẹ to tọ yoo si waye latọdọ ileeṣẹ epo rọbi Niajiria, NNPC."

Awọn eeyan n ra epo sinu mọto ati ike