Hushpuppi Trial: Malami ní ẹ̀rí ti wà nílẹ̀ tó le mú Abba Kyari jẹ́jọ́ l'Amẹrika

Hushpuppi

Oríṣun àwòrán, Hushpuppi ati Abba Kyari

Agbẹjọro agba ati Minisita eto idajọ ni Naijiria, Abubakar Malami, sọ pe ijọba apapọ Naijiria le gbe igbakeji kọmiṣọna ọlọpaa, Abba Kyari lọ sí orilẹ-ede Amẹrika.

O ni eyi lo ni se lori ẹsun lilu jibiti lori ayelujara ti wọn fi kan Ramon Ọlọrunwa Abbas, ti ọpọ mọ si Hushpuppi.

Malami fidi ọrọ yii mulẹ lasiko to n kopa lori eto nipa ọrọ oselu kan to waye ni ileeṣẹ amohunmaworan Channels lalẹ ọjọ Aje.

Minisita feto idajọ naa ni o dabi ẹni pe Kyari ni lati lọ salaye ara rẹ ni Amẹrika lori ọrọ Hushpuppi.

Àkọlé fídíò, Adunni Ade: Lóòtọ́ọ́ ní àwọn adarí eré máa ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré-bìnrin

Malami ṣalaye idi ti DCP Kyari yoo fi lọ jẹjọ l'Amẹrika:

Malami sọ lori eto ọhun pe ọrọ naa mu ifura wa fun Abba Kyari gẹgẹ iwadii ti ileeṣẹ ọlọpaa ṣe lori ẹsun iwa ibajẹ ti ileeṣẹ ọlọpaa FBI Amerika fi kan an.

Bo tilẹ jẹ pe ẹjọ niiṣe pẹlu Naijiria ati ilẹ okeere, ijọba apapọ ko ni beṣu bẹgba lati jọwọ Kyari fun Amẹrika fun iwadii.

Iṣẹ ṣi n lọwọ lori ọrọ naa, amọ a o ri pe idajọ ododo waye lori ọrọ yii.

Ati wipe pẹlu bi ẹjọ yii ti niṣe pẹlu orilẹ ede UAE ati Amẹrika, ọrọ naa nilo ibaṣepọ to muna doko lori ẹjọ yii.

Ohun ti mo n sọ nipe ijọba Naijiria n ṣiṣẹ pọ pẹlu Amẹrika lati ri pe idajọ ododo waye.

Ti ọrọ naa ba si tun gba ki igbẹjọ waye ni Naijiria, ijọba yoo ri pe o waye.

A ti n sọrọ pẹlu awọn aṣoju ijọba ti ọrọ naa kaa, oriṣiiriṣii iwe ni a ti kọ si ara wa lori ọrọ yii," Malami ṣalaye.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ileeṣẹ ọlọpaa FBI fẹsun kan DCP Kyari lori ẹsun jibiti ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ti wọn fi kan Hushpuppi.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria ti kọkọ gbe igbimọ kan dide lati ṣe iwadii DCP Kyari.

Lẹyin naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni ki Kyari lọ rọkun nile ninu ẹka IRT to wa.

Àkọlé fídíò, Wo aburú àti ìpalára tí òògùn olóró Kush tuntun yí n ṣé ní Sierra Leone

Bawo ni gbogbo ọrọ Abba Kyari ati Hushpuppi ṣe bẹrẹ?

Gbajugba orí Instagram to jẹ ọmọ Naijiria, Ramon Abass tí ọ̀pọ̀ mọ sì Hushpuppi bẹbẹ pé òun kò jebi esun kejì nínú gbogbo èyí ti wọn fi kan an ni ile ejo Amerika èyí tó ní ṣe pelu jìjì owó.

Lára ohun tó tún wà nínú ìwé aridaju ẹri tó wà níwájú ilé ejò ni pé Abbas fún Oga Olopaa Naijiria kan ni owo abetele, ti iwadii ni Amẹrika si fihan pé Igbakeji Oga Olopaa Abba Kyari ni.

Ní báyìí pelu bí ejò ṣe ń lọ, ó seese kí Hushpuppi fi ẹ̀wọ̀n ogún ọdún gbàrà gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà nínú ìwé ilé ẹjọ́.

DCP Abba Kyari ni oun ko beere fun owo kankan lọwọ Hushpuppi

Nigba ti asiri ọrọ naa tu sita, igbakeji kọmisana ọlọpaa ni Naijiria, Abba Kyari sọ pe irọ ni ẹsun ti wọn fi kan ileeṣẹ ọlọpaa pe wọn gba owo lọwọ Raymond 'Husspuppi' Igbalode to n jẹjọ lọwọ ni Amẹrika.

Bakan naa, wọn fẹsun kan pe Hushpuppi fun Abba Kyari ni owo abẹtẹlẹ.

Ẹka to n ri si idajọ nilẹ Amẹrika sọ pe awọn ti fi panpẹ ofin mu ọmọ orilẹede Naijiria mẹta bayii ni Amẹrika to n ran Hushpuppi Abbas lọwọ to fi ji miliọnu owo Dollar $1.1m ni ọna idigunjale wiwọke owo jade.

Ninu atẹjade ti wọn fi sita lati ẹka ile ẹjọ naa ni ọjọ kejidinlọgbn oṣu keje, 2021 sọ pe Hushpuppi jẹwọ to si gba pe lootọ ni oun jẹbi ẹsun jiji owo gọbọi atawọn ẹsun mii to lu mọ eto akanṣe katakara "Business Email Compromise Schemes".