Hushpuppi: Wo ìdí tí ilé ẹjọ́ ilẹ̀ America fi sún ọjọ́ ìdájọ́ Hushpuppi síwájú

Hushpuppi

Oríṣun àwòrán, Hushpuppi

Ile ẹjọ ilẹ America ti sun ọjọ idajọ lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan ọmọ Naijiria, Ramoni Abbas ti ọpọ mọ si Hushpuppi si ọjọ kọkanla, oṣu Keje.

Agbẹnusọ fun ile ẹjọ naa, Thom Mrozek sọ fun BBC Pidgin pe ile ẹjọ sun idajọ nitori pe olori awọn agbẹjọro fun Hushpuppi, Loius Shapiro, beere fun.

Ọdun 2020 ni ọwọ awọn ọlọpaa orilẹ-ede Dubai tẹ Hushpuppi nibi to n gbe.

Lati igba naa si lo ti wa ni ọgba ẹwọn nilẹ america fun ẹsun lilu jibiti lori ayelujara, eyi ti owo rẹ to miliọnu mẹrinlelogun Dọla.

Ọjọ kẹrinla, oṣu Keji ọdun yii lo yẹ ki idajọ o waye lori ẹsun naa.

Akọsilẹ ile ẹjọ ti Mrozek fi ranṣẹ si BBC fihan pe Onidajọ agbegbe, Onidajọ Otis D. Wright lo buwọlu sisun ọjọ idajọ siwaju.

Ọgbẹni Mrozek sọ pe ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun 2022 ni idajọ yoo tẹsiwaju lori ọrọ Hushpuppi ni aago mọkanla owurọ.

Botilẹ jẹ pe ko sọ bi idajọ naa yoo sẹ lọ, Mrozek sọ pe wọn o le Hushpuppi kuro nilẹ America to ba fi pari ẹwọn rẹ.

Bawo ni ọwọ ṣe tẹ Hushpuppi?

Hushpuppi

Oríṣun àwòrán, Hushpuppi

Ki ọwọ to o tẹ, gbajumọ olowo ati onifaaji ni Ramoni Abass Hushpuppi lori ayelujara Instagram.

O ma n ṣafihan owo, aṣọ, ọkọ ati awọn dukia mii to ni.

Inu oṣu Kẹfa, ọdun 2020 ni ọwọ tẹ ẹ nilu Dubai, lẹyin ti wọn fi ẹsun kan an pe o n gbero lati ji ọpọlọpọ miliọnu Dọla nipa jibiti ori ayelujara.

Ileeṣẹ amofin kan nilẹ America, banki ilẹ okeere kan, ati ẹgbẹ agbabọọlu kan ninu idije Premier League lo n gbiyanju lati ja lole.

Oṣu Keje ni Dubai fi ranṣẹ si ilu Chicago lorilẹ-ede America labẹ amojuto ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ FBI.

Awọn onimọ nipa iwa ọdaran woye pe o sẹ e ṣe ki Hushpuppi lo to ogun ọdun ni ẹwọn, ti ile ẹjọ ba fi ri i pe o jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

Hushpuppi nile ẹjọ ilẹ America

Oríṣun àwòrán, others

Hushpuppi nikan kọ ni ọmọ Naijiria to n jẹjọ ẹsun jibiti ori ayelujara ni America.

Ọmọ Naijiria niran, Obinwanne Okeke, ti ọpọ mọ si Invictus Obi naa wa lẹwọn lọwọlọwọ.

Ẹwọn ọdun mẹwaa nile ẹjọ kan ni agbegbe Virginia Raj Parekh ju u si.

Wọn fi ẹsun kan an pe o lu awọn eeyan kan ni jibiti owo to to miliọnu mọkanla Dọla.