Islamic State leader Abu Ibrahim al-Qurayshi killed : Àwọn ọmọ ogun America pa olórí ISIS, Ibrahim al-Qurayshi ní Syria

Oríṣun àwòrán, US DEPARTMENT OF STATE
Awọn ọmọ ogun ilẹ America ti pa olori ikọ agbesunmọmi Islamic State of Iraq and Syria ni Ariwa orilẹ-ede Syria loru mọju Ọjọbọ.
Aarẹ America, Joe Biden to kede iroyin naa sọ pe iku Abu Ibrahim al-Hashimi al-Qurayshi ti mu ọkan pataki lara awọn agbesunmọmi to n ni aye lara kuro.
Qurayshi fi ọwọ ara rẹ tú ado oloro to pa oun ati mọlẹbi rẹ .
- Ìjọba Kano fẹ̀sùn oníkókó márùn ún kan àwọn afurasí tó pa ọmọ ọdún márùn ún Hanifa
- Àwọn agbébọn pa ọgọ́ta èèyàn ní ibùdó ìfiniwọ̀ ní DR Congo
- Àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Àdúláwọ̀ fòfin de Burkina Faso lórí ìdìtẹ̀gbàjọba
- Nkan dẹnu kọlẹ̀ ní àwọn agbègbè kan ní America nítorí ìjì líle
- Orílẹ̀-èdè North Korea ṣe ìfilọ́lẹ̀ àdó olóró tó tóbi jùlọ láti ọdún 2017
- Wo àwọn ìgbéyàwó tí ayé pariwo wọ́n lọ́dún tó lọ
Awọn oṣiṣẹ addola ni Syria sọ pe oku eeyan mẹtala ni awọn ri lẹyin ikọlu ti awọn ọmọ ogun ṣe.
Ilu Atmeh, ti ko fi bẹẹ jina si ẹnu ibode pẹlu orilẹ-ede Turkey,ni ikọlu naa ti waye.
Ṣaaju ni iwadii ti fihan awọn ologun pe ile alájà pupọ kan ni Qurayshi n gbe pẹlu mọlẹbi rẹ ni Atmeh, ati pe kii jade sita rara.

Oríṣun àwòrán, EPA
Dipo ko jade, awọn abani fi ẹru ranṣẹ lo ma n fi iṣẹ ran si awọn ọmọ ẹyin rẹ ni ibudo wọn ni Syria ati awọn ibomiran.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe awọn ọmọ ikọ naa kan doju ija kọ awọn ọmọ ogun America pẹlu ibọn ti wọn n yin si ọkọ baalu ti wọn fẹ fi kọlu ile Qurayshi.
Wakati meji si ni iro ibọn fi n dun ki awọn baalu ẹlikọpita naa to o lọ.
Awọn alaṣẹ ilẹ America sọ pe awọn doola idile kan to n gbe ni aja kinni ile naa, ki wọn o to o kọlu u.

Oríṣun àwòrán, EPA
Oṣu Kẹwaa, ọdun 2019 ni ẹgbẹ IS yan Abu Ibrahim al-Qurayshi ni adari tuntun.
Eyi waye lẹyin ọjọ mẹrin ti Abu Bakr al-Baghdadi ku, amọ wọn ko fi orukọ rẹ gan-an-gan tabi aworan sita.
Lẹyin asiko diẹ ni ilẹ America ri aṣiri pe ogbontagi alakatakiti ẹsin kan lati Iraq ni.
- Àwọn nǹkan mẹ́ta tí a kò tíì mọ̀ nípa Covid-19 lẹ́yìn tí àrùn náà bẹ́ sílẹ̀ rèé
- Ìjọba Nàìjíríà kéde ìlànà tuntun lórí COVID-19, Ó mú àdínkù bá ìye èèyàn tó lè wọ ṣọ́ọ̀ṣì, mọ́sáláṣí
- Okòòwò márùn ún tí o lè bẹ̀rẹ̀ nínú ilé rẹ̀
- Ẹ kó àwọn ọmọ ọdún 12 títí dé 15 wá fún abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19
- Ṣé ẹ ti gbọ́ nípa òògùn ìbílẹ̀ Coronavirus tí Ooni filọ́lẹ̀? Ó ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó ní Covid-19 ló ti gbádùn
Ọdun 1976 ni wọn bi nilu Mosul.
Awọn orukọ to n jẹ ni Hajji Abdullah, Amir Mohammed Said Abdul Rahman al-Mawla ati Abdullah Qardash.
Ilẹ America sọ pe "Apanirun" ni orukọ ti awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ n pe e.













