Hanifa death: Ìjọba fẹ̀sùn oníkókó márùnún kan àwọn afurasí tó pa akẹ́kọ̀ ọmọ ọdún márùn ún

Hanifa Abubakar atawọn afurasi to pa a

Oríṣun àwòrán, Hanifa Abubakar family

Ipinlẹ Kano tun ti fẹsun onikoko marun un kan afurasi Abdulmaliq Tanko atawọn meji mii lori ẹsun pe wọin ṣekupa ọmọ ọdun marun un, Hanifa Abubakar ni kano.

Tanko, Hashimu Isiyaku ati Fatima Musa n jẹjọ niwaju adajọ majisireeti Muhammad Jibrin fun ẹsun ipaniyan, ijinigbe and gbigbe eeyan pamọ.

Ẹsun ti wọn fi kan gbogbo wọn ni ijinigbe ati iṣekupa Hanifa pẹlu majele.

Ẹsun ti wọn fi kan awọn afurasi to pa Hanifa

Tanko atawọn eeyan meji mii n jẹjọ lori ẹsun ijinigbe.

Ara ẹsun mii ti wọn fi kan wọn ni lilo oogun peku peku lati pa ọmọ ọdun marun un Hanifa.

Àkọlé fídíò, Akàwégboyè alákàrà

Wọn ti fi eṣun mii kan wọn pe wọn gbimọ pọ lati sin Hanifa ninu iboji ti ko jin.

Ẹsun iṣekupani Hanifa lẹyin ti wọn ti kọkọ gba ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira ninu miliọnu mẹfa owo itusilẹ ti wọn beere fun lati ọdọ awọn obi rẹ.

Àkọlé fídíò, OLota

Ohun ti adajọ majisireeti sọ ree

Adajọ majisireeti Jubrin paṣẹ pe ki wọn ju awọn afurasi mẹtẹẹta si atimọle titi di asiko igbẹjọ mii.

Amọ, agbẹjọro fun olupẹjọ, Aisha Mahmud sọ fun ileẹjọ ni Ọjọru pe ijọba ti pinnu lati gbe ẹjọ naa lọ si ile ẹjọ giga.

Àkọlé fídíò, Alhaji Shanko

Mahmud to tun jẹ ọga agba ajọ to n ri si igbẹjọ nipinlẹ Kano ṣalaye pe igbesẹ ko ṣẹyin bi ileẹjọ majisireeti ko ṣe ni aṣẹ lati gbọ iru ẹjọ bayii.

O wa rọ ileẹjọ lati fi awọn afurasi silẹ ni atimọle fun ọjọ meje ti eto lati gbe ẹjọ naa kro nile ẹjọ majisireeti yoo fi kẹsẹ jari.

Àkọlé fídíò, Ipaniyan Ogun

Ọrọ agbẹjọro fun olupẹjọ

Mahmud ni Tanko atawọn afurasi meji toku yoo jẹjọ lori ẹsun ipaniyan.

Awọn afurasi meji yoku naa yoo jẹjọ lori ẹsun ijinigbe ati igbimọ pọ lati huwa ọdaran.

Àkọlé fídíò, Ikere Ekiti: Olúkẹ̀ẹ́rẹ́ àti Ògògà tako ara wọn lórí ẹni tíí ṣe aláṣẹ ilú Ikere

Mahmud ni ''agbẹyẹwo ẹsun ti wọn fi kan Tanko afurasi meji yoku yii fihan pe ileẹjọ majisireeti ko lagbara lati gbọ ẹjọ yii,

Iyẹn lo jẹ ki a gbe ẹjọ naa lọ siwaju ile ẹjọ giga bayii.''

Àkọlé fídíò, Tọktaya afọju ti Eledua tun fi ibeji ta lọrẹ

Adajọ majisireeti naa gba si agbẹjọro olupẹjọ lẹnu, o si sun igbẹjọ naa siwaju si ọjọ kẹsan an oṣu keji.

Ko si agbẹjọro fawọn afurasi nile ẹjọ, ṣugbọn agbẹjọro olupẹjọ ni ile ẹjọ giga yoo gbe igbesẹ lori iyẹn ti ẹjọ naa ba de ibẹ.

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke