Shisha smoking students: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin méjì tó ń fa shisha ti padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ wọn

Awọn akẹkọọ to n fa shisha

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Awọn akẹkọọbinrin ile ẹkọ girama kan ti wọn da duro nitori pe wọn n fa shisha ninu aṣọ ile ẹkọ wọnlagbegbe Onikolobo ni ipinlẹ Ogun ti pada si ẹnu ẹkọ wọn bayii.

Fidio to ṣe afihan awọn akẹkọọ naa nibi ti wọn ti n fa shisha ti lu ori ayelujara pa ki ijọba ipinlẹ Ogun to ni ki wọn lọ rọkun nile.

Amọ, kọmiṣọnna eto ẹkọ, Abayomi Arigbagbu lo kede igbesẹ ijọba lati dawọn akẹkọọ naa pada sẹnu ẹkọ wọn.

Ijọba ṣalaye idi to fi dawọn akẹkọọ naa pada sile ẹkọ ni kiakia

Kọmiṣọnna eto ẹkọ ṣalaye pe ijọba ni kawọn akẹkọọ naa pada sile ẹkọ wọn lẹyin ti awọn akọṣẹ-mọṣẹ ti ba wọn sọrọ tan.

Arigbagbu ni oniruuru eto igbaninimọran ni awọn akẹkọọ naa ti gba.

Àkọlé fídíò, Ogun King Killing: Baálẹ̀ Agodo ní ààrin Ẹ̀gẹ́ ni òun sùn mọ́jú, tí òun kò sì rí aya, ọmọ

Wọn si ti yẹ lati pada si ẹnu ẹkọ wọn bayii pẹlu idanilẹkọ ti wọn ti gba.

Ni oṣu kejila ọdun 2021 ni ijọba ni kawọn akẹkọọ meji ọhun lọ rọkun nle lẹyin ti wọn ṣe aṣemọṣe yii.

Àkọlé fídíò, Ipaniyan Ogun

Ijiya fun awọn akẹkọọ to n fa shisha

Kọmiṣọnna eto ẹkọ nipinlẹ Ogun sọ pe awọn akẹkọọ yii ti ṣiṣẹ aṣekara nile ẹkọ wọn.

Àkọlé fídíò, Ikere Ekiti: Olúkẹ̀ẹ́rẹ́ àti Ògògà tako ara wọn lórí ẹni tíí ṣe aláṣẹ ilú Ikere

O ni eyi yoo jẹ ẹkọ fawọn akẹgbẹ wọn to ba fẹ hu iru iwa bayii lati ki ọwọ ọmọ bọ aṣọ.

Arigbagbu ni ijọba ti ṣe eto lati dẹkun iwa ibajẹ awọn akẹkọọ kaakiri ile ẹkọ nipinlẹ Ogun.

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke

Erongba ijọba lati dẹkun iwa ibajẹ nile ẹkọ

Kọmiṣọnna eto ẹkọ ti ṣalaye pe ijọba ti ṣe alakalẹ oniruuru ọna lati dẹkun iwa ibajẹ awọn akẹkọọ.

O ni lara wọn ni pe akẹkọọ ti ko ba gbẹkọ ni yara igbẹkọ rẹ daadaa ko ni lanfaani lati kọ idanwo rẹ.

Àkọlé fídíò, Zazzu Portable: Èmi ni mo ni Zazzu Zeh, orúkọ mi ló wà níbẹ̀ àmọ́ wọ́n fẹ́ gbá mi

Arigbagbu sọ pe igbesẹ yii wa lati da ṣeria fawọn akẹkọọ to n ba sa nile ẹkọ.

Akọwe agba ni ileeṣẹ ijọba to n ri eto ẹko, Abosede Ogunleye, ti wa rọ awọn akẹkọọ lati kọju si ẹkọ wọn.

O ni ki wọn yago fun iwa ti o le ba ọjọ iwaju wọn ti o dara jẹ tabi ti o ba orukọ idile ti wọn ti jade jẹ.

Àkọlé fídíò, Omi Daji: Odò tó dédé sàn jáde tí kìí gbẹ tòjò tẹ̀ẹ̀rùn, wọn kìí pa tàbí jẹ ẹja inú rẹ̀