Nigeria 2023 election: Aminu Waziri Tambuwal fi èròńgbà rẹ̀ láti díje dupò aàrẹ̀ Nàìjíríà

Tambuwal

Oríṣun àwòrán, @Sokoto Gov office facebook

Kini o ṣokunfa ipinnu Aminu Waziri Tambuwal tó fẹ̀ gbé àpótí ìdìbò ààrẹ Nàìjíríà nígbà kejì?

''Mo ti tẹti gbọ ohun tawọn ọmọ ẹgbẹ wa sọ,tori naa lo mu mi kede erongba mii lati dije dupo aarẹ Naijiria.''

Ọrọ yi ni Gomina ipinlẹ Sokoto Amnu Waziri Tambuwal fi se ikede erongba rẹ lọjọ Aje toun naa si darapọ mọ awọn ton gbero lati di ipo aarẹ Naijiria muninu idibo 2023.

Gomina yi to ti fi igba kan jẹ olori ile asofin Naijiria fi ero rẹ lelẹ ni ipinlẹ Sokoto lẹyin ipade to se pẹlu awọn alẹnulọrọ.

Tambuwal sọ pe oun gbe igbesẹ yi lẹyin tawọn to wa ni ẹka ẹgbẹ naa nipinlẹ Sokoto kesi oun ati pe oun ti setan lati bẹrẹ ijiroro kaakiri Naijria lati le tẹsiwaju pẹlu erongba yi.

''Mo ti gbọ ohun awọn agbaagba ẹgbẹ obinrin,ati ọdọ lori pe ki n bẹrẹ ki n si tẹsiwaju pẹlu ijiroro nipa erongba mi lati dije ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ wa''

Àkọlé fídíò, Dele Momodu: Gbogbo aáyan àwa Nadeco láti tú Abiola sílẹ̀ ni kò hàn sí Kọla Abiọla

Ipo wo ni Tambuwal ni oun kọkọ fẹ du?

Aminu Tambuwal tẹsiwaju pe: ''nigba tawọn ọmọ ile asofin Naijiria ti saa keje kan si mi pe awọn fẹ ki n di ipo olori ile mu nigba na,

Mo sọ awọn asọkalẹ kọọkan to fi mọ pe mo ni awọn baba nigbẹjọ bi Sheu Shagari ati Aliyu Wamakko ati awọn meji mii ni ipinlẹ Sokoto''

Koda, Mo sọ fun wọn pe ki wọn lọ si ipinlẹ mi ki wọn si ba awọn olori yi jiroro, bi wọn ba fasẹ sii, mo ma a gba aba yin ti ma a si du ipo olori ile asofin''

O fi kun pe: ''Sheu Shagari sọ fun wọn nigba naa pe 'bi ẹ ba fẹ fa ọmọ wa kalẹ, ko gbọdọ jẹ nitori ẹlẹyamẹya tab notori ẹsin' ''

Tambuwal pari ọrọ rẹ pe erongba tootọ lawọn eeyan gbọdọ lo lati mu olori Naijiria ti yoo se orileede naa ati gbogbo araalu lanfaani.

Àkọlé fídíò, Alhaji Shanko

Ta ni Tambuwal lagbo oselu Naijiria?

Odu ni Aminu Waziri Tambuwal lagbo oselu.

Agbẹjọro yi yan oselu laayo to si jẹ ọkan lara awọn eekanninu ẹgbẹ oselu PDP to wa bayii.

Àkọlé fídíò, Eba

Saaju ki o to darapọ mọ ẹgbẹ PDP abẹ asa ẹgbẹ All Nigeria Congress Party ANCP lo dje dupo to fi kọkọ lọ si ile asofin agba Naijiria lọdun 2003.

Lati igba taa n wi yi, ile asofin Naijiria lo ti di ilumọọka paapa bo ti se di olori ile asojusofin lọdun 2011-2015.

Àkọlé fídíò, Sikiru Alabi

Ninu irinajo Tambuwal, kini kan to jẹ́ yọ ni bo ti se n fo lati inu ẹgbẹ oselu kan si omiran.

O kere tan lati igba to ti darapọ mọ ẹgbẹ oselu ANPP to fi bẹrẹ lọdun 2003, o ti paarọ ẹgbẹ lati ANPP lọ si DPP,ANPP,PDP to si tun bẹ lọ si APC ko to tun pada si PDP bayii:

•2003 ANPP

•2007 DPP

•2007 ANPP

•2007 PDP

•2014 APC

•2018 PDP

Àkọlé fídíò, Buga Jesse

Tambuwal ati erongba rẹ lati di aarẹ Naijiria kii se nkan to sẹsẹ bẹrẹ loni

Lọdun 2018 oun ati awọn oludije mii jijọ dije du tikẹẹti ẹgbẹ oselu PDP lati soju ẹgbẹ naa.

Ko pegede ninu igbiyanju yi sugbọn o tun ti wa gbe apoti idibo bayii lati ri tikẹẹti ẹgbẹ PDP gba lati soju wọn ninu idibo 2023.

Àkọlé fídíò, Akàwégboyè alákàrà

Tambuwal ti wa kun awọn oludije mii to jade pe awọn fẹ du ipo aarẹ lọdun 2023.

Ninu ẹgbẹ PDP yoo maa koju awọn oloselu mii to dantọ bi Abubakar Bukola Saraki, Atiku Abubakar ati awọn miran.