Isbae u, boyfriend mummy wa: Ẹ foríjìnmí, ẹlẹ́ran ara ni mí- Gbajúgbajà adẹ́rìnpòṣónú, Bae_U Adebayo Ridwan Abidemi

Adebayo

Oríṣun àwòrán, @Isbae-u

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gbajúgbajà adẹ́rìnpòṣónú, Adebayo Ridwan Abidemi tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí IsBae_U ti fèsì sí ẹ̀sùn tí àwọn obìnrin kan fi kàn án pé ó máa ń bèrè fún ìbálòpọ̀ kí ó tó fi wọ́n sínú eré.

Lórí fọ́nrán kan tó fi sórí ẹ̀rọ Instagram rẹ̀ lónìí, Bae_U sọ pé láti ìgbà tí awuyewuye ọ̀hún ti bẹ̀rẹ̀ ni ọkàn òun kò ti balẹ̀ mọ́ àti pé òun gbà pé òun ṣe àṣìṣe ńlá.

Ó ní òun kò dá ẹni kankan lẹ́bi fún ìwà náà bíkòṣe ara òun, tí òun sì gbà wí pé òun ti ṣẹ̀, tó sì tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn olólùfẹ́ òun.

Adebayo fi kun un pé arábìnrin tó fi fọ́nrán náà síta ni ó ti ń fi fọ́nrán náà gbowó lọ́wọ́ òun ni.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Adebayo

Oríṣun àwòrán, @Isbae-u

Báwo lọ̀rọ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀?

Ní ọjọ́ Àìkú ní 'Gistlover' fi sórí ẹ̀rọ Instagram pé Isbae U máa ń ní kí àwọn obìnrin fi ẹ̀yìn lélẹ̀ kí ó tó le fi wọ́n sí ipò nínú eré rẹ̀.

Àkọlé fídíò, Sikiru Alabi

Onírúurú àwòrán tó ní ibi tí Bae U ti ń bá àwọn obìnrin náà sọ̀rọ̀ ló fi sí orí ẹ̀rọ rẹ̀.

Èyí ti ń mú kí àwọn ènìyàn máa sọ oríṣìíríṣìí nǹkan nípa rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Àkọlé fídíò, Eba

Ta ni Bae U?

Adebayo Ridwan tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Bae U Barbie jẹ́ adẹ́rìnpòṣónú lórí Instagram.

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke

Adebayo Ridwan ní òun bẹ̀rẹ̀ eré ìpanilẹ́rìn-ín lẹ́yìn tí ìrònú fẹ́ pa òun sílé.

Ó ní fúnra òun lò ń tọ́jú ara òun kí Ọlọ́hun tó fi ọ̀nà iṣẹ́ tí òun ń ṣe mọ òun.

Bákan náà ló máa ń ṣeré ìtàgé.

Àkọlé fídíò, Olùdíje gómìnà APC