Olubadan stool: Àwọn Olóyè ti wọ́gilé ẹjọ́ tí wọ́n pé tẹ́lẹ̀ lórí bí a ṣe ń jẹ ọba Olúbàdàn

Olubadan

Oríṣun àwòrán, Others

Ile ẹjọ giga ni ilu Ibadan ti da ẹjọ ti awọn Oloye Ibadan tó gba ade lọwọ Gomina Ajimobi pe nu ni Ibadan.

Adajo Munta Abimbola lo da ẹjọ yii nu nile ẹjọ giga loni ọjọ Iṣegun.

O ni nibayii, ko si igbẹjọ kankan mọ nile ẹjọ to n di yiyan Olubadan tuntun lọwọ mọ.

Adajọ naa ni ki awọn afọbajẹ bẹrẹ igbesẹ yiyan Olubadan tuntun bayii.

Bawo ni ọrọ ṣe jẹ nile ẹjọ?

Adajo Munta Abimbola da igbẹjọ ti Senato Lekna Balogun ati awọn Oloye meje mii pe nu ni Ibadan.

Saaju ni wọn ti pe ẹjọ naa lati fi onte le oye Oba ti gomina ana fun ipinlẹ Oyo, oloogbe Abiola Ajimobi fi wọn jẹ.

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke

Wọn pe ẹjọ naa tako eyi ti o waye ni ọjọ kokandinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 2019 tẹlẹ ni.

Adajo naa wa ni gbogbo eto ti tẹlẹ ofin yiayna ati kikede Olubadan ti ọdun 1957 bi o ṣe wa lati ọdun mọdun ni ilẹ Ibadan ni eyi ti awọn igbesẹ to ti waye sẹyin ko daru rara.

Awon Oloye Ibadan

Oríṣun àwòrán, others

Kini o ti ṣẹlẹ séyin?

Àwọn Olóyè ti wọ́gilé ẹjọ́ tí wọ́n pé tẹ́lẹ̀ lórí bí a ṣe ń jẹ ọba Olúbàdàn

Oro jije oye Olubadan ti ile Ibadan ti bere lati igba ti Oba Saliu Adetunji ti kọ́kọ́ waja laipe.Wọ́n ti gbé Olubadan wọ káà ilẹ̀, bí ìsìnkú Ọba Adetunji ṣe lọ nìyí

Oloye Lekan Balogun ati awọn oloye agba mii ti kọwe ranṣẹ si agbejọro wọn, Kunle Ṣọbaloju lati dẹkun ẹjọ ti wọn pe tako aṣẹ ti o lodi si bi wọn ṣe sọ awọn oloye agba naa di ọba.

Àkọlé fídíò, Eba

Iwe naa ti wọn kọ ni ọgbọn ọjọ, oṣu kini, ọdun 2020 eleyii ti o to awọn oniroyin lọwọ lo fi idi ẹ mulẹ pe igbesẹ naa waye ki omi alafia to n jọba nilu Ibadan ma baa daru.

Eyii si n waye gẹgẹ bi awọn oloye agba ti ọrọ naa kan ṣe sọọ ninu lẹta ti wọn kọọ pe "ki atungbeyẹwo ilana bi a ṣe n jẹ Olubadan ti ilẹ Ibadan tọdun 1957 ṣi dẹdsẹ duro naa di asiko Olubadan ti ilẹ Ibadan tuntun".

Àkọlé fídíò, Buga Jesse

Kini o ti kọ́kọ́ sele seyin lori yiyan Olubadan ati ile ejo?

Saaju ni iroyin gbode kan wi pe o ṣeeṣe ki rogbodiyan mii tun ṣẹyọ lori ẹni ti oye Olubadan kan nitori pe ẹjọ ti wọn pe lori ọrọ naa ṣi wa nilẹ ẹjọ.

Àkọlé fídíò, Sikiru Alabi

Ninu igbẹjọ to waye lọjọ kẹrinla, oṣu kini ọdun yii, Adajọ Munta Abimbọla to jẹ adajọ agba n'ipinlẹ Ọyọ kesi awọn ti ẹjọ naa kan lati wa wi tẹnu wọn.

O ni pe nipasẹ awọn agbẹjọro to n ṣoju fun wọn lori erongba wọn nipa lilọ ile ẹjọ kotẹmilọrun lori ọrọ naa.

Àkọlé fídíò, Tọktaya afọju ti Eledua tun fi ibeji ta lọrẹ

Ọjọ kini, oṣu keji ọdun yii si ni wọn da fun wọn lati fi ara han.

Nibo ni oro iwe ipejó náà dé duro bayii?

Àkọlé fídíò, Omi Daji: Odò tó dédé sàn jáde tí kìí gbẹ tòjò tẹ̀ẹ̀rùn, wọn kìí pa tàbí jẹ ẹja inú rẹ̀

Ṣugbọn nibayii ti awọn oloye naa ti kesi agbẹjọro wọn lati wọgile ẹjọ naa, o ti han gbangba wi pe gbogbo rogbodiyan ti o rọ mọ ẹni ti o kan lati jẹ oye Olubadan ti ilẹ Ibadan ti tẹnubodo.

Eyi si tumo si pe ko si ejo mo nile ejo lori yiyan olubadan.

Àkọlé fídíò, Ikere Ekiti: Olúkẹ̀ẹ́rẹ́ àti Ògògà tako ara wọn lórí ẹni tíí ṣe aláṣẹ ilú Ikere