OAU internal strike: ASUU Fasiti Obafemi Awolowo fárígá, ìyansẹ́lódì tẹ̀síwájú lórí pínpín owó àjemọ́n;ú àwon Olùkọ́

Oríṣun àwòrán, @OAU
Egbẹ olukọ fasiti Obafemi Awolowo ti gunle iyansẹlodi ọlọjọ gbọrọ lori ainiyanju ọrọ nipa bi wọn yoo ti se pin owo ajẹmọnu wọn.
Lọjọ Aje yi ni wọn bẹrẹ iyansẹlodi wọn.
Alaga ẹgbẹ naa ni fasiti Obafemi Awolowo, arakunrin Adeola Egbedoku sọ fun ileesẹ iroyin Naijiria Premium Times pe patapata lawọn yoo gun le iyansẹlodi naa.
Wọn ni awọn alasẹ ilẹ ẹkọ naa faake kọri lati san awọn owo ajẹmọnu ti o jẹ ẹtọ awọn.
- Ọlọ́run ló ní kí Abacha kú, àwọn àgbà Yorùbá púpò kò bá ṣòfò- Dele Momodu
- Wo àwọn ọmọ Yorùbá mẹ́fà tí ẹnu ń kùn lórí ìbò ààrẹ ọdún 2023
- Ọmọ Nàíjíríà, ẹ yé yan àwọn ‘Grandpa’ ní ààrẹ, ẹ wá ọlọ́gbọ́n ọ̀dọ́ tó tún sán-an-gun - Seyi Makinde
- Ẹ̀yín àgbà Yorùbá, ẹ dìde yanjú aáwọ̀ òṣèlú láàrin Tinubu àti Osinbajo, bíbẹ̀ẹ́kọ́... - Ajulo
- Sanwo-Olu kède iye tí àwọn aráàlú yóò máa wọ ọkọ̀ ojú irin ayára bí àṣá tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ́ rà
- Pásítọ̀ ti ríran sí mi pé mà á jẹ Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ọdún 2018- Dele Momodu
- Makinde, Dele Momodu ń ṣèdárò Àgbà Oyè Ilẹ̀ Ibadan, Harry Akande tó jáde láyé
Kini o fa gbonmisii omi ko too laarin won?
Owo ti ijoba apapo san si asuwon Fasiti naa lo fa edeaiyede yi.
ASUU fẹsun kan alasẹ fasii labẹ akoso Ọjọgbọn Eyitope Ogunbodede pe wọn mọomọ se idiwọ owo yi ti awọn olukọ naa sọ pe ijọba ti san si akoto owo fasiti lati ọjọ kẹtala, osu Kejila ọdun 2021.
Ilee'se iroyin Premium Times jabọ pe ẹgbẹ ASUU gbe igbesẹ yi lẹyin ipade pajawiri ti ẹgbẹ se ni gbọngan ikẹkọọ fasiti naa lọjọ Aje.
Kini awon Alase Fasiti naa n so?
Amọ, awọn alasẹ fasiti naa ti wọn ti saaju sọ pe ọrọ ara wa ni ihalẹ awọn akẹkọọ yi jẹ ti wa sọ pe awọn n woye ọrọ yi ko to di pe awọn yoo gbe igbesẹ kankan.
Bawo lọrọ se de ibi to de yi?
Iwadii PREMIUM TIMES fi han pe ohun to mu ki owo ajẹmọnu yi pẹ ni pinpin ko ju pe awọn ẹgbẹ olukọ fasiti ko fẹnuko pẹlu awọn ẹgbẹ olukọ lori ọna ti wn yoo fi pin owo yi.
Eka asuu fasiti naa ati ikọ ẹgbẹ fasiti mi iyẹn Congress of Nigerian Universities' Academics ni wọn jijọ ni ero ọtọọtọ lori owo pinpin yi.
Ilana ọtọọtọ ni wọn gbe kalẹ ti fasiti si ni ki wọn pa mejeeji pọ di ọkan soso.
- Àwùjọ àgbáyé, ẹ ṣèrànwọ́ fún Burkina Faso kó le borí ìṣòro - Olórí ìjọba ológun
- Sanwo-Olu kède iye tí àwọn aráàlú yóò máa wọ ọkọ̀ ojú irin ayára bí àṣá tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ́ rà
- Osun la fẹ́ kí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ti wáyé, kìí ṣe Abuja - Mọ̀lẹ́bí yarí
- Ilé aṣòfin n rẹkẹ, Boris Johnson takú, tá ní yóò bóri lórí awuyewuye ''party'' ọjọ́ ìbí?
- Òkú kú ní ẹ̀ẹ̀kejì nígbà tí òkú 400 jóná ráúráú ní mọ́ṣúárì, ẹbí bú sẹ́kún lẹ́ẹ̀kejì
- Dangote, má ṣe dáwọn ọ̀dọ́ tó ní kó dupò ààrẹ lọ́dún 2023 lóhùn o- Shehu Sani
Airi ọrọ yi yanju dabi ẹni pe o se idiwọ sisan owo naa amọ ẹgbẹ ASUU fasiti OAU lẹyin ipade wọn sọ pe alasẹ fasiti naa ko fi inu kan ba awọn se lori ọrọ yi.
Adeola Egbedokun to fi iwe asẹ sita fawọn olukọ nipa iyansẹlodi yi sọ ni ọjọ Aje pe olu ẹgbẹ ASUU ti fasẹ si ki awọn gunle iyansẹlodi ọlọjọgbọọrọ yi.
Kini iyansẹlodi yi yoo tumọ si fawọn akẹkọọ?
Ko si igba ti iyansẹlodi kii ni ipa ti ko sunwọn fawọn akẹkọọ fasiti ni Naijiria.
Yala eleyi to n waye ni abẹle tabi gbogboogbo, iyansẹlodi a maa mu ifasẹyin ba eto ẹkọ.
Bakan naa lo si n mu ki awọn obi ati akẹkọọ maa ke gbajare si ijọba lati wa wọrọkọ fi sada lori ọrọ iyansẹlodi.
Saaju ki wọn to wọle pada, awọn ile ẹkọ fasiti Naijiria ti gunleiyansẹlodi.

















