Mercy Aigbe: Ọkọ mi tẹ́lẹ̀ àti Adekaz kò fi ìgbà kankan jẹ́ ọ̀rẹ́, kìí sẹ ọ̀rẹ́ ọkọ mi ni mo fẹ́ - Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, Mercy aigbe
Gbajugbaja oṣerebinrin, Mercy Aigbe ti sọ pe ọkọ tuntun ti oun fẹ, Kazim Adeoti, ko fi igba kankan jẹ ọrẹ ọkọ rẹ atijọ.
Ọsẹ to kọja ni Mercy kede lori ayelujara pe oun ti ṣe igbeyawo pẹlu ọkunrin miran, lẹyin ọdun mẹrin ti igbeyawo rẹ pẹlu olokoowo, Lanre Gentry forisanpọn.
Bi Mercy ṣe kede Alhaji Adeoti gẹgẹ bi ọkọ rẹ tuntun fa awuyewuye laarin awọn ọmọ Naijiria, paapaa lori ayelujara.
Alagbata ati abani gbe sinima jade ni Adeoti.
Ọpọ eeyan lo n sọ pe ko bojumu bi Mercy sẹ fẹ ọkunrin naa nitori o ni iyawo ati ọmọ mẹrin.
- Ṣé lóòtọ́ ni Mercy Aigbe ti sẹ ìgbéyàwó pẹ̀lú Adekaz, àbọ̀ ìwádìí wa rèé
- Wo àwọn ìgbéyàwó tí ayé pariwo wọ́n lọ́dún tó lọ
- Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bí wọ́n ṣe rí Abba Kyari, Obi Cubana níbi ìgbéyàwò ọmọ ọ̀gá ọlọ́pàá Alkali Baba
- Pásítọ̀ mi bá àbúrò mi ṣe àṣemáṣe, gba mílíọ́nù àkọ́kọ́ tí mo pa bíi òṣèré tíátà, ó tún já ojú òpó ayélujára mi gbà - Toyo baby
Bakan naa ni awọn kan ti ẹ n sọ pe ọrẹ timọtimọ ni ọkọ ti Mercy fi silẹ, Lanre Gentry ati Alhaji Adeoti.
Eyi ṣeeṣe ko jẹ nitori awọn aworan kan ti idile mejeeji jọ ya papọ lo mu ki awọn eniyan sọ bẹẹ.
Esi ti Mercy Aigbe fun awọn to sọ pe ọrẹ ọkọ rẹ ni Kazim Adeoti
Ṣugbọn nigba to sọrọ lori eto ileeṣẹ amohunmaworan tVC ni ọjọ mẹrin sẹyin, Aigbe sọ pe ọkọ oun tẹlẹ ati ọkọ rẹ nisinsinyi ko fi igba kankan jẹ ọrẹ.
Ninu atẹjiṣẹ kan to fi ranṣẹ si ọkan lara awọn atọkun eto naa, Your View, lasiko ti wọn n jiroro nipa igbeyawo rẹ tuntun ni ọrọ̀ naa ti jade.
Ọjọ Aiku, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kinni, ni Mercy kede pẹlu aworan pe ọjọ igbeyawo ololufẹ oun tuntun ku wakati diẹ.
- 'A kò le gba ẹlẹ́wọ̀n kankan wọlé mọ́, kò sí òunjẹ tá a fẹ́ fún wọn'
- Alukoro JAMB wọ́ Ahmed Isah Brekete lọ síwájú Adájọ, ₦6bn lo n bèèrè lówó gbà má bínú
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti sàfihàn àwọn òníjàgídíjàgán méjìdínlọ́gọ́rùn ún lónìí ní Ado Ekiti
- Àwọn Olóyè ti wọ́gilé ẹjọ́ tí wọ́n pé tẹ́lẹ̀ lórí bí a ṣe ń jẹ ọba Olúbàdàn
- Ọwọ́ aráàlú ní ètò ìdájọ́ òdodo Nàìjíríà wà, kìí ṣé ọdọ àwọn onímọ̀ ètò ìdájọ́- Osinbajo
Aworan to fi sita jẹ ti gbajugbaja alagbata sinima, Kazim Adeoti.
Lẹyin naa lo tun fi ọpọlọpọ aworan sita to ṣafihan awọn mejeeji gẹgẹ bi ololufẹ.
Ọrọ yii fa awuyewuye, ti ọpọ si n na ika abuku si Mercy pe o da ile onile ru.
Ọkọ rẹ tẹlẹ, Ọgbẹni Gentry paapaa sọ lori ayelujara pe ọkan lara awọn nkan to fa ituka igbeyawo awọn ti n han sita bayii.
Lara ẹsun ti Gentry fi kan Mercy nigba ti igbeyawo wọn tuka lọdun 2017 ni pe o n fẹ awọn ọkunrin miran.














