America no visa interview: U.S. yóò máa fún àwọn ọmo Nàìjíríà kan ní físà ìwé ìrìnnà láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àjọ ilẹ̀ Amẹrika ní àwọn ń ṣe àyípadà sí ètò fífúnni ní visa lójúnà à ti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn tí kò ní èròǹgbá láti máa gbe ilẹ̀ Amẹrika láti máa ṣe sí ìwé ìrìnnà wọn láì ní ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò mọ́.
Ní inú oṣù kejì ní ètò tuntun yìí yóò bẹ̀rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko kí wọn tó tarí rẹ̀ sí Abuja.
Ṣaájú àkókò yìí, àwọn tó bá fẹ́ gba ìwé ìrìnnà lọ sí Amẹrika máa ń nílò láti yọjú sí Embassy ní Abuja tàbí ilé iṣẹ́ àjọ náà ní ìpínlẹ̀ Eko fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.
- Kìnìún méjì ṣekùpa olùṣọ́gbà ẹranko, wọ́n sì sálọ
- Àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Àdúláwọ̀ fòfin de Burkina Faso lórí ìdìtẹ̀gbàjọba
- Àwọn ọlọ́pàá méjì ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ wọn níbi tí wọ́n ti ń ṣe àyẹ̀wò ọkọ̀
- Ẹ foríjìnmí, ẹlẹ́ran ara ni mí- Gbajúgbajà adẹ́rìnpòṣónú, Bae_U
- Ọkọ mi tẹ́lẹ̀ àti Adekaz kò fi ìgbà kankan jẹ́ ọ̀rẹ́, kìí sẹ ọ̀rẹ́ ọkọ mi ni mo fẹ́ - Mercy Aigbe
- Alukoro JAMB wọ́ Ahmed Isah Brekete lọ síwájú Adájọ, ₦6bn lo n bèèrè lówó gbà má bínú
Ìyàtọ̀ yóò wà báyìí?
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí àjọ ilẹ̀ Amẹrika fi síta, iye ènìyàn tó ma le jẹ àǹfàní ètò yìí ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ kò ní tó nǹkan ṣùgbọ́n tí èyí yóò yí padà tí ètò náà bá ti dé Abuja.
Àjọ náà ní ènìyàn kan nínú mọ̀lẹ́bí ní yóò wá fi àwọn ìwé ẹ̀rí wọn lélẹ̀, àwọn ọmọdé kò nílò láti wá.
Bákan náà ni wọ́n ní ó ṣeéṣe kí ìgbésẹ̀ náà máa gbà tó oṣù méjì báyìí ṣùgbọ́n ìrètí wà pé kò ní máa ju ọ̀sẹ̀ pérete lọ tó báyá.
Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sọ pé ẹni náà kò ní le gba àwọn ìwé náà padà àyàfi tí gbogbo ètò bá parí.
Ta ni ó le jẹ àǹfàní yìí?
Àwọn tó le ṣe àtúnṣe sí ìwé ìrìnnà wọn láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ní àwọn tó ń fẹ́ B1/B2, F, M, J (àwọn akadá nìkan) H, L or C1/D tí wọ́n sì gbọdọ̀ ní àwọn nǹkan wọ̀nyìí :
- Nàìjíríà ni wọ́n ti gbọdọ̀ kọ́kọ́ fun ni visa lákọ̀kọ́.
- èyí ó ń bèèrè fún gbọ́dọ̀ jẹ́ nǹkan kan náà pẹ̀lú èyí ó ti gbà tẹ́lẹ̀.
-tí ọjọ́ bá ti lọ lórí visa náà láàárín oṣù 24 tábi tí ó bá ku oṣù mẹ́ta tí ọjọ́ yóò lọ lórí rẹ̀.
- Tí o ba ní pásípọ̀ọ̀tì t fún gbogbo ìgbà tí o lo visa náà àti ìgbà tí ó fẹ́ fi lò ó.
- tí wọn kò bá tí ì mú ẹ fún ẹ̀ṣẹ̀ kankan ní Amẹrika rí, kódà bí wọ́n bá yááfì rẹ.
- tí o kò bá ti ṣiṣẹ́ láì ní àṣẹ ilẹ̀ Amẹrika tàbí lò jù ìgbà tí wọ́n fún ọ lọ.
Ìgbésẹ̀ tí ènìyàn yóò tẹ̀lẹ́:
Ènìyàn yóò kọ́kọ́ san owó fún ètò visa náà lórí ẹ̀rọ ayélujúra tàbí sí ilé ìfowópamọ́ ṣaájú kí wọ́n ó tó bèrè fún visa.
Ẹni tí ó bá ní gbogbo àwọb nǹkan tó nílò wọ̀nyìí yóò lọ sórí ẹ̀rọ ayélujúra US láti ṣe àwọn ìgbésẹ̀ tó kàn.
- Fathia Balogun kéde aṣọ ẹbí ₦150,000 àti ₦120,000 fún ọjọ́ ìbí rẹ̀
- Àwùjọ àgbáyé, ẹ ṣèrànwọ́ fún Burkina Faso kó le borí ìṣòro - Olórí ìjọba ológun
- Tiyín lẹ ṣe o, àwa kò gbà èsì ìdìbò abẹ́nú PDP l‘Ekiti - Segun Oni
- Osun la fẹ́ kí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ti wáyé, kìí ṣe Abuja - Mọ̀lẹ́bí yarí
- Àwọn ọmọbìnrin oníwọ́kuwọ́ ló mú kí ń yẹ̀bá nídìí iṣẹ́ tíátà
- Sanwo-Olu kède iye tí àwọn aráàlú yóò máa wọ ọkọ̀ ojú irin ayára bí àṣá tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ́ rà
















