Policement accidental death: Àwọn ọlọ́pàá méjì ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ wọn níbi tí wọ́n ti ń ṣe àyẹ̀wò ọkọ̀

Agbofinro

Oríṣun àwòrán, EPA

Àwọn ọlọ́pàá méjì kan ni wọ́n ti yìbọn fún ní orílẹ̀ èdè Germany níbi tí wọ́n ti ń ṣe àyẹ̀wò ọkọ̀.

Ìròyìn ní àwọn ọlọ́pàá yìí dá ọkọ̀ kan dúró ní ẹkùn Kusel ní Rhineland-Palatinate, ìpínlẹ̀ tó páàlà pẹ̀lú ilẹ̀ Faransé.

Ọlọ́pàá ọkùnrin kan ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n àti obìnrin ọlọ́pàá ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún ni wọ́n ṣekúpa nínú ìkọlù náà.

Àjọ ọlọ́pàá ti pè fún wíwá àwọn tó ṣiṣẹ́ láabi náà.

Gbogbo àwọn òpópónà tó wà ní agbègbè náà ni wọ́n ti gbé tì pa, tí wọ́n sì tún lékún nínú ìwádìí wọn sí ìpínlẹ̀ Saarland.

Àkọlé fídíò, Ikere Ekiti: Olúkẹ̀ẹ́rẹ́ àti Ògògà tako ara wọn lórí ẹni tíí ṣe aláṣẹ ilú Ikere

Kí ni ó ṣẹlẹ̀ gan an?

Kò ì tíì sí àlàyé kíkún lórí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, bí kò ṣe tíì sí àlàyé kankan lórí àwọn tó hùwà náà, ọkọ̀ tí wọ́n gbé wá tàbí ọ̀nà ibi tí wọn sá gbà.

Àjọ ọlọ́pàá gan kò ì tíì sọ pàtó bí ọ̀rọ̀ náà ṣe lọ.

Agbofinro ati ibi to ti sele

Ìròyìn ní àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n pa wọ̀nyìí ni wọ́n ti ṣaájú fi àtẹ̀jíṣẹ́ ráńṣẹ́ pé àwọn dá ọkọ̀ kan dúró tí àwọn sì furasí àwọn tó wà nínú rẹ̀ àti pé àwọn rí ohun ìfura lẹ́yìn ọkọ̀ náà.

Lẹ́yìn èyí ni àtẹ̀jíṣẹ́ mìíràn wọlé pé wọ́n tí ń yìbọn mọ́ àwọn ki ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ náà tó já.

Àkọlé fídíò, Ogun King Killing: Baálẹ̀ Agodo ní ààrin Ẹ̀gẹ́ ni òun sùn mọ́jú, tí òun kò sì rí aya, ọmọ

Nígbà tí àwọn ọlọ́pàá yóò fi dé ibẹ̀, obìnrin ọlọ́pàá náà ti kú, tí ẹnìkejì rẹ̀ sì kú láìpẹ́ sí ìgbà náà.

Sabrina Kunz, tó jẹ́ alága ẹgbẹ́ àwọn ọlọ́pàá ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà bani lọ́kàn jẹ́ púpọ̀.