Mason Greenwood: Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Man U dá Greenwood dúró lẹ́yìn tí ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ sọ pé ó lu òun

Oríṣun àwòrán, MARC ATKINS/GETTY
Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti kede pe agbabọọlu wọn, Mason Greenwood ko ni i pada si ibudo igbaradi tabi kopa ni ifẹsẹwọnsẹ kankan titi di igba ti awọn ko ti i le sọ.
Ọjọ Aiku ni fidio, fnran ohun ati aworan jade sori ayelujara pe Greenwood lu obinrin kan bii bara.
Obinrin naa to jẹ ọrẹbinrin rẹ, Harriet Robson, fi awọn nkan yii si ori ayelujara Instagram rẹ, ṣugbọn o ti pada yọ wọn kuro.
O kọ akori si abẹ rẹ pe "Fun gbogbo ẹni to fẹ ẹ mọ nkan ti Mason Greenwood ma n sẹ fun mi".
Ileeṣẹ ọlọpaa Greater Manchester sọ pe oun ri awọn aworan ati fidio naa.
Manchester United ti kọkọ fi ikede sita pe oun ko faramọ iwa ipa kankan, to si ni oun ti ri awọn ẹsun ti wọn fi kan Greenwood.
Wọn ti kọkọ ni awọn ko ni sọ ohunkohun lori isẹlẹ naa titi wọn o fi ri okodoro ọrọ.
Mason Greewood funra r ko ti i sọ nkankan nipa awọn ẹsun naa.
Oṣu Kẹta, ọdun 2019 ni ẹni ogun naa bẹrẹ iṣẹ pẹlu Man United, to si tọwọ bọ adehun ọlọdun mẹrin pẹlu wọn ni oṣu Keji, ọdun 2021 lẹyin to ti gun awọn ipele igbega ni ile ẹkọ United Academy.












