Iyabo Oko: Ọmọ òṣèré tíátà náà ní àwọn mọ̀ọ́mọ̀ gbé ìròyìn ìlera màmá òun kúrò lórí ayélujára ni

Oríṣun àwòrán, iyabo_oko
Osere pataki tii odu, tii kii se aimọ fun oloko lagbo awọn osere tiata ni Kuburat Odukanmi, ti ọpọ eeyan mọ si Iyabo Oko.
Laipẹ si ni iroyin jade pe ojojo n se Ogun iya naa, ara ogun ko le, aisan naa si le tobẹẹ to fi gba apa ati ẹsẹ rẹ.
Koda, asiko kan tiẹ wa, ti ariwo ta pe olodi iya naa ti jade laye, ti awọn ololufẹ rẹ si n tara poro lori iku iya naa.
- A ti gbálé ati gbáta, kò sí ǹkankan lọ́wọ́ wa mọ́ ni a ṣe kígbe síta- Adebisi Aisha, Ọmọ Iyabo Oko
- Àwa ọmọ Iyabo Oko ló dá owó gọbọi fi gbé ìyá wa lọ sí India fún ìtọjú- Ewa, ọmọ Iyabo Oko
- Mo ta ọkọ̀ ayọkẹ́lẹ́ méjì lórí àìsàn yìí, mo nílò ìrànwọ́ ẹ̀yin olólùfẹ́ mi - Iyabo Oko
- Inú wa dún pé Oba Oke dá ẹ̀mí Iyabo Oko padà, a gbàgbọ́ pé ìya wa ṣì máa gbádùn pẹ̀lú àdúrà- Omo Iyabo Oko
- Báyìí ni ìrìnàjò àìsàn Iyabo Oko ṣe bẹ̀rẹ̀ láti ọdún márùn ún ṣẹ́yìn
- Ìròyìn ayọ̀, Iyabo Oko kúrò nílé ìwòsàn, ó ń sọ̀rọ̀ fatafata àmọ́...
- "Àìsàn tó ń ṣe Iyabo Oko ti ṣàkóbá fún ọmọ ìka ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀"
Amọ wakati diẹ lẹyin ikede ọfọ Iyabo Oko naa, tun ni iroyin miran jade pe olodi iya naa lo ku nitori oun gangan si n bẹ loke eepẹ.
Mọlẹbi iya naa sọ fun BBC Yoruba nigba naa pe lootọ ni aisan Iyabo Oko gbe ọwọ lile amọ ẹlẹmi ko tii gba, to si n gba itọju alagbara lọwọ dokita.
Ọpọ eeyan lo n kaanu agba osere tiata yii, ti wọn si nifẹ lati mọ ibi ti ilera iya naa de nibayii ti ilẹ ti ta diẹ, ti wọn ti gburo rẹ kẹyin.
Eyi lo mu ki BBC Yoruba tun kan si mọlẹbi Iyabo Oko pe bawo ni ara mama nigba to to ọjọ mẹta ta ti gburo wọn, ka si mọ bi alaafia wọn ti gbewọn si.
Mama wa ti n gbadun, awa la pinnu lati mase sọrọ rẹ lori ayelujara mọ:
Ọkan lara awọn ọmọ gbajugbaja oṣere tiata naa wa sọ fun BBC Yoruba pe agba oṣere naa ti n gbadun, bo tilẹ jẹ pe o ku ni ibọn n ro.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, o ni awọn gẹgẹ bii mọlẹbi mọọmọ kọ lati sọrọ nipa oṣere naa lori ayelujara ni nitori awọn eeyan kan to le maa ro pe nṣe ni awọn fẹ tọrọ owo lọwọ awọn ololufẹ rẹ.
O ni "Awọn mọlẹbi ti ni ki a maṣe sọ ohunkohun nipa ilera iya wa lọwọ yii nitori awọn eeyan to le maa ro pe a fẹ tọrọ owo lọwọ wọn ni."
"Bi mọ ṣe n ba yin sọrọ yii gan, ọwọ mi ni ẹrọ ilewọ wọn wa, nitori a ko fẹ ki wọn ba ẹnikẹni sọrọ lakoko yii amọ ara wọn ti n balẹ diẹ-diẹ."
"Kii ṣe gbogbo nnkan to ba n ṣẹlẹ ni a oo maa sọ lori ayelujara, a ko si ṣetan lati maa gbe wọn jade ni gbogbo igba, ẹni to ba fẹ lati ṣe iranlọwọ fun yoo ṣe e lai bẹbẹ."
Iyabo Oko ko tii le rin kaakiri:
Nigba to n sọrọ lori ipo ti ilera oṣere tiata naa de duro lọwọ lọwọ bayii, ọmọ Iyabo Oko ni iya oun ko tii le rin kaakiri, amọ awọn fi igbagbọ awọn sinu Ọlọrun fun imularada rẹ.
O tẹsiwaju pe awọn ẹbi n gbaruku ti oṣere naa lati tọju rẹ, awọn si n gbiyanju ohun ti awọn le ṣe.
O ni "Agbelebu wa ni wọn jẹ, a oo si maa gbe wọn titi ti Ọlọrun yoo fi gba ogo."
O ni o ṣeeṣe ki oṣere ọhun ba awọn eeyan sọrọ laipẹ, amọ kii ṣe lori ẹrọ ayaworan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ọmọ Yorùbá mẹ́ta àti gbajúmọ̀ míì tó ní Lupus, àrùn tó n bá Kemi Afolabi fínra
- Ẹsẹ̀ mi yẹ̀ gẹ̀rẹ̀, mo la orí mọ́ táísì, mo sì fẹ́ ẹ̀ pàdánù ọpọlọ nígbà tà ń ya fíìmù - Mide Martins
- Wọ́n tan bàbá 85 kúrò nílé, fọ́ igi mọ lórí, ju òkú rẹ̀ sétí odò l‘Ogun
- "Ọlọ́pàá ló pe mí láti wá gbé òkú Timothy Adegoke lẹ́sẹ̀ títì"
- Wọ́n fi abẹ dá ọgbẹ́ sí Timothy Adegoke lára ni, kí ẹ̀mí tó bọ́ lára rẹ̀ - Onímọ̀ ìwádìí
- Ọ̀kan lára àwọn afurasí mẹ́rin tó gé orí Sofiat Okeowo láti fi ṣẹ́ṣó gba ìtúsílẹ̀
- Afurasí Fulani gé ọwọ́ Fijilańté méjèèjì ni Iwere Ile ni Ipinle Oyo
Iyabo Oko ji pada lẹyin ti wọn ni o ti ku:
Ibẹrẹ ọdun 2022 ni iroyin gbode kan pe Iyabo Oko ti jade.
Iroyin naa lo milẹ titi lẹyin ti ọkan lara awọn ọmọ rẹ, Bisi Aisha kede loju opo Instagram rẹ pe iya oun ti ku.
Amọ lẹyin wakati diẹ si akoko naa lo ṣe fidio kan nibi to ti sọ pe iya oun ṣi wa laaye.
Gẹgẹ bii ohun ti Bisi sọ lasiko naa, ẹgbọn rẹ kan lo kọkọ sọ fun pe iyẹ rẹ ti ku, amọ wọn tun pe pada pe ọrọ ko ri bẹẹ mọ.





















