Bola Tinubu: Ìdí rèé tí èròngbà Bola Tinubu ṣé n dá àgbo òṣèlú Nàìjíríà ru

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, @Bola Tinubu

Àkọlé àwòrán, Bola Tinubu

Nilẹ oni to mọ lagbo oselu ni Naijiria, ninu awọn oloselu to ti kede erongba wọn lati dupo aarẹ Naijiria ko si eleyi to fẹ milẹ titi to ti Bola Ahmed Tinubu.

Kii se pe oluwaarẹ n fọwọ rọ awọn to si yi ti sọ pe awọn fẹ du ipo aarẹ bi kii se pe a foju wo iru iriwisi to tẹle ikede rẹ yi.

Osinbajo ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, @Osinbajo

Awọn to ku to kede pe awọn fẹ du ipo ko mu iru ariwisi yi bi ti Tinubu.

Eleyi lo mu wa beere pe ki gan an lo n fa awuyewuye lori ikede erongba Tinubu lati du ipo aarẹ Naijiria?

Ninu alaye eleyi taa fẹ se agbeyẹwo rẹ, ohun to foju han sawọn eeyan ni pe Bola Tinubu jẹ odu lagbo oselu ati pe erongba rẹ lati du ipo aarẹ kii se tuntun.

Saaju asiko yi lo ti han gbangba si awọn eeyan pe gbogbo igbiyanju Tinubu nipa bo ti se pẹka bi iroko ko ju pe o fẹ jẹ aarẹ Naijiria.

Lasiko to se abẹwo si aarẹ Buhari lati lọ sọ fun pe oun fẹ dije aarẹ, o sọ ọrọ yi pe ọjọ ti pẹ toun ti n gbero lati jẹ aarẹ.

Bayi ti asiko wa n sunmọ bọ, ki lo n fa awuyeweuye saaju ki ipolongo tiẹ to bẹrẹ?

Àkọlé fídíò, Fatimah Abode Lybia

Kini Idi ti awọn kan ko fi fẹ Tinubu gẹgẹ bii aarẹ 2023?

Ni isọri awọn to n Tinubu ko yẹ ni aarẹ orisi ni wọn.

Ninu wọn la ti ri awọn to sọ pe ikede Tinubu lati jẹ aarẹ da bi ẹni pe o dalẹ awọn ẹya kan ni Naijiria to se pe asiko ti wọn ni lati jẹ aarẹ.

Àkọlé fídíò, Ẹni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?

Egbẹ idagbasoke awọn ọmọ ilẹ Igbo Ohanaeze Ndigbo wa lara awọn taa n wi yi.

Ninu awọn to kede pe awọn fẹ du ipo aarẹ, Tinubu nikan ni wọn sọ pe erongba rẹ le da Naijiria ru.

Wọn ni erongba rẹ ko dun mọ Ọlọrun ninu nitori naa ko le de ori ipo naa.

Àkọlé fídíò, Èmi ni mo yọ "wipe" fi nu omi ẹkún to ti gbẹ́ àti ikun imú nímú òkú ọmọ tí wọ́n gbé lé mi lọ́wọ́ - Ìyá Ojo Emmanuel

Ni isọri mii la ti ri awọn to jẹ ẹya Yoruba kanna bi ti Tinubu ti wọn tako erongba rẹ.

Awọn wọnyi pin si orisi meji.

Akọkọ lawọn to sọ pọnbele pe OYO ni Tinubu wa pẹlu erongba rẹ. Afẹnifẹre wa ninu isọri yi.

Awọn miran bi Ilana Omo Oodua tilẹ sọ pe awọn ko ni gbe lẹyin oloselu kankan nitori pe ohun tawọn fẹ ni atunto orileede Naijiria eleyi ti yoo mu ki ẹya Yoruba ya sọtọ ti wọn yoo si da ijọba ara wọn se.

Bawọn wọn yi ti se n sọ ti wọn lawọn kan loju opo ayelujara paapa awọn ọdọ n sọ pe yiyan Tinubu si ipo aarẹ yoo dabi ẹni pe arugbo nikan lo le da ijọba se ni Naijiria.

Lọdọ awọn taa n wi yi, fifi Tinubu rọ po Buhari yoo da bi ẹni pe a n fo lati ibi kan ta si n ba soju kan naa.

Ewẹ awọn mii tilẹ sọ pe awọn iruju kan to so mọ Tinubu lọwọ yi paapa nipa ọjọ ori rẹ ati ọna to se gba ri owo rẹ jẹ nkan tawọn ko le tori rẹ gbe lẹyin rẹ lati di aarẹ Naijiria.

Bi ẹ ba ti n gbọ ọrọ nipa Bullion Van ati ibeere miran nipa Tinubu awọn wọn yi lo n sagbatẹru aatako Tinubu pe awọn ko fẹ nipo aarẹ Naijiria.

Àkọlé fídíò, Lori ọrọ Olubadan tuntun

Awọn ipenija mii wo ni Tinubu tun le koju

Ipo aarẹ Naijiria jẹ ipo ẹlẹgẹ paapa nipa ohun tawọn eeyan a maa wo lati fi dibo fun oloselu kankan.

Ninu rẹ la ti ri ọrọ ẹya ati ẹsin.

Esin paapa jẹ eleyi to le se alatako fun Tinubu saaju ko to le bẹrẹ ipolongo rẹ.

Àkọlé fídíò, Young Tolibian

Musulumi lati apa Iwọ oorun Guusu Naijiria ni Tinubu.

Bi o ba fẹ se aseyọri ninu idibo 2023, yoo ni lati mu igbakeji aarẹ lati ilẹ́ Ariwa Naijiria fun itẹwọgba awọn eeyan ibẹ.

Amọ o tun gbọdọ wo iru igbakeji ti yoo yan nitori aarẹ to jẹ musulumi kii saba se daadaa lọdọ awọn oludibo paapa to ba mu igbakeji ẹlẹsin kan naa pẹlu rẹ.

Fun idi eyi, Tinubu ni lati mu igbakeji to jẹ Kristẹni lati ilẹ ariwa.

Eleyi le fun un ni isoro nitori pe awọn eeyan ariwa kii foju ree wo oludije ti kii ba se musulumi.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe làlùyọ pẹ̀lú ìpèníjà ara tí èmi náà ń lọ ọ́fíìsì gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ìjọba - Raymond Adegoke

Kini o n ṣẹlẹ ninu Ọrọ Tinubu ati Osinbajo?

Bola Ahmed Tinubu jẹ baba isalẹ fun ọpọ oloselu ni Naijiria, ninu wọn ni igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo.

Lasiko ti Tinubu jẹ Gomina nipinlẹ Eko lọdun 1999, o yan Osinbajo sipo Kọmisọnna eto idajọ.

Osinbajọ to pada wa di igbakeji aarẹ kii ko iyan Tinubu kere sugbọn ti ọrọ to n lọ lode pe o fẹ du ipo aarẹ ba fi le jẹ ootọ, Osinbajo ati baba isalẹ rẹ yoo jijọ bọ sokoto kan naa.

Àkọlé fídíò, BIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi

Osinbajo ko to Tinubu lọjọ ori ko si ni koju ipenija ọrọ pe bawo lo se ko ọrọ rẹ jọ bi ti Tinubu.

Ohun ti yoo kan jẹ ipenija ni pe o le ma ta ewe ta egbo de awọn ibi ti yẹ lati le fi ri ibo awọn ara ilu bi ti Tinubu.

Titi di igba ti a o fi gbọ pe Osinbajo kede erongba rẹ, a o ni le sọ ju bayi lọ nipa iru ikoju ti yoo le se fun Tinubu fun tikẹẹti ẹgbẹ oselu APC fun ipo aarẹ.

Ki lawọn alatilẹyin Tinubu n sọ bayii?

Jagaban Borgu, gẹgẹ bi wọn ti se n pe Asiwaju Bola Tinubu, jẹ oloselu kan to ni ọpọ alabase ati ololufẹ́.

Pupọ awọn to n se ipolongo Tinubu bayi a maa jẹri si pe o ti se wahala pupọ fun isọkan Naijiria tori naa asiko to bayi lati jẹ ko dipo to ga julọ ni Naijiria.

Fonran fidio kan taa ri loju opo ayelujara safihan agbaọjẹ oloselu nii Rasidi Ladoja to sọ pe aburo oun ni Tinubu nitori naa ko nilo lati beere ki oun to satilẹyin fun.

Àkọlé fídíò, 'Ká tó rí irú Akala, ó di "century" míì, kò sí olóṣèlú kankan tó máa ń ṣilẹ̀kùn rẹ̀ fún wa l'Ogbomoso'

Kaakiri to fi de ori awọn oloselu lati ilẹ ariwa ninu ẹgbẹoselu APC ati awọn ẹgbẹ miran la ti ri awọn to n sọ pe Tinubu yẹ lẹni taa yn sipo aarẹ.

Koda, Gomina ipinlẹ Oyo sọ pe oun ro daada si Tinubu sugbọn oun to dara julọ loun n fẹ fun Naijiria.

Laarin awọn to jẹ anfaani ipo kan tabi omiran lọdọ Tinubu, ohun ti wọn n sọ ni pe alatilẹyin ati oluranlọwọ to n gbe awọn eeyan dide ni Tinubu.

Àkọlé fídíò, 'Mo sọ fún Dókítà pé èmi ò lè gé ọyàn mi, pé ṣọ́ọ̀ṣì yóò fi àdúrà ṣẹ́gun àìsàn jẹjẹrẹ ọmú mi'

Wọn a maa tọka si iye oloselu to lorukọ ti Tinubu ti fa soke bi Minisita Babtunde Raji Fasola,Igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo,olori ile asojusofin Femi Gbajabiamila,Minisita Rauf Aregbesola ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Koda, wọn a maa sọ pe bi kii ba se ti atilẹyin Tinubu, Aarẹ Buhari ko ba ma de ori ipo aarẹ.

Labẹ eleyi, ibeere kan taa fi kadi apilẹkọ yi ni boya aarẹ Buhar yoo gbaruku ti Tinubu lati fi sẹsan atilẹyin to fun saaju.

Abi Yemi Osinbajo ti aarẹ Buhari ti n ba sisẹ pọ lati nkan bi ọdun mẹjọ din diẹ ni aarẹ yoo yan laayo?

Idahun si ibeere yi ni yoo tọka ibi ti adaghba yoo rọ si nipa ẹni ti yoo jawe olubori gẹgẹ bi oludije ti yoo ri tikẹẹti ẹgbẹ oselu APC gba bo ba ya.