Social media comedians: Ayélujára sọ ọmọ Nàìjíríà mẹ́fà di gbájúgbajà

Oríṣun àwòrán, Others
Ori nikan lo mọ ọlọla to ba di ọla, ko si sí eni to mọ ọna ati la laye nigba mii.
Awọn Naijiria mẹfa kan ni awọn itakun ikansiraẹni ayelujara ti sọ di ilúmọọka bayii.
Nipa oriṣiiriṣii fidio ati fọto ti wọn pin loju opo Instagram, Facebook ati Twitter ti awọn eeyan bẹrẹ si ni sọ nipa rẹ ni awọn eeyan yii fi di ilúmọọka.
Bi awada, bi ere ni awọn eeyan mẹfa yii di gbajugbaja lẹsẹ k'ẹsẹ.
- Àwọn arẹwà obinrin Yollywood, tá ló mọ iṣẹ́ rẹ̀ jù?
- Ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi kò rọrùn rárá ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ mó di ayaba- Jaye Kuti
- Kunle Afolayan, òṣìṣẹ́ báńkì tẹ́lẹ̀ kó tó di gbajúgbajà òṣèré
- Odunlade fẹ́ j'ọba, Bolanle Ninalowo fun ìyàwó rẹ̀ ni ẹ̀bun kanka, Pá Kasumu rebi àgbà ree
- Awọn òṣèré Yoruba tí wọ́n bí ní ọjọ kan náà
- Lizzy Anjorin gbàgbé ọ̀rọ̀ àná, ó kí Iyabo Ojo kú ọjọ́ ìbí, Femi Adebayo kọ ọmọ l'áṣà
Salle:
Salle jẹ omodebinrin ọdun mẹtadinlogun to n kiri ọja nipinlẹ Imo.

Oríṣun àwòrán, Others
Fidio kan lori ayelujara ninu eyi ti Salle ti kọ orin aladun lo sọ ọ di ẹni t'awọn eeyan bẹrẹ si ni sọ nipa rẹ.
Salle di gbajugbaja lori ayelujara debi pe awọn agbaọjẹ olorin lagbaaye bẹrẹ si ni sọ nipa rẹ.
Oreofe Oluwa Lawal-Babalola:
Ẹni to ba ti ranti fidio "mummy, calm down," ko le ṣai ranti ọmọdekunrin Oreofe Lawal-Babalola ti a n sọ nipa rẹ yìí.
Ọmọ ọdun marun un pere ni Oreofe i ṣe.

Oríṣun àwòrán, others
Ọmọ yii di ẹni tí awọn eeyan n sọ nipa rẹ nigba ti o mu mama rẹ ṣere lasiko ti iya rẹ fẹ lu u.
Koda gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti gba Oreofe ni alejo.
BBC gan an ti ṣe ifọrọwerọ pẹlu rẹ, ati pe Oreofe ti di aṣojú ileeṣẹ talẹ talẹ kan niluu Abuja bayii.
Bakan naa ni Oreofe ti kopa ninu ere ori itage kan ti Kunle Afolayan ṣe.
Taju:
Ọmọ ilu Ibadan ni Taju, ọmọ ọdun marun un si ni i ṣe.
Taju di ẹni ti aye n sọ nipa rẹ lẹyin ti fidio kan ninu eyi to ti n tiraka lati sọ ede oyinbo lu ayelujara pa.

Oríṣun àwòrán, Others
Ọpọ eeyan to fi mọ awọn ilúmọọka bii Ayo Makun, Don Jazzy, Falz, Funke Akindele, Mo Abudu, Funmi Awelewa ati Alibaba lo kaanu rẹ ti wọn si dide iranwọ si i.
Lẹyin naa ni Taju paarọ orukọ rẹ si Opeyemi ti o si n ṣe daadaa labẹ eto kan ti ijọba ipinlẹ Oyo gbe kalẹ.
Olajumoke Orisaguna:
Ori lo mọ iṣẹ aṣela laye.
Lati ipinlẹ Osun ni arẹwa obinrin, Jumoke Orisaguna ti wa iṣẹ wa si ilu Eko.

Oríṣun àwòrán, Others
Burẹdi ni Jumoke n kiri niluu Eko ki ori to gbe e ko o ire nigba ti gbajugbaja ayafọto n ni, TY Bello ya fọto rẹ eyin ti o fi sori ayelujara.
Lati ibẹ ni ọpọ eeyan ti mọ nipa Jumoke oniburẹdi, arẹwa iya ọlọmọ meji.
Awọn ileeṣẹ kan fun Jumoke ni ẹkọ ọfẹ, koda ileeṣẹ iroyin CNN ti ṣe ifọrọwerọ pẹlu Jumoke oniburẹdi.
Ayomide:
Orin akọrin ẹmi, Tope Alabi, ni Ayomide kọ lọna ara ninu fidio kan lori ayelujara ti awọn eeyan fi mọ nipa rẹ.
Ọsan ni Ayomide n kiri niluu Ilaro nipinlẹ Ogun nibi ti ọkunrin kan to n jẹ Sunkanmi ti ṣe fidio rẹ nibi to ti fi ohun aladun rẹ kọ orin Tope Alabi.
Lẹyin naa ni Eledua gbe iranwọ dide fun Ayomide ti Alufaa Rev Mother Esther Ajayi si fun un eto ẹkọ ọfẹ.
Success Adegor:
Success Adegor, ọmọ ọdun meje, di ẹni taye n sọ nipa rẹ nigba ti fidio kan ninu eyi to ti banujẹ lori bi wọn ṣe le e kuro nile iwe tori airowo san.

Oríṣun àwòrán, others
Ohun to ṣe awọn eeyan laanu ni bi Success ti sọ pe o san ki wọn lu oun lẹgba ju ki wọn le oun kuro nile ẹkọ lọ.
Eyi lo jẹ kí ijọba ipinlẹ Delta dide iranwọ fun Success ati ẹbi rẹ.






















