Mummy calm down: Ìyá Ore sọ pé gbogbo ìgbà tí óun bá n bá a wí ló ma n ṣe àwàdà
Laarin ọsẹ to kọja ni di ilumọọka, lairo tẹlẹ. Eyi ko ṣẹyin fidio kan ṣe gba ori ayelujara, to si ṣafihan ọmọ naa nibi to ti n bẹ iya rẹ fun idariji.
Iya ọmọ naa sọ pe iyalẹnu lo jẹ fun oun nigba ti awọn eeyan bẹrẹ si ni pe akiyesi oun si iroyin pe gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu fẹ ẹ ri ọmọ oun.
O ni niṣe ni inu oun dun pe ọmọ naa ko oun jade si ire, paapa nigba ti gomina tun pe wọn lori ẹrọ ibanisọrọ.
Arabinrin sọ pe ọjọ tipẹ ti ọmọ naa ti ma n ṣe awada oriṣiriṣi lasiko ti wọn ba n ba awi, fun aṣemaṣe.
"Mi o ni lọkan pe ma a ya fidio rẹ lọjọ naa, ṣugbọn bi mo ṣe n beere pe kilode to fi ṣe nkan ti mo ni ko gbọdọ ṣe, lo bẹrẹ si ni gba ori ara rẹ, to si n sọ pe, Ore, kilode ti o fi ṣe bẹ ẹ?"
O sọ pe ẹyin o rẹyin ni oun to o mọ pe ẹgbọn oun ti oun fi fidio naa ranṣẹ si lo fi si ori ayelujara.