Risikat Moromoke Azeez: Mínísítà tí fi ẹ̀bùn owó ránṣẹ́ si ìyá Kausara, ó tún jẹ́jẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ f'áwọn ọmọ rẹ̀
Mínísíta fún ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ àti eré ìdáraya ní Naijiria Sunday Dare ti kéde pé àwọn ṣetán láti rán àwọn ọmọ olójú búlúù ti bàbá wọ́n lé àwọn àti ìyá wọ́n síta lọ si ilé iwé.
Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún mínísítà, Shola Kolawole lo sọ èyí lásìkò tó sàbẹ̀wò si ìyá àwọn ọmọ náà Risikat tí òun pẹ̀lú ni ojú búlúù.
Bákan náà ni Kolawole fún ẹbi náà lówó bí mínísítà ṣe ran, o ní kò sí ọmọde ti kò yẹ láì lọ sí ilé ìwé.
" Itan rẹ̀ jẹ́ èyí tó kọni lóminú, ó sì ṣeni láànú. Ìyá àti ọmọ méji tí ọkọ wọ́n dà síta nítórí ǹkan ti kìí ṣe ẹ̀bi wọ́n. Kò sí ọmọ ti kò yẹ láì lọ sí ilé ìwé"
Aládùgbò mí ni wọ́n Ilorin kò jìn à sí Ogbomosho, ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ náà sì sọ pé kí a fẹ́rà ọmọlàkejì wa gẹ́gẹ́ bi ara wa.
Bákan náà ni ìyàwó gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara Olufolake Abdulrahaman ti fẹ̀bun owó ránṣẹ́ sí obìnrin náà pẹ̀lú.
Láti ìgbà ti ọ̀rọ̀ yìí ti jẹ jáde ni ọ̀ṣẹ̀ to kọjá ni àwọn ọmọ Naijiria ti dìde láti gbárùkù ti obìnrin náà àti àwọn ọmọ rẹ̀.
Aya Adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà àná ní Nàìjíríà, Toyin Saraki náà ti fi ẹ̀bùn owó ránṣẹ́ sí obìnrin Risikat.
Wọ́n ṣe èyí lóòni nígbà tó ràn àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ Patricai Komolafe àti àwọn adari ẹgbe rẹ ni Kwara lọ láti lọ fi owo náà jíṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Rafiu Abdul
Ilorin Blue Eyes Family: Ìyá àwọn ọmọ tí bàbá kọ̀ sílẹ̀ torí àwọ̀ ojú wọn bá BBC sọ̀rọ̀
"Abi ṣe oju buluu yii kan naa kọ ni baba Kausara ri lara iya rẹ nigba to yofẹẹ rẹ to fi ṣe "Wos fáín gẹẹ̀lì"?"
Risikat to jẹ ọmọ agbo ile Ayegbami niluu Ilorin.
O kẹnu bọrọ, o ṣalaye fun BBC Yoruba ohun toju rẹ n ri nile ọkọ latọjọ to ti bẹrẹ si ni bimọ pẹlu awọ oju to yatọ si ti gbogbo eeyan.


Idẹyẹsi ọhun pọ latọdọ ọ̀kọ, mọlẹbi ọkọ koda ladugbo to bẹẹ to fi pada dero ile baba rẹ.
"Torii oju buluu ti ọmọ mi ni naa lawọn ẹbi rẹ ṣe ń sọ̀rọ̀ pe se iru oju yii naa loo maa bi lọ ni".
O ni tori rẹ gan lo fa a ti ọkọ rẹ fi le wọn kuro nile.
"Ó bí alakọbi oju rẹ ri buluu, o bi ẹlẹkeji oju ri buluu, ṣe iru oju yii ni iwọ o maa bi lọ ni?", eyi ni ibeere ti awọn mọlẹbi maa n ti si ọkọ.

Iru ọrọ ti ẹbi ati ọrẹ rẹ n sọ fun un gẹlẹ naa lo fi n huwa si iyawo ati awọn ọmọ ọhun
Mallam Abdulwasiu lorukọ ọkọ rẹ n jẹ. Risikat ni igba toun ti kuro lọdọ baba Kausara, ile awọn obi oun loun ko lọ ti wọn si n gbọ jijẹ mimu.
Koda akọbi ọmọ rẹ to ti n pe ọdun marun lọ bayii ko tii wọ ile iwe tori baba kọ lati ran an lọ.
Ohun to wa ṣe wa ni Kayefi ni wi pe iya awọn ọmọ yii funrarẹ gan, iru oju buluu yii kan naa lo ni.
Torinaa kii ṣe awọn ọmọ yii nikan lo koju idẹyẹsi. Ladugbo nkan toju iya wn n ri ko kere, ọmọde mii a ri i a kan dede sa lọ pe "ẹhn ẹ wa wo iruu oju yii, ti yoo họ".
Ninu idile iya ati baba tirẹ ko si ẹnikẹni to ni iru oju yii o.
Nigba ti BBC Yoruba tiraka titi titi lati ri ọkọ Risikat ba sọrọ, ọpọlọpọ ọjọ la fi da fidio yii duro tori idọgba gbudọ wa ninu iṣẹ wa gẹgẹ bi ohun ti ẹ fi n wari fun iṣẹ BBC Yoruba, a pada ri baba awọn ọmọ yii ba sọ̀rọ̀.
Esi to fọ lagbara, o wa ninu fidio naa.
