Kehinde lady mechanic: Láti kékeré níṣẹ́ẹ mọkálíìkì ti wù mí, mo bá ń tẹ̀lé bàbá mi

Àkọlé fídíò, 'Mo fẹ́ gbé ògo ìdílé ìyá àti bàbá mi ga pẹ̀lú iṣẹ́ Mọkálìíkì'
Kehinde Mọkaliiki

Iru itan bayii kii ṣe olojoojumọ tẹẹ le ri fidio tabi iroyin nipa rẹ nibi gbogbo ṣugbọn eyi to fọwọ tọ ni lọkan gidi gan ni.

Ibeere to ṣee ṣe ko wa sọkan awọn mii ni wi pe ṣé obìnrin rèé àbí ọkùnrin tó kárà mọ́ṣẹ́ mọkaliiki báyìí?

Ọmọ ọdun mejidinlogun ni Kehinde Popoola to tun jẹ ọmọ ileewe girama ṣugbọn kii ṣe ọmọbinrin bii gbogbo ọmọbinrin ti ẹ mọ.

Iṣẹ mọkaliiki ni Kehinde yan laayo lati kekere ọjọ aye rẹ. Ifẹ to ni si ka maa tu irin kan si omiran, ka maa lo irinṣẹ lo mu kọ lọ bẹrẹ si ni kọṣẹ ni ṣọọbu mọkaliiki kan.

Ibeji ni Kehinde, Taye rẹ wa laaye ṣugbọn ibi ori da oun si naa lo i tete n tọpasẹ rẹ bayii.

Lai tii pari ẹkọ rẹ nileewe girama, o ti ni afojusun fun ọjọ iwaju to logo nipa kika imọ ẹkọ Mechanical Engineering nileewe giga fasiti ko baa le di ọga funrarẹ nileeṣẹ imọ ẹrọ tirẹ.

Ọga ẹ to n kọṣẹ lọdọ rẹ gan fọwọ sọya pe o lee dele de oun daadaa fun iṣẹ bi oun ko ba si nile.

Kehinde jẹ ọmọ ilu Omu-Aran ni ipinlẹ Kwara to si wa ni ipele kaarun nileewe girama.

BBC Yoruba ba Kehinde Popoola pade lẹnu iṣẹ rẹ lasiko to n tun ọkọ ṣe lọwọ.